Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS, ti gbe awọn afurasi to lọwọ ninu jiji awọn agunbanirọ to rinrinajo lati ibadan lọ si ipinlẹ Imo lọ sile ẹjọ
Waju adajọ Chukwudifu Oputa ni wọn ti kawọ sẹyin rojọ nile ẹjọ giga kan niluu Oweri
Orukọ awọn afurasi naa ni Babangnda Aliyu, Aliyu Usman ti inagijẹ rẹ n jẹ Dongo ati Mohammed Ali
Gbogbo wọn ti ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn
xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx
Iwọde EdnSARs, ninu eyii ti ọpọ ẹmi ti sọnu lọdun 2020 pe ọdun mẹfa lonii
Ọkunrin to kan fara gbọta lasiko iwọde naa Agbeze Ifeanyi Matthew sọ fun BBC pe
Igba aya ni ọta ibọn ti ba oun lọjọ naa, ti ọta ọhun si jade ni odi keji
Ẹkunrẹrẹ wa loju opo wa
xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx
Ọwọ agbofinro ti tẹ pasitọ kan ati iyawo rẹ lori ẹsun pe wọn de awọn eeyan mọlẹ pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ ni South Afrika
Awọn eeyan ti ko din igba ni pasitọ naa de mọlẹ, nigba ti awọn miran wa nibi ti wọn pe ni ọgba imularada
To ba fẹ mọ ẹkunrẹrẹ