Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Ènìyàn 12 ló ti gbẹ́mí mì lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ilé alájà mẹ́rin tó dàwó
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ẹṣọ alaabo
ati awọn panapana ti gbiyanju lati doola ẹmi awọn eniyan lẹyin ti iṣẹlẹ
ile to dawo to waye ni Cameroon.
Ajọ panapana ni o
kere tan eniyan mejila lo tib a iṣẹlẹ naa lọ ni Ọjọ Aiku, ti eniyan to le
ni mọkanlelogun si farapa ninu iṣẹlẹ naa.
Agbegbe Douala ni
iṣẹlẹ ọhun ti waye, ni agbegbe ti awọn eniyan ti n se karakata.
Ile alaja mẹrin naa
lo dawo lori ile miran ni nkan bii aago kan our ni ẹkun ariwa ilu naa.
Ijọba ibilẹ ni
agbegbe naa ni awọn adoola ẹmi ti n wa awọn ti wọn ha si inu ile naa
Ilewosan Laquintinie
ni Douala ni eniyan mẹtala ni wọn ko wa si ibẹ, amọ ọmọdebinrin ọdun
mẹta ati ọdọ ẹni ọdun mọkandinlogun ku ni ileewosan.
Wọn fikun un pe awọn
ọmọde mẹta kan n gba itọju pajawiri lọwọ.
Ìjọba Naijiria wọ́gilé àwọn 'App' ayáni lówó kan
Ààrùn Anthrax kò tíì ran ẹnikẹ́ni ní Naijiria àyàfi àwọn ẹran ọ̀sìn
Ajọ to n gbogun
ti ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC, ti sọ pe aarun Anthrax to ti ran awọn ẹran ọsin
kan ni Naijiria, ko ti ran eniyan kankan.
Ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ
NTA sọ ninu iroyin kan to gbe jade pe olori ajọ NCDC, Dokita Nasir Ahmed, sọ pe
ajọ naa ṣi n ṣe amojuto, to si n fimu finlẹ paapaa ni agbegbe Suleja, ipinlẹ
Niger, nibi ti aarun naa ti kọkọ bẹrẹ ni Naijiria.
Bakan naa lo sọ
pe ijọba, nipasẹ ileeṣẹ eto ilera n ṣe eto ilanilọyẹ lori awọn apẹẹrẹ ti aarun
naa ma n fi han, ati bi eniyan ṣe le dena kiko o.
Ṣaaju ni ijọba
kede pe oun ti ra abẹrẹ ajẹsara lati fi tọju awọn ẹran ọsin niluu suleja.
Awọn ẹran ọsin
ati awọn ẹranko miran to n gbe ninu igbo ma n ko aarun naa ti wọn ba mu omi
tabi jẹ koriko to ni kokoro aarun naa.
Awọn ẹranko to ma
n ṣaba mu ni agutan, maalu, ewurẹ ati igala.
Awọn onimọ iṣegun
oyinbo sọ pe eniyan le ko aarun naa nigba ti wọn ba ni ifarakanra pẹlu ẹranko
to ni i, tabi fi ọwọ kan ohunkohun to wa lati ara ẹranko bẹẹ.
Ijọba fi ikilọ
sita nigba ti aarun naa bu jade ni Naijiria pe, ki awọn eeyan ṣọra fun jijẹ ẹya
ara ẹran ti aisan ba n ṣe.
Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Anthrax to ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Nàìjíríà
Àìsàn Diphteria tún pa ènìyàn mẹ́wàá ní Kaduna, ohun tí a mọ̀ rèé
Ikú dóró! Sunday Igboho pàdánù ìyá rẹ̀
Àjọ ọmọlẹ́yìn Kristi, CAN sọ̀rọ̀ sókè lórí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiró tó gbòde kan
Ajọ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN ti fi ẹhọnu wọn
han si ọwọngogo epo bẹntiro to gbode ni Naijiria.
Ninu atẹjade ti ajọ naa fi lede ni wọn ti ni ijiya to
kọja afẹnusọ ni awọn ọmọ Naijiria n fi arar ọ ni asiko yii.
Ajọ naa wa kesi ijọba apapọ lati tete wa wọrọkọ fi se
ada lori iṣẹlẹ ọwọngogo to gbode kan yii.
Aarẹ ẹgbẹ CAN, Archbishop Daniel Okoh ni bio tilẹ jẹpe
o ti to asiko ki wọn yọ owo iranwọ epo lati mu ki orilẹde Naijiria
tẹsiwaju, o ni o yẹ ki wọn se e ni ọna ti ko ni nira jọjọ fun awọn ọmọ
Naijiria.
‘’Nitori ọwọngogo yii ni a se sọrọ soke, ti a si fi
ẹhọnu wa han si ohun to n waye ni awujọ wa.
''Iya ati iṣẹ ti gbode kan, ti nkan ko si rọrun fun awọn
araalu mọ.''
''Nitori naa a n fi asiko yii kesi awọn adari lorilẹede Naijiria
ki wọn wa ọna abayọ si ipenija ti awọn eniyan n koju wọnyii.''
Oríṣun àwòrán, Others
''Asiko ti awọn araalu si n wa ọna atijẹ ati mu lẹyin ti
owo ounjẹ lọ si oke si N540, ti eyi si fa ki owo eto irinna, ounjẹ, ati
awọn ọja gbe pẹẹli soke kaakiri ''
''Eyi mu ki igbeaye nira fun awọn araalu, ti wọn ko tii bọ
nibẹ, ti ọwọngogo miran tun gun ori epo, to fi da N617.''
''Eleyii mu ki alafo to wa laarin awọn ọlọla ati talaka gun
si ju bi o se uẹ lọ, ti awọn araalu ko si ri owo fi se nkan rere mọ tabi ki
wọn tilẹ jẹun.''
''IIsoro yii pọju fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko tilẹ
ria je jẹun tẹlẹ, ki wọn to wa dakun iṣoro wọn.''
Bakan naa ni CAN wa gba ijọba ni imọran lati gbe eto ọrọ
aje Naijiria gba ibomiran lọ, ki iya ati iṣẹ yii le dopin laipẹ fun awọn
araalu.
Wọn ni ki iranwọ ti ijọba fẹ se fun awọn araalu ju owo
perese ti wọn fẹ fun wọn lọ, amọ ki wọn pese eto irinna fun wọn kaakiri
ipinlẹ de ipinlẹ, eleyii ti yoo mu aye rọrun fun awọn araalu.
‘’ Ìjìyà tó lágbára jùlọ ní ayé ló tọ́sí ẹni tó bá sọ̀rọ̀ lòdì sí Qur’an,’’
Oríṣun àwòrán, Reuters
Olori ẹsin Islam, Ayatollah Ali Khamenei ti sọ pe
ẹnikẹni to ba sọrọ lodi si Quran gbọdọ foju wina ijiya to lagbara julọ
lagbaye.
Eyi ko ṣẹyin ifẹhọnuhan tako ẹsin Islam ati Quran to
waye ni orilẹede Sweden, to fi mọ Denmark naa.
Awọn to fẹhọnuhan naa ni iroyin gbe pe o ṣeese ki wọn
tẹ Quran mọlẹ, tabi ki wọn sọrọ tako rẹ lasiko ifẹhọnuhan naa.
Ayatollah ni idahun si iṣẹlẹ yii bu ẹnu atẹ lu iru
igbesẹ bẹẹ, to si ni awọn to n hu iru iwa bẹẹ ko dara to.
Bakan naa lo kesi ijọba orilẹede Sweden lati fi panpẹ
ọba mu awọn to hu iru iwa bẹẹ, to si ni ki wọn yonda wọn fun awọn
orilẹede ti wọn n se ẹsin Musulumi lati se idajọ wọn.
O ni gbogbo awọn
onimọ nipa Islam lo ti buwọlu pe ẹnikẹni to ba sọrọ tako Qur’an naa yẹ
fun ijiya to gajulọ ni aye.
To si ni ohun to tọ ni ki ijọba Sweden jọwọ awọn
afẹhọnuhan naa nitori ọdaran ni wọn, ki wọn si fi wọn jofin.
Ẹwẹ, awọn onimọ Islam ti kede pe ki wọn pa ọmọbinrin
kan ti wọn ni o sọ ọrọ odi si Prophet Muhammed SAW.
Wo ohun to ṣẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn tí Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ṣe ikọlu sí ibùba IPOB
Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Ileeṣẹ ologun ni Naijiria sọ pe awọn ti ri ọkan ninu awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi IPOB mu bẹẹ si ni awọn ri nkan ija oloro gba lọwọ awọn ọdaran yii.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi soju opo Twitter wọn ni wọn ti kede ọrọ yi.
Onyema Nwachukwu to jẹ ọga ẹka ibaraẹnisọrọ ileeṣẹ naa sọ pe ṣaaju lawọn ti kọkọ ṣe ikọlu si ibuba awọn ikọ yi lowurọ ọjọ Abamẹta ninu igbo kijikiji kan ni ilu Asaba.
O ni nigba tawọn tọ awọn to salọ ninu awọn agbesunmọmi yi lọwọ tẹ ọkan ninu wọn tawọn si gba nkan ija ni ibọn AK47 marun un,ibọn ṣakabula mẹrin, ọta ibọn ati alupupu to fi mọ foonu tawọn ikọ yi n lo,
Aworan awọn nkan tawọn ologun lawọn ri gba ree gẹgẹ bi wọn ṣe fi han loju opo Twitter wọn.
Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Iṣẹ́ bọ lọ́wọ́ Ọgá àgbà, igbákejì àjọ tó n mójútó ìpèsè àti lílò òògùn
Oríṣun àwòrán, WHO
Àkọlé àwòrán, Aworan oogun to ṣeku pa awọn ọmọde ni The Gambia
Ijọba orileede Gambai ti fọwọ osi juwe ile fun ọga agba ajọ to n mojuto ipese oogun nilẹ naa ati igbakeji rẹ.
Igbesẹ yi ko ṣẹyin abọ igbimọ iwadii ti ijọba gbe kalẹ to ṣafihan pe ajọ naa ko forukọ ileeṣẹ apoogun ilẹ India kan ni ibamu pẹlu ofin ilẹ ọhun.
Ileeṣẹ yi ni wọn lo lọwọ si iku awọn ọmọde aadọrin to lo oogun ikọ ayederun ileeṣẹ naa,
Markieu Janneh Kaira ati Foumata Jah Sowe ni ọga agba ati igbakeji ajọ to n mojuto ipeese ati lilo oogun lorileede The Gambia.
Wọn lawọn mejeeji ko ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ koda wọn ti fa awọn mejeeji le ọlọpaa lọwọ fẹkunrẹrẹ iwadii.
Igbimọ iwadii ti ijọba gbe kalẹ tun sọ pe ileeṣẹ to pọn oogun naa ni India lọwọ ninu iku awọn ọmọde to lo orisi oogun mẹrin ti ileeṣẹ yi pọn gẹgẹ bi ajọ ilera lagbaye WHO ti ṣe sọ.
Bakan naa ni ijọba gba iwe aṣẹ lọwọ ileeṣẹ 'Atlantic Pharmacy Company Limited' to ṣe atọna fun ileeṣẹ apoogun taa n wi yi.
Ṣugbọn ileeṣẹ apoogun 'Maiden Pharmaceuticals', to pọn awọn oogun to ṣokunfa iku awọn ọmọde yi sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ pe oogun awn ṣekupa awọn ọmọde yi.
Wọn ni esi ayẹwo tawọn alaṣẹ orileede India gbejade fihan pe ko si nkankan to ṣe oogun tawọn pọn.
Titi di asiko yi, kosi ẹni le sọ pato aawọ ti iṣẹlẹ yi lu da silẹ laarin ijọba The Gambia, ileeṣẹ to ṣatọna Maiden Pharmaceuticlas ati ileeṣẹ to n mojuto pipọn oogun wọnyi.
Olubadan ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn Alaagba, yí ìpinnu rẹ̀ padà
Ẹ kéde mi bí ẹni tó jáwé olúborí ìbò Ààrẹ - Atiku sọ fún ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò
Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic
Party, PDP, nínú ètò ìdìbò tó kọjá, Alhaji Atiku Abubakar ti rọ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́
ẹ̀hónú ìbò láti kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò náà.
Atiku Abubakar ní àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC
gbà wí pé ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún ni òun ti gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.
Atiku sọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Ẹtì nínú ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn èyí tí òun
àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ gbé kalẹ̀ fún ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà láti fi tako
ìjáwe olúborí Tinubu.
Nínú ọ̀rọ̀ náà èyí tí agbẹjọ́rò rẹ̀, Chris Uche ní INEC kò sọ
wí pé àwọn ṣe àṣìṣe bí wọ́n ṣe ti ṣaájú sọ wí pé òun jáwé olúborí ní ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n
títí tí ìgbẹ́jọ́ náà fi parí.
INEC nínú èsì sí ẹjọ́ tí Atiku pè ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún
ni Atiku tí jáwé olúborí.
Àwọn Ìpínlẹ̀ tí INEC kà kalẹ̀ pé Atiku tí jáwé olúborí ni
Adamawa, Akkwa Ibom, Bauchi, Bayelsa, Borno, Delta, Ekiti, Gombe, Jigawa,
Kaduna, Katsina, Kebbi, Kogi, Kwara, Nasarawa, Niger, Osun, Sokoto, Taraba,
Yobe àti Zamfara.
Ó ní láti ìgbà náà títí tí ìgbẹ́jọ́ náà fi parí kò sí ìgbà
tí INEC fi yí ọ̀rọ̀ náà padà.
Ó ní èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni ẹni tó yẹ kí wọ́n kéde gẹ́gẹ́
bí Ààrẹ nítorí náà kí Adájọ́ gbé ipò náà fún òun.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ènìyàn mẹ́rin lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ní kí àwọn obìnrin méjì rìn ní ìhòhò
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹede
Inidia ni ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin mẹrin kan lori ẹsun pe wọn ni ki obinrin rin
ni ihoho ni gbangba ni agbegbe ariwa orilẹede naa.
Agbegbe naa lo ti n koju
ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ, ti eniyan 120 si ti ba iṣẹlẹ naa lọ.
Awọn mẹrin ti ọwọ tẹ naa
ni wọn ri ninu fidio to ja ranyin ni osu karun un nibi ti awọn araalu ti n rin
obinrin meji naa ni ihoho.
Ileeṣẹ ọlọpaa loju opo
Twitter wọn ni awọn mẹrin to wa ni idi iṣẹlẹ naa ni ọwọ awọn ti tẹ.
Awọn obinrin naa ni
fidio ṣafihan ti wọn n rin ni ihoho, ti awọn araalu si n fi wọn ṣe yẹyẹ.
Agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti
waye ni kosi ẹrọ ayelujara nitori ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ to waye nibẹ.
Ijọba ton ṣe akoso
agbegbe naa, Bharatiya Janata Party, BJP ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe igbeṣẹ naa lẹyin
ti fidio ọhun jade si ori ẹrọ ayelujara.
Oríṣun àwòrán, Others
Wọn fikun un pe iwadii lẹkunrẹrẹ
lai yọ ẹnikẹni kuro n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa
Bakan naa ni wọn ṣeleri
pè awọn to hu iru iwa bẹẹ yoo fi oju wina ofin.
Ti wọn si ni o ṣeeṣẹ ki
ijiya to tọsi wọn gba ọna iku lọ.
Ifẹhọnuhan naa lo bẹ silẹ
lasiko ti ija waye ni Manipur, nitori awọn araalu ti ko ri iṣẹ ijọba ati awọn
anfaani miran.
Awọn afẹhọnuhan naa ṣekọlu
si ile ijọsin ati awọn ile miran ni agbegbe naa, ti ẹgbẹgbẹrun eniyan si na
papa bora ni agbegbe naa.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin tó na obìnrin yìí dojú ikú tí wọ́n tún ju òkú rẹ̀ s' ódò adágún ilé ìtura
Ọkọ, ìyàwó, ọmọ méjì àti èèyàn méjì míì kú lẹ́yìn tí wọ́n kó sílé tuntun
Davido pín ₦237m fáwọn ọmọ aláìníìyá yíká Nàìjíríà
Adebutu takú pé ẹbu ìwé ẹ̀rí WAEC ni Abiodun ń lò, WAEC kọ̀ láti fi ẹ̀dà ìwé ẹ̀rí ránṣẹ́ sí ‘Tribunal’ l‘Ogun
Irọ́ ni pé wọ́n fẹ́ fi orò lé àwọn àjòjì kúrò ní Eko - Ìjọba
Oríṣun àwòrán, LASG
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ní kí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ náà má tẹ́tí
sí ìròyìn kan tó gba orí ayélujára pé orò fẹ́ jáde ní àwọn agbègbè kan.
Ṣáájú ni ìròyìn ti gba orí ayélujára pé orò fẹ́ jáde ní àwọn
àdúgbò kan lọ́jọ́bọ̀, ogúnjọ́ àti ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Keje láàárín
aago méjìlá sí aago márùn-ún àbọ̀ ìdájí àwọn ọjọ́ náà.
Lára àwọn àdúgbò tí wọ́n ní orò náà ti máa wáyé ni
Ikate,Ijora-Badiya, Amuwo-Odofin,
Ojota, Ikorodu àti Somolu-Bariga àti agbègbè rẹ̀.
Bákan náà ni wọ́n tún dárúkọ Igbobi-Sabe, Ojodu-Isheri,
Isolo-Okota-Ilasamaja, Ejigbo-Idimu, Isheri-Ijegun, Ikotun-Igando, Iba,
Lawanson-Itire àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ohun tí wọ́n kọ sórí ìròyìn náà ni pé kí àwọn obìnrin àti àwọn
tí kìí bá ṣe ọmọ Eko ó fi ara pamọ́ láwọn àsìkò tí orò fi fẹ́ jáde náà pé ọmọ
onílùú fẹ́ ṣe orò.
Ẹ̀wẹ̀, agbenusọ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Gboyega Akosile nígbà tó
ń bá akọ̀ròyìn PUNCH sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní Alausa, Ikeja ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́
ni ìròyìn náà.
Akosile rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láti máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn
lọ pé kò sí nǹkan tó jọ pé orò kankan fẹ́ wáyé.
Ó ní kò sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá àti pé kìí ṣe ohun tó yẹ
kí ìjọba tilẹ̀ máa dá sí ni.
Wo ọ̀nà mẹ́sàn-án tí ìjọba ìpínlẹ̀ àti àpapọ̀ yóò fi mú àdínkù bá ìyà aráàlú torí ọ̀wọ́n owó epo
Ènìyàn méjì farapa níbi ìjàm̀bá ọkọ̀ òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan
Oríṣun àwòrán, @drizzie99
Kò dín ní ènìyàn mẹ́jọ tí orí kó yọ lọ́wọ́ ikú nígbà tí
ìjàm̀bá ọkọ̀ kan wáyé ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan lọ́jọ́rú.
Ìròyìn ní ọkọ̀ ńlá kan tó kó àwọn màálù ló lọ kọlu àwọn ọkọ̀
ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́ta mìíràn.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ènìyàn méjì farapa níbi
ìjàm̀bá ọ̀hún.
Ní agbègbè Sagamu Interchange ni ọkọ̀ ńlá náà pàdánù ìjánu rẹ̀
tó sì lọ kọlu ọkọ̀ Toyota Hiace méjì, Toyota SUV kan àti ọkọ̀ ńlá kan mìíràn.
Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ Azeez Olayiwola gẹ́gẹ́ bí ìwé
ìròyìn PUNCH ṣe sọ ní awakọ̀ ọkọ̀ ńlá náà kò iwájú láti mọ̀ wí pé súnkẹrẹ fàkẹrẹ
ọkọ̀ wà ní iwájú rẹ̀ tó sì ń sáré bọ̀.
Olayiwola ní ìgbà tí awakọ̀ náà máa fi súnmọ́ àwọn ọkọ̀ náà
kò ríbi mú àdínkù bá eré tó ń sá, tó sì lọ kọlu àwọn ọkọ̀ tó wà níwájú rẹ̀.
Nígbà tó ń fìdí ìjàm̀bá náà múlẹ̀, Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń mójútó
ojú pópó (FRSC) tí ìpínlẹ̀ Ogun, Ahmed Umar ní àwọn méjì tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀
náà ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn.
Ó ní ènìyàn mẹ́jọ ló wà nínú àwọn ọkọ̀ tí ìjàm̀bá náà kàn àmọ́
àwọn méjì ló farapa tí wọ́n sì ti wà ní ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Irọ́ ni o, mi ò pé Tinubu lórí ìgbẹ́jọ́ ẹ̀hónú ìbò to ń wáyé ní Abuja - Adájọ́ àgbà, Ariwoola
Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ìyẹn Supreme
court tí jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀ tó gba ìgboro pé Adájọ́ àgbà Nàìjíríà, Olukayode
Ariwoola bá Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ ètò ìdìbò sípò Ààrẹ.
Ariwoola ní òun kò tún ní àjọsọ kankan pẹ̀lú Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́
ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS, Yusuf Bichi.
Adájọ́ àgbà náà ní ilé ẹjọ́ kò ní èròńgbà láti ṣègbè lẹ́yìn ẹnikẹ́ni
kò bá à jẹ́ Tinubu, olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Atiku
Abubakar tàbí olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí adarí ètò ìròyìn ilé ẹjọ́ náà, Dókítà
Festus Akande fi léde lọ́jọ́rú ní kò sí òótọ́ nínú ìròyìn tí àwọn kan ń gbé
kiri lórí ayélujára.
Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa ṣe àtìlẹyìn fún ẹ̀ka ètò
ìdájọ́ kí wọ́n lè máa ṣe ojúṣe wọn bó ṣe yẹ.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ará ìlú ti ń bá ẹjọ́ tó ń wáyé lórí
awuyewuye lórí ètò ìdìbò sípò Ààrẹ lọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nítorí náà kò yẹ kí wọ́n
fààyè àhesọ ọ̀rọ̀ tí kò ní so èso rere lórí ejò náà.
Ó fi kun pé tí àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ bá ti ń tàn kalẹ̀ ju bó ṣe
yẹ lọ, orílẹ̀ èdè kò ní tẹ̀síwájú àti pé ìdásílẹ̀ àwọn ilé ẹjọ́ wáyé láti jà
fún ará ìlú ni.
Ariwoola ní bíbọ̀wọ̀ fún òfin àti tí tẹ̀lé àlàkalẹ̀ ìwé òfin
Nàìjíríà nínú gbogbo àwọn ẹjọ́ ni òun to máa ń jẹ àwọn lógún ní gbogbo ìgbà.
Bákan náà ló fi àwọn ènìyàn lọ́kàn balẹ̀ pé ìdájọ́ òdodo ló
máa wáyé nínú gbogbo àwọn ẹjọ́ tó ń lọ ní àwọn ilé ẹjọ́ káàkiri Nàìjíríà.
Gomina Adeleke yan àwọn Kọmísọ́nà rẹ̀, ohun náà náwọ́ gan ipò kọ́misọ́nà kan fún ara rẹ̀