Ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC tọ́wọ bọ̀wé àdéhùn, buwọ́lu N70,000 náírà gẹ́gẹ́ bí owó ọkọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook Joe Ajaero/NLC Hq/Facebook
Lojuna lati mu igbe aye idẹrun ba awọn oṣiṣẹ ijọba kaakiri ilẹ Naijiria, ijọba apapọ ti tọwọ bọwe adehun tuntun pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC.
Bo tilẹ jẹ pe oniruuru ijiroro lo waye laaarin awọn aṣoju ijọba ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, sibẹ, gbogbo wọn lo panupọ lati fẹnuko lori adehun tuntun.
Nibi ipade ti awọn alakoso NLC ati ijọba apapọ ṣe lọjọ kejilelogun, ati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, ni wọn ti buwọlu ẹgbẹrun lọna aadọrin naira gẹgẹ bi owo iranwọ ọkọ wiwọ fun awọn oṣiṣẹ.
Ajọ NLC lo sọrọ nipa adojukọ awọn oṣiṣẹ pẹlu bi owo ọja ṣe lọ soke, owo oṣu tuntun awọn oṣiṣẹ, owo epo to lọ soke, to fi mọ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ.
Ọmọwe Muhammad Maigari Dingyadi, to jẹ minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ lo buwọ lu iwe adehun naa pẹlu NLC lorukọ ijọba apapọ.
Timi Yakubu, alakoso eto iṣuna; Ọmọwe Garba Abdul S. U., akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ oṣiṣẹ lori ṣoju ijọba apapọ; nigba ti aarẹ ẹgbẹ NLC, Joe Ajaero ati akọwe agba fun ajọ JNPSNC, Olowoyo Gbenga, wa nibi ipade adehun tuntun naa pẹlu.
Kí ni wọ́n fẹnukò lé lórí?
Nibi ipade naa, ijọba apapọ yoo bẹrẹ sii san ẹgbẹrun lọna aadọrin naira fun gbogbo oṣiṣẹ patapata fun oṣu mẹfa gbako, ati pe inu oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni yoo bẹrẹ.
Ijọba tun buwọ lu owo ajẹmọnu, eyi to bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Karun-un, ọdun 2026, nigba ti owo ajẹẹlẹ yoo bẹrẹ ni sisan lati ibẹrẹ oṣu Kọkanla, ati pe oṣu mẹta-mẹta ni ijọba yoo maa san an.
Ni afikun, ijọba sọ pe ohun yoo san owo ajẹmọnu oṣu mọkandinlogun fun awọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera, eyi ti wọn yoo san fun oṣu mẹyta gbako, bẹrẹ lati oṣu Kejila, ọdun 2026.
Lori afikun owo oṣu tuntun, ijọba apapọ sọ pe wọn yoo ṣagbekalẹ igbimọ to n ri si ijiroro owo oṣu, ti wọn yoo si bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ.
Kókó pàtàkí márùn-ún tó wà nínú àdéhùn náà
Atẹjade wọn buwọlu lẹyin ipade, ni wọn ti koko marun-un ti wọn fẹnu rẹ ko le lori, awọn si ni:
Owo Oṣu Tuntun:
A fẹnuko pe wọn yoo gbe igbimọ ti yoo ri sọrọ owo oṣu tuntun kalẹ, ti wọn yoo si bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ. Sibẹ, a ko fẹnuko lori ṣiṣe agbekalẹ owo oṣu tuntun ati igba ti sisan rẹ yoo bẹrẹ.
Adinku lori owo epo rọbii:
Ijọba apapọ yoo san owo iranwọ ẹgbẹrun lọna aadọrin naira kaakiri ẹka iṣẹ ijọba fun oṣu mẹfa, ti yoo si bẹrẹ inu oṣu Kọkanla, ọdun 2026.
Ijọba apapọ ti buwọ lu awọn owo gba ma binu fun awọn oṣiṣẹ, ti sisan rẹ si ti bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Karun-un, ọdun 2026. Sisan owo oṣu ajẹẹlẹ yoo bẹrẹ ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni oṣu mẹta-mẹta.
Owo oṣu asaalẹ fun oṣu mọkandinlogun fawọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera ni yoo di sisan laarin oṣu mẹta, bẹrẹ lati oṣu Kejila, ọdun 2026.
Idẹrun owo ori sisan fawọn oṣiṣẹ
Gẹgẹ bi owo ori sisan ṣe ṣe pataki, ọrọ adinku ninu owo ori sisan fawọn oṣiṣẹ la o gbe lọ siwaju igbimọ iṣakoso, iyẹn NEC.
Owo ijamba fun awọn agbẹ:
Ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹ agbẹ ati aabo lori ounjẹ ti fi orukọ awọn ti yoo jẹ anfaani ati iye owo to jẹ naa ranṣẹ si ileeṣẹ to n ri sọrọ owo oṣu sisan, NSIWC lati ṣa ayẹwo rẹ. Ayẹwo naa ni yoo pari laaarin ọsẹ meji, ko to di pe wọn buwọlu fun sisan.
Ayipada rampẹ ni CONHESS
Ileeṣẹ NSIWC ti ṣeleri lati pari gbogbo agbeyẹwo lori idagbasoke naa laaarin ọsẹ mẹta pere, lati le jẹ ki igbimọ aarẹ lori owo oṣu gbe ipinnu kalẹ lori ayipada CONHESS.
Nibi ipade naa, wọn rọ awọn ijọba ipinlẹ ati ibilẹ lati ṣiṣẹ lori agbekalẹ ijọba apapọ yii, bẹẹ ni wọn rọ awọn ẹgbẹ kaakiri lati dide sọrọ fifi idi rẹ mulẹ kaakiri ẹka iṣẹ ijọba.
Awọn alakoso naa ni wọn tun sọ pe wọn yoo jokoo ipade tuntun pada lẹyin oṣu kan, lati wo bi nnkan yoo ṣe lọ laaarin asiko naa.



























