Ajọ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN ti fi ẹhọnu wọn
han si ọwọngogo epo bẹntiro to gbode ni Naijiria.
Ninu atẹjade ti ajọ naa fi lede ni wọn ti ni ijiya to
kọja afẹnusọ ni awọn ọmọ Naijiria n fi arar ọ ni asiko yii.
Ajọ naa wa kesi ijọba apapọ lati tete wa wọrọkọ fi se
ada lori iṣẹlẹ ọwọngogo to gbode kan yii.
Aarẹ ẹgbẹ CAN, Archbishop Daniel Okoh ni bio tilẹ jẹpe
o ti to asiko ki wọn yọ owo iranwọ epo lati mu ki orilẹde Naijiria
tẹsiwaju, o ni o yẹ ki wọn se e ni ọna ti ko ni nira jọjọ fun awọn ọmọ
Naijiria.
‘’Nitori ọwọngogo yii ni a se sọrọ soke, ti a si fi
ẹhọnu wa han si ohun to n waye ni awujọ wa.
''Iya ati iṣẹ ti gbode kan, ti nkan ko si rọrun fun awọn
araalu mọ.''
''Nitori naa a n fi asiko yii kesi awọn adari lorilẹede Naijiria
ki wọn wa ọna abayọ si ipenija ti awọn eniyan n koju wọnyii.''
''Asiko ti awọn araalu si n wa ọna atijẹ ati mu lẹyin ti
owo ounjẹ lọ si oke si N540, ti eyi si fa ki owo eto irinna, ounjẹ, ati
awọn ọja gbe pẹẹli soke kaakiri ''
''Eyi mu ki igbeaye nira fun awọn araalu, ti wọn ko tii bọ
nibẹ, ti ọwọngogo miran tun gun ori epo, to fi da N617.''
''Eleyii mu ki alafo to wa laarin awọn ọlọla ati talaka gun
si ju bi o se uẹ lọ, ti awọn araalu ko si ri owo fi se nkan rere mọ tabi ki
wọn tilẹ jẹun.''
''IIsoro yii pọju fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko tilẹ
ria je jẹun tẹlẹ, ki wọn to wa dakun iṣoro wọn.''
Bakan naa ni CAN wa gba ijọba ni imọran lati gbe eto ọrọ
aje Naijiria gba ibomiran lọ, ki iya ati iṣẹ yii le dopin laipẹ fun awọn
araalu.
Wọn ni ki iranwọ ti ijọba fẹ se fun awọn araalu ju owo
perese ti wọn fẹ fun wọn lọ, amọ ki wọn pese eto irinna fun wọn kaakiri
ipinlẹ de ipinlẹ, eleyii ti yoo mu aye rọrun fun awọn araalu.