South Africa kéde ẹ̀dínwó lórí epo bẹntiróòlù àti dísù, sọ̀rọ̀ lórí owó orí tẹ́tẹ́

Aworan minista feto iṣuna ni South Africa, ọwọ kan to mu foonu dani to n wọ tẹtẹ bọọlu ati ike kan ti wọn da daisi kuro ninu rẹ.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijọba orileede South Africa ti kede ẹdinwo lori epo bẹntiroolu ati disu, fun irọrun ati igbayegbadun araalu.

Awọn alakoso naa sọ pe fun igba diẹ ni ẹdinwo ọhun wa fun, lati le jẹ ki awọn araalu jẹ igbadun iṣakoso ọhun.

Minisita feto iṣuna lorileede naa, Enoch Godongwana sọ pe aarin ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, si ọjọ kinni, oṣu Kejila, ọdun 2026 ni ẹdinwo ọhun yoo fi waye.

Godongwana sọ pe jaala epo kan yoo ja silẹ si R1.50 ($0.09); nigba ti jaala disu kan yoo walẹ si R3 ($0.18).

Awọn araalu yoo jẹ anfaani ẹdinwo yii titi di ọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2027.

Godongwana lasiko to n fi ikede naa sita nile igbimọ aṣofin l'ỌJọru to kọja, tun mẹnuba eto ọrọ aje ati ipawowọle orileede naa.

Minisita feto iṣuna naa sọ pe iye ti awọn tun ti ya ti lọ soke nitori bi owo epo ṣe lọ soke lagbaye, leyi to ṣakoba fun ẹkun Aarin Gbungbun Ila Oorun.

O ni lẹyin ti wọn gbe eto iṣuna wọn kalẹ ninu oṣu Keji, ni ilẹ Israel ati Amẹrika lọ ṣe ikọlu si Iran, to si jẹ ki wọn si Strait ni Homuz pa, eyi to jẹ ko ni ipalara fun idagbasoke orileede naa.

Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe nitori wahala to ṣẹlẹ lẹkun naa to fi mọ agbegbe El Niño, ṣe akoba pupọ fun eto ọrọ aje, leyi to jẹ ki wọn padanu awọn nnkan, paapaa lẹka eto kikọ ọrọ aje lọ sita

"A n foju sọna fun idagbasoke ida kan le ni meji (1.2%) fun ọdun 2026, leyi to ja walẹ ni ida kana ti mẹfa ti a foju sọna fun ninu oṣu Keji," o sọ bẹẹ.

Minisita fi kun ọrọ rẹ pe pẹlu ifasẹyin naa, owo wọle ti wọn n foju sọna fun lọdun 2026 si 2027 lagbara ju ohun ti wọn n foju sọna fun lọ, nitori alekun ninu owo ori ati owo ori ọja to wọle.

Owó epo tó já wálẹ̀

Ijọba ipinlẹ naa sọ pe lati ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla si ọjọ Kinni, oṣu Kejila ni owo epo naa yoo fi ja silẹ.

Minisita feto iṣuna sọ pe ijọba yoo tun sun anfaani ijawalẹ naa siwaju di ọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2027.

O ṣalaye pe ijọba nilo biliọnu mẹwaa owo ilẹ South Africa (R10b) gẹgẹ bi owo iranwọ yii, eyi to le ni miliọnu lọna ẹgbẹfa owo dọla ($608.64m).

Bakan naa lo ni ijọba yoo padanu biliọnu mẹwaa owo South Africa (R10b) nitori awọn nnkan ti wọn fi sinu eto.

Lori bi ijọba yoo ṣe ṣagbatẹru eto naa, Godongwana sọ pe ijọba yoo ri owo naa to pe ni 'Central Energy Fund'.

"Lati na owo lori iranwọ yii, ijọba yoo da owo biliọnu mẹwaa (R10b) pada si 'Central Energy Fund', wọn yoo si daa pada si apo aṣuwọn eto iṣuna, National Revenue Fund, leyi ti yoo si wọnu afipamọ," o sọ bẹẹ.

Owo ori tẹtẹ ori ayelujara

Aworan ike tẹtẹ kan ati daisi rẹ.

Labẹ akoso eto to pe ni 'Medium Term Budget Policy Statement' nile igbimọ aṣofin, minisita ṣalaye pe apo aṣuwọn iṣuna apapọ, ti wọn ṣẹṣẹ gbe kalẹ lọ ni ibamu pẹlu eto owo ori tẹtẹ ori ayelujara (National Online Gambling Tax), ati pe wọn yoo fi abajade ẹkunrẹrẹ sita nipa ọdun 2027.

Ṣugbọn ko sọrọ nipa iye ti owo ori tẹtẹ ori ayelujara yoo jẹ.

Godongwana jẹ ko di mimọ pe oniruuru esi ni awọn ti gba lẹyin ti wọn ṣagbekalẹ aba gbigba owo ori tẹtẹ lori ayelujara.

"Agbeyẹwo ati iwadii ṣi n lọ lọwọ lori afojusun agbekalẹ owo ori tẹtẹ, to fi mọ ilana tuntun lo maa wa nita laipẹ," minisita ṣalaye.

Ọdun 2025 ni ijọba Ghana ti bẹrẹ eto naa lati maa gba ida ogun gẹgẹ bi owo ori tẹtẹ ori ayelujara, eyi ti wọn ni o jẹ alekun ida meji owo ti wọn n ri lọdọọdun.

Ni ti owo ori ayelujara

Aworan  ọwọ kan to mu foonu dani to n wọ tẹtẹ bọọlu.

Nipa ọrọ owo ori ayelujara, minisita ṣalaye pe ọna ọtọọtọ ni ijọba yoo gba lori rẹ, ti wọn yoo si tun erongba wọn ṣe lori agbekalẹ wọn n foju sọna fun.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe oniruuru esi ni iọba ti gba lati ibẹrẹ ọdun yii, to si ni idi niyẹn ti awọn fi gbọdọ ṣagbeyẹwo rẹ daadaa.

Ni ibẹrẹ ọdun yii, ni wọn ti gbe gbogbo afipamọ wọn sita fun awọn eeyan lati mọ, to fi mọ awọn eyi to n lọ lori ayelujara.

"A ni lati maa wo gbogbo owo to n lọ labẹ ofin ni ibamu pẹlu titẹle ilana owo ori sisan, dipo ka kan maa buwọlu iwe," minisita fidi rẹ mulẹ.

Ayipada erongba yii lo waye lẹyin ti awọn alakoso owo ori ayelujara ti tako agbekalẹ ijọba.

Gbigbogun ti iwa ọdaran ati jibiti

Minisita feto iṣuna ni South Africa jẹ ko di mimọ pe ijọba n gbe igbesẹ lati ṣe afikun lati ro ileeṣẹ ọlọpaa lagbara, ati pe owo to le ni miliọnu lọna ẹgbẹrin (R810m) ni wọn ti ya sọtọ fun ọdun to m bọ.

Fun ti ẹka eto idajọ, o ni ijọba ti ya biliọnu meji (R2.2b) silẹ fun ẹka naa lọdun to n bọ, lati rii daju pe ile-ẹjọ ati adajọ ṣiṣẹ wọn lai ni baba iṣalẹ.

Godongwana sọ siwaju pe ijọba tun ti ṣe afikun lori owo ti wọn ya sọtọ fun ẹka to n ri si ẹnu ibode orileede naa, to fi mọ afikun awọn oṣiṣẹ wọn.