Ninu igbiyanju
lati riidaju wi pe alaafia j’ọba ni ipinlẹ Bayelsa, Imo, ati Kogi ti eto idibo
yoo ti waye lọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun yii, Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede
Naijiria, Kayode Adeolu Egbetokun gbe ipade alaafia to ṣe kaakiri awọn ipinlẹ wọnyii
de ipinlẹ Kogi l'Ọjọru.
Awọn ọkanojọkan
alẹnulọrọ ni ẹka eto ilera, ẹgbẹ awujọ, oṣiṣẹ eto idibo, awọn adari ilu ati awọn
aṣiwaju ẹsin, ẹgbẹ ọdọ ati awọn ẹṣọ aabo lo pejupesẹ nibi ipade naa to waye ni
ilu Lọkọja tii ṣe olu ilu ipinlẹ Kogi.
Afojusun ipade
naa ni lati sọ asọyepọ, pin iroyin ati lati ṣe eto ti yoo mu ku eto idibo lọ ni
irọwọrọsẹ pẹlu alaafia ni ipinlẹ naa.
Bakan naa ni Egbetokun parọwa si awọn adari ẹgbẹ oṣelu lati ko ipa ti yoo mu ki alaafia j'ọba lai si iwa ipanle laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ati alatilẹyin wọn, ki wọn si riidaju wi pe awọn oludibo ni anfani lati ṣe ojuṣe wọn lai si ifoya.
Nibi ipade naa, oga agba ileeṣẹ ọlọpaa fesi lori fọnran to n lọ kaakiri niluu Anyingba, nibi ti wọn ti fi ẹsun kan wi pe awọn ọlọpaa jawọ ile ọkan lara awọn adari ẹgbẹ oṣelu ni agbegbe naa, gẹgẹ bi o ṣe ke si igbakeji oga agba ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe akoso ẹka iwadiii lori iwa ọdaran, lati ṣe iwadii ọrọ naa, ki wọn le ṣe awari ohun to ṣẹlẹ gan an ni pato.
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa mẹnuba pataki ojuṣe ileeṣẹ naa lati ko akoyawọ lai gbe si ẹyin ẹnikẹni ninu eto idibo naa.
O kilọ fun awọn to n dije du ipo ati awọn alatilẹyin wọn, to fi mọ awọn ẹṣọ aabo pe ẹnikẹni ti o ba tapa si ofin ko ni lọ lai jiya.