Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Ètò ìdìbò kò tíì bẹ̀rẹ̀ ní agbèègbè Cantonement ní Lokoja
O yẹ ki eto idibo ti bẹrẹ ni Ward B, unit 006, ni agbegbe 'Cantonement' niluu Lọkọja, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo yari wi pe awọn ko ni ko ohun elo bọọlẹ ninu ọkọ, nitori pe awọn ẹṣọ abọ ko tii de.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ naa ṣe alaye fun wa wi pe awọn kan ti ba ara wọn ja laarọ oni ni ibudo idibo naa, eyii lo mu wọn takete pe o di igba ti awọn agbofinro ba de ki eto idibo to bẹrẹ.
Àjọ elétò ìlera tó n mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, ‘Red Cross’, wà ní ìkàlẹ̀ níbi ètò ìdìbò tó n lọ lọ́wọ́ n’ìpínlẹ̀ Kogi
Wọn ni pe ko ni si aaye pẹ ẹnikan wa farapa ko dẹ wa ri itọju lasiko ni ipinlẹ Kogi.
Àwọn Eléso dúró pé kí ebi Kó má pa àwọn olùdìbò ní agbègbè Zango Daji primary school PU - Lokoja - Kogi
Àwọn Eléso dúró pé kí ebi Kó má pa àwọn olùdìbò ní agbègbè Zango Daji primary school PU - Lokoja - Kogi
Wọ́n jí òṣìṣẹ́ àjọ INEC gbé ní Bayelsa, bí àwọn 12 míràn ṣe móríbọ́ nínú ọkọ̀ ojú omi tó dànù, Adarí ẹ̀ka ìlanilọ́yẹ àjọ INEC wí pé èyí kò níí dá àwọn dúró
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nkan ko ṣe ẹnu re fun ajọ eleto idibo ilẹ yii (INEC), ni
ipinlẹ Bayelsa ni bi oṣiṣẹ ajọ naa kan to jẹ alamojuto ibo (SPO) ni wọọdu
Ossioma nijọba ibilẹ Sagbama ṣe bọ sọwọ awọn ajinigbe nibi ti o tin duro lati wọ
ọkọ oju omi ni etido Amassoma.
Adari ẹka ilanilọyẹ lajọ naa, Wilfred Ifogah, to fi ọrọ
yii lede ninu atẹjade kan wi pe awọn ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.
Bii pe ẹni ti wọn ji gbe o tii to, awọn mejila miran to
tun jẹ oṣiṣẹ ajọ naa ni ori koyọ ninu ijamba ọkọ oju omi nigba ti ọkọ ti awọn oṣiṣẹ
naa wa ninu rẹ dojude lakoko ti wọn n ko nkan idibo lọ wọọdu Koluama, nijọba
ibilẹ Guusu Ijaw.
Atẹjade naa wi pe “O jẹ ohun idunnu pe a ko padanu ẹnikẹni
bi wọn ṣe doola ẹmi awọn oṣiṣẹ mejila naa ati awakọ wọn”.
Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹnikẹni to farapa, lara awọn ohun elo
idibo ti wọn ko dani bii iwe esi ibo, ẹrọ ilewọ amunaọwa (power bank) ati ẹru
awọn oṣiṣẹ naa lo b’odo lọ.
Ifogah wi pe “iye awọn to forukọ silẹ ni agbeegbe naa jẹ ẹgbẹẹdọgbọn
ati ejidinlaadọriinlelọọdurun (5368), ti awọn to gba kaadi idibo alalopẹ si jẹ ẹgbẹẹdọgbọn
ati ọkanlelẹwaalelọọdurun (5311)”.
O fi kun un pe ajọ INEC n sagbogbo ipa rẹ lati ri pe eto
idibo waye lagbeegbe naa.
Àjọ INEC ti pín àwọn ohun èlò fún ètò ìdìbò n'ípínlẹ̀ Kogi, Àjọ INEC ti bẹ̀rẹ̀ síní pín àwọn ohun èlò fún ètò ìdìbò n'ípínlẹ̀ Kogi
Ajọ eleto idibo,
INEC ti bẹrẹ sini pin awọn nnkan elo fun eto idibo ati iwe akọsilẹ abajade ibo
ni ẹka banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN, to n bẹ ni Lọkọja, olu ilu ipinlẹ
Kogi.
Ninu ọrọ ti o ba
awọn oniroyin sọ l'Ọjọbọ nibi ti wọn ti n ṣe eto naa, adari itaniji ati ilanilọyẹ
fun awọn oludibo fun ajọ INEC n'ipinlẹ Lọkọja, Aliru Haruna Sule ṣe alaye wi pe
ajọ naa ti pese awọn ohun elo ti o to lati dibo ninu eto idibo ti yoo waye ni
Satide ọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun yii n'ipinlẹ Kogi.
O ni awọn ọkọ ti
yoo pin awọn ohun elo naa ti wa n'ikalẹ, bẹẹ sini awọn ẹṣo aabo ti yoo maa
mojuto igbokegbodo awọn ohun elo naa jakejado awọn ijọba ibilẹ mọkanlelogun to
n bẹ n'ipinlẹ naa ti n duro wamuwamu.
Sule ni gbogbo
ibudo ti idibo yoo tiwaye ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa yoo ti ni anfani lati ṣe onka
ati akọsilẹ abajade ibo, dipo bi alakoso ajọ naa ni ijọba ibilẹ ṣe maa n ṣee tẹlẹri.
O parọwa si awọn oludibo lati jade lọ ṣe ojuṣe wọn lọjọ idibo lai si ifoya
kankan. O fi kun ọrọ rẹ wi pe ẹni ti o ba ni ero tabi eto buburu nikan ni ko ni
jade lati lọ dibo lọjọ Abamẹta.
Àwọn ọ̀nà láti fi dá ìròyìn òfégè mọ̀ lásìkò ìbò 2023
Àwọn nǹkan tí o gbọ́dọ̀ mọ̀ kí o tó lọ sí ibùdó ìdìbò nìyí
Ọ̀gá àgbà Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣe ìpàdé àlàáfíà pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ saaju ètò ìdìbò Ìpínlẹ̀ Kogi, Afojusun ipade naa ni lati sọ asọyepọ, pin iroyin ati lati ṣe eto ti yoo mu ku eto idibo lọ ni irọwọrọsẹ pẹlu alaafia ni ipinlẹ naa.
Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi
Ninu igbiyanju
lati riidaju wi pe alaafia j’ọba ni ipinlẹ Bayelsa, Imo, ati Kogi ti eto idibo
yoo ti waye lọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun yii, Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede
Naijiria, Kayode Adeolu Egbetokun gbe ipade alaafia to ṣe kaakiri awọn ipinlẹ wọnyii
de ipinlẹ Kogi l'Ọjọru.
Awọn ọkanojọkan
alẹnulọrọ ni ẹka eto ilera, ẹgbẹ awujọ, oṣiṣẹ eto idibo, awọn adari ilu ati awọn
aṣiwaju ẹsin, ẹgbẹ ọdọ ati awọn ẹṣọ aabo lo pejupesẹ nibi ipade naa to waye ni
ilu Lọkọja tii ṣe olu ilu ipinlẹ Kogi.
Afojusun ipade
naa ni lati sọ asọyepọ, pin iroyin ati lati ṣe eto ti yoo mu ku eto idibo lọ ni
irọwọrọsẹ pẹlu alaafia ni ipinlẹ naa.
Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi
Bakan naa ni Egbetokun parọwa si awọn adari ẹgbẹ oṣelu lati ko ipa ti yoo mu ki alaafia j'ọba lai si iwa ipanle laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ati alatilẹyin wọn, ki wọn si riidaju wi pe awọn oludibo ni anfani lati ṣe ojuṣe wọn lai si ifoya.
Nibi ipade naa, oga agba ileeṣẹ ọlọpaa fesi lori fọnran to n lọ kaakiri niluu Anyingba, nibi ti wọn ti fi ẹsun kan wi pe awọn ọlọpaa jawọ ile ọkan lara awọn adari ẹgbẹ oṣelu ni agbegbe naa, gẹgẹ bi o ṣe ke si igbakeji oga agba ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe akoso ẹka iwadiii lori iwa ọdaran, lati ṣe iwadii ọrọ naa, ki wọn le ṣe awari ohun to ṣẹlẹ gan an ni pato.
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa mẹnuba pataki ojuṣe ileeṣẹ naa lati ko akoyawọ lai gbe si ẹyin ẹnikẹni ninu eto idibo naa.
O kilọ fun awọn to n dije du ipo ati awọn alatilẹyin wọn, to fi mọ awọn ẹṣọ aabo pe ẹnikẹni ti o ba tapa si ofin ko ni lọ lai jiya.
Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi
Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi
Alásè ọmọ orílẹ̀-èdè Ireland gba adé Guinness World Records mọ́ Hilda Baci lọ́wọ́
Wo àwọn gbajúmọ̀ tí wọ́n pàdánú ẹ̀mí wọn lẹ́ni ọdún 27
Gómìnà Otti faraya bí wọ́n ṣe ṣàwárí òkú ènìyàn tó lé ní àádọ́rin ní ẹ̀gbẹ́ ọjà ẹran
Oríṣun àwòrán, Alex/Getty Images
Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Alex Otti ní àwọn ṣe àwárí òkú tó ti gbẹ
tó lé ní àádọ́ta tó fi mọ́ àwọn tí kò ní orí mọ́ nínú igbó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọjà ẹran
Lokpanta tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Umunneochi ní òpópónà Enugu sí Port Harcourt.
Gómìnà Otti ní àwọn tún ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn ajínigbé kan máa
ń lo ọjà náà láti gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àwọn tí wọ́n bá jí gbé.
Lásìkò tí gómìnà Otti ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ló tú pẹrẹpẹ́rẹ̀
sílẹ̀ pé àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn kan ti sọ ọjà náà di orikò wọn níbi tí
wọ́n ti máa ń hu àwọn ìwà kò tọ́.
Ó ní àwọn kan máa ń ta oogun olóró, ìbon àtàwọn nǹkan míì tó
lòdì sí òfin nínú ọjà náà.
Ó ní egungun òkú ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé ni àwọn rí ní
ẹ̀bá ọjà náà.
Ó ṣàlàyé pé èyí ló mú àwọn gbé àwọn ìgbésẹ̀ tuntun lórí ọjà ọ̀hún
àti pé àwọn kò ní gba àwọn ọ̀daràn kankan láyé láti fi ìpínlẹ̀ Abia ṣe
ibùjókòó.
Ó fi kun pé ìpinnu ìjọba láti sọ ọjà náà di ọjà ojoojúmọ̀
nìyí àti pé kìí ṣe pé àwọn fi tako ẹ̀yà kan bíkòṣe láti mú kí ètò ààbò ìpínlẹ̀
náà gbópọn si.
Gómìnà Otti fi kun pé àwọn ti pèsè ẹ̀rọ ayàwòrán sí gbogbo
inú ọjà náà láti lè mú kí ètò ààbò tó dájú wà ní tìbú tòró ọjà ọ̀hún.
Bákan náà ló ní gbogbo àwọn tó ń sùn nínú ọjà náà tẹ́lẹ̀ ti
ń sùn ní ìgboro àti pé àwọn máa mọ odi yí ọjà náà ká láti lè túnbọ̀ pọn kún ètò
ààbò ọjà náà.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin da àbá láti sọ ìdánwò WAEC, NECO, JAMB di ọ̀fẹ́ nù
Wo kókó mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara
Alága tuntun EFCC pàṣẹ fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láti kéde iye dúkìá tí wọ́n ní
Oríṣun àwòrán, Ola Olukoyede/FACEBOOK
Alága àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC, Ola
Olukoyede ti darí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà láti kéde iye dúkìá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan
wọn ní.
Olukoyede tó kéde ìdarí náà ní olú Iléeṣẹ́ EFCC tó wà ní
Abuja ní ìgbésẹ̀ náà wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó de àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà.
Ó ní ó pọn dandan fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń
gbógun ti ìwà àjẹbánu gbọ́dọ̀ wẹ ọwọ́ náà mọ́ dáradára.
Ó ṣàlàyé pé gbogbo àwọn tí àwọn n ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ náà ni
àwọn máa kéde dúkìá àwọn àti pé àwọn ènìyàn kò nílò láti bẹ̀rù ohunkóhun tí wọn
kò bá ti lẹ́bọ lẹ́rù.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale ní bí ó tilẹ̀
jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ kan ti kéde dúkìá wọn tẹ́lẹ̀ rí, ó ní wọ́n máa tun kéde
báyìí.
Bákan náà ló ní àwọn máa ṣèwádìí àwọn dúkìá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan
bá kéde láti fìdí òótọ́ múlẹ̀ lórí àwọn dúkìá náà.
Olukoyede tún pàrọwà sí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà láti ní ìfarajìn
sí iṣẹ́ wọn àti ìdí rẹ̀ tí wọ́n ṣe ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ.
PDP ń pè fún yíyọ Akeredolu nípò gómìnà l’Ondo, APC ní àìríkanṣèkan ló ń da PDP láàmú
Ọmọdé mẹ́rin kú lásìkò tí ògiri ṣọ́ọ̀ṣì dà wó
Awọn ọmọde mẹrin ti padanu ẹmi wọn lorileede Burundi lẹyin ti ile ijọsin kan wo lasiko ojo.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin ijọba nilẹ naa ṣe sọ awọn eeyan mẹẹdogun mii farapa ninu iṣẹlẹ naa to waye lowurọ ọjọ Aiku.
Apa guusu ilẹ naa nibi ti ile ijọsin yi wa jẹ ibi to ti n koju afẹfẹ lile ati arọrọda ojo lẹnu lọọlọ yi.
Ogiri ile ijọsin yi kan lo wo lo awọn ọmọde wọnyi ti wọn n kopa ninu isin idanilẹkọ ni ṣọọṣi naa.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjọba Ogun fèsì lórí fídíò ìrẹsì "palliative" tó gba orí ayélujára
Ọwọ́ ọlọ́pàá tún padà tẹ afurasí ayédèrú dókítà tó sá làhámọ́
Awọn ọlọpaa lorileede South Africa ti kede pe awọn ti tun arakunrin kan to sa ni ahamọ wọn mu pada.
Kingsley Leeto Chele, jẹ ẹni ti wọn fẹsun kan pe ayederu dokita nii ṣe.
Loju opo ayelujara a maa pe ara rẹ ni Dr Kingsley Chele tabi Dr KJ Ncube.
Ninu iroyin to taa jabọ tẹlẹ lọsẹ to kọja, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti bẹrẹ si ni wa afurasi yi to sa mọ awọn lọwọ.
Wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi oni gbajuẹ oju opo Facebook to n parọ tan awọn obinrin.
Bayii, wọn ni ọwọ awọn ti tẹ ẹ pada lowurọ kutu ọjọ Aje ni Vosloorus lẹba Johannesburg lẹyin ti ileeṣẹ iroyin kan tawọn lolobo ibi to sa pamọ si.
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Gauteng lawọn mọ riri ipa ti ileeṣẹ iroyin yi ko ati ni paapa tawọn araadugbo nipa kikoju iwa ọdaran.
Bẹẹ ni atẹjade kan lati ọdọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe wi.
Afurasi yi ti wọn ko mọ ọmọ orileede ibi to ti wa yoo foju ba ileẹjọ ni Pretoris lọjọ Iṣẹgun gẹgẹ bo ṣe wa ninu eto ko to sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ.
Pẹlu binkan ṣe ri yi, wọn ti fi ẹsun pe o sa mọ ọlọpaa lọwọ kun eleyiii to n koju tẹlẹ.
Ẹsun onigun meji ni wọn fi kan tẹlẹ to da lori gbajuẹ-o sọ fawọn akọṣẹmọṣẹ ilera loju opo Facebook pe oun n wa awọn ti yoo dowo pọ pẹlu rẹ ko to lu wọn ni gbajuẹ.
Titi di asiko yi, Ọgbẹni Chele ko tii sọrọ nipa awọn ẹsun wọnyi.
Oríṣun àwòrán, SA Police Service
'Ifá ló yẹ kí a máa lò láti fi yan àwọn olóṣèlú tí a bá fẹ́ yan adarí rere'