Seyi Makinde àti ìjọba àpapọ̀ tako ara wọn lórí ₦250b owó NLNG

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde/Bola Tinubu
Ijọba ipinlẹ Oyo ati ijọba apapọ Naijiria ti tako ara wọn lori ọrọ owo kan ti iye rẹ to ₦250b, eyii ti gomina ipinlẹ Oyo sọ pe o yẹ ki wọn san fun awọn ipinlẹ.
Owo naa lo jẹ lara ere ti ijọba ri lati ileeṣẹ Nigeria Liquefied Natural Gas (NLNG), ninu eyii to yẹ ko kan awọn ipinlẹ.
Makinde ni o yẹ ki ijọba apapọ pin owo naa amọ niṣe lo jẹ gaba le lori.
Ẹwẹ, ijọba apapọ ti fesi pe ko si ootọ kankan ninu ọrọ ti Makinde sọ nipa owo naa, ariyanjiyan ọhun si ti n fa gbas-gbos laarin ijọba apapọ atawọn alatilẹyin Makinde.
Ki ni Makinde sọ ni pato?
Nibi ipade kan to da lori eto iṣuna ọdun 2027, ti wọn pe ni Budget Stakeholders' Consultative Engagement, eyii to waye ni gbagede Olola Ogunlana to wa ninu ọgba ile ẹkọ giga, fasiti Ibadan ni Makinde ti sọrọ naa.
Makinde, to n du ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement (APM) sọ pe ijọba apapọ ti na owo ọhun, o si ti pinnu lati ma fun awọn ipinlẹ titi di ẹyin eto idibo Aarẹ ọdun 2027.
O ni "Ni ṣe ni wọn tan wa jẹ. owo ajẹmọnu to yẹ ka gba lọwọ Nigerian LNG, nibo ni owo naa wa?"
Gomina naa ni awọn ti ọrọ kan ti ṣe ohun to tọ lori rẹ, wọn ti si ṣe iṣiro iye to yẹ ko kan awọn ipinlẹ ninu owo ọhun lati tun ilu ṣe.
Makinde tẹsiwaju oe "Wọn ti ṣe iṣiro owo naa, wọn si sọ pe ipinlẹ kọọkan yoo ri owo ti iye rẹ to ₦250b. A ti n jiroro lori awọn akanṣe iṣẹ ti a maa fi owo naa ṣe, eyii ti yoo mu ki ọrọ aje awọn ipinlẹ gbooro.
"Ni bayii wọn wa n sọ pe awọn ko ni san owo naa titi di ẹyin eto idibo. Ṣe eto idibo ṣe pataki ju awọn ọmọ Naijiria ni?
O ni ko tọ ki ijọba di owo to yẹ ko pin fun awọn ipinlẹ mu nitori ede aiyede laarin rẹ atawọn ipinlẹ naa.
"Ṣe ẹyin lẹ ni owo ni? Kilode ti a gbọdọ fi tipa tikuuku ṣiṣẹ fun yin?"
Makinde ninu ọrọ ni ijọba apapọ gbagbọ pe ti oun ba san owo naa fun awọn ipinlẹ, wọn ko ni ṣatilẹyin oun ninu eto idibo ọdun 2027.
Irọ ni Makinde n pa – Ijọba apapọ
Wayi o, ijọba apapọ ti sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ gomina Makinde pe oun gbẹsẹ le owo Nigerian LNG to tọ si awọn ipinlẹ.
Ninu atẹjade ti agbenusọ Aarẹ, Bayo Onanuga fi lede, o ni irọ ni gomina naa pa, ati pe ki awọn araalu maṣe naani ẹsun to fi kan ijọba apapọ.
Ninu atẹjade naa ni Onanuga ti ṣalaye bi ijọba apapọ ṣe maa n pin owo laarin rẹ ati ijọba ipinlẹ, titi kan ijọba ibilẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ti ijọba apapọ ba san ₦250b fun gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria, o n tumọ si pe apapọ owo naa yoo to tiriliọnu mẹsan an naira.
O sọ siwaju si pe gẹgẹ bi wọn ṣe n pin lasiko yii, ijọba yoo nilo ₦33.68 (to jẹ bii $25b) ko to le san iye owo ti Makinde sọ.
Onanuga tun fidi rẹ mulẹ pe NLNG ko tii fi akoko igba kan ri san owo ti iye rẹ to $25b sinu apo ijọba apapọ.
Lẹyin naa lo sọ pe irọ ni ọrọ Makinde ati pe ọrọ aṣinilọna lasan ni ọrọ ọhun.
O tun fẹsun kan Makinde pe o mọọmọ ti oṣelu bọ ọrọ naa ko to fẹsun kan ijọba apapọ dipo ko sọrọ pẹlu ẹru maa jẹ mi rinṣo.
O pari ọrọ rẹ si araalu pe ki wọn masẹ naani ọrọ ti Makinde sọ.
Taa ni ka wa gbagbọ bayii?
Wayi o, bo tilẹ jẹ pe Onanuga ṣe awọn alaye bi ijoba ṣe n pin owo to n wọle ati iye to n pin fun awọn ijọba ipinlẹ, to tun sọ pe NLNG ko san to owo ti Makinde n sọ, ko mẹnuba iye owo pato ti ileeṣe naa ti san ati iye to ti tẹ awọn ijọba ipinlẹ lọwọ.
Bakan naa, awọn ijọba ipinlẹ mii ni Naijiria ko sọrọ soke boya ootọ ni Makinde n sọ tabi mẹnuba iye ti ijọba apapọ ti fun awọn ninu owo naa tabi ko tilẹ fun wọn ni owo kankan ninu rẹ.
Amọ ṣa, ọpọ araalu lo gbagbọ pe ọrọ awọn mejeji ni oṣelu ninu latari bi Makinde ṣe n du ipo Aarẹ lẹyin to kọ lati ṣatilẹyin fun saa keji Tinubu lọdun 2027.




























