Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Mọ̀lẹ́bí Olóògbé Fasoranti kéde ọjọ́ ìsìnkú lẹ́yìn tí èèkàn ọmọlẹ́yìn Awolowo náà jáde láyé lẹ́ni ọdún 100
Awọn mọlẹbi olori ẹgbẹ Afenifere to jade laye lẹni ọgọrun-un ọdun, Reuben Fasoranti ti kede ọjọ ti wọn yoo tẹ baba naa si afẹfẹ rere.
Atẹjade ti ọkan lara awọn mọlẹbi Oloogbe naa, Ọmọwe Taiwo Fasoranti fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade to fi sita laipẹ yii.
Ọkunrin naa sọ pe eto isinku yoo waye laaarin ọjọ kẹrindinlogun si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2026.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye ninu atẹjade to kọ lorukọ mọlẹbi, Taiwo Fasoranti sọ pe eto isin onigbagbọ yoo waye lọjọ kẹrindinlogun nile rẹ to wa layika ile-ẹkọ alakọbẹrẹ Omolere to wa niluu Akure, ipinlẹ Ondo, bẹrẹ lati agogo mẹrin irọlẹ.
O tẹsiwaju pe lẹyin eyi ni wọn yoo gbe baba naa wọ ṣọọṣi St David's Cathedral to wa ni Ijomu niluu Akure bakan naa, bẹrẹ lati agogo mẹwaa owurọ.
Kete ti wọn ba kuro ni ṣọọṣi naa ni wọn yoo fi eeru fun eeru, ati erupẹ fun erupẹ ninu itẹku ile ijọsin ọhun.
Inu ile baba naa ni wọn yoo ti gba awọn eeyan lalejo fun eto wẹjẹ-wẹmu, gẹgẹ bo ṣe ṣalayẹ.
Bakan naa ni awọn mọlẹbi naa tun sọ pe isin idupẹ yoo waye lọjọ Aiku, ogunjọ, oṣu Kejila, ninu ile ijọsin kan naa ọhun.
Awọn mẹlẹbi yii wa n rọ gbogbo eeyan lati maa gbadura fun wọn, ki wọn si yọju lati ṣẹyẹ ikẹyin fun baba awọn to ko ipa ribiribi ko to di pe ọlọjọ de.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Gomina Lucky Aiyedatiwa tipinlẹ Ondo lo kete iku Oloogbe Reuben Fasoranti lọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Gomina Aiyedatiwa ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi agba alẹnulọrọ to fi ipa rere silẹ ko too jade laye.