Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Published

Ijọba apapọ ti ṣi aṣọ loju eto kan ti wọn sọ pe yoo maye dẹrun faraalu fun aadọrun ọjọ gbako

Eto naa ni wọn pe ni "90-Day Action Plan To Ease Cost Of Living For Nigerians"

Ṣe eyii n tumọ si pe owọngogo ounjẹ ati owo epo yoo walẹ ni, ati pe ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin aadọrun ọjọ?

Lọ soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ

____________________________________________________________

Imaamu Mọṣalaṣi kan ti padanu ipo rẹ lori ẹsun pe o n fi waasi rẹ polongo ibo saa keji fun Aarẹ Bola Tinubu

A gbọ pe gbogbo igba ni imaamu naa maa n sọrọ didundidun nipa Tinubu

Amọ o ti fesi pe oun ko polongo ibo, ohun tou n sọ ni pe ki awọn ọmọ ijọ oun dẹkun ati maa bu Aarẹ nitori ọwọngogo to gbode

____________________________________________________________

Gbajugbaja oṣere tiata nni, Francis Duru ti jade laye

Mọlẹbi rẹ sọ pe o jade laye lẹyin aisan ranpẹ

Ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni Duru ki ọlọjọ to de