Ayálégbé ni Tinubu ní Aso Rock, dúkìá gbogbo wa ni – Owoyele Sowore

Àkọlé fídíò, Ayálégbé ni Tinubu ní Aso Rock, dúkìá gbogbo wa ni – Owoyele Sowore
Ayálégbé ni Tinubu ní Aso Rock, dúkìá gbogbo wa ni – Owoyele Sowore
Published

Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC, Omoyele Sowore ti sọ pe ayalegbe lasan ni Aarẹ Bola Tinubu nile ijọba Aso Rock, araalu lo ni ile ọhun.

Sowore lo sọrọ naa lasiko to n ba BBC sọrọ nipa lẹta kan ti AAC kọ si ijọba apapọ pe ẹgbẹ oun fẹ lo ile ijọba ọhun fun eto ẹgbẹ rẹ.

O ni ti ẹgbẹ oṣelu APC ba le maa lo ile ijọba naa fun awọn eto rẹ atawọn eto mii awọn naa gbọdọ ni anfani si nitori dukia ajọni lo jẹ.

Sowore sọ pe "A jọ ni Aso Rock ni, kii ṣe ile Bola Tinubu.

"Awọn n ṣe ẹgbẹ tiwọn ninu Aso Rock, gbogbo igba ni wọn n ṣepade nibẹ. Igba mii gan wọn a lọ ṣe igbeyawo nibẹ, igbamii wọn a lọ ṣe isọmọlorukọ nibẹ.

"A wa nipe, ẹgbẹ kan o le lo Aso Rock ki ẹ wa sọ pe ẹgbẹ keji ko le lo Aso Rock. Gbogbo wa la jọ ni Aso Rock, owo wa ni wọn fi kọ. Ayaleggbe ni Tinubu ni Aso Rock"

Sowore ni ayalegbe ni Tinubu ni Aso Rock amọ o jẹ ohun ibanujẹ pe ijọba ko tii fesi si lẹti ti ẹgbẹ oun fi ranṣẹ.

Nipa ti eto ẹkọ ni Naijiria, ajafẹtọ ọmọniyan naa sọ pe ẹtọ araalu ni ẹkọ ọfẹ yẹ ko jẹ.

O fidi rẹ mulẹ pe pupọ ninu awọn to wa lori oye ijọba lonii ni wọn jẹ anfani eto ẹkọ ọfẹ nigba ti wọn wa nile ẹkọ.

O pari ọrọ rẹ pe owo gọbọi lo yẹ ki awọn oṣiṣẹ ijọba maa gba, 500,000 naira ko si kere ju fun awọn oṣiṣẹ ọhun.