Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nipa àyẹ̀wò fóònù kí o tó rà á

Lojuna lati maa tọpinpin ati ṣe agbeyẹwo awọn ẹrọ ibanisọrọ to n wọle silẹ Naijiria, ajọ to n ri sọrọ eto ikansira-ẹni nilẹ Naijiria, NCC ti sọ pe igbesẹ ti bẹrẹ lakọtun.
NNC sọ pe awọn to ba n ra foonu tuntun lasiko yoo nilo lati tẹ awọn koodi (code) kan, ki wọn ba le mọ boya ojulowo foonu ni wọn n ko owo le lori.
Koodi ti NCC pe ni *315# ni awọn ọmọ Naijiria yoo tẹ sori foonu tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fẹẹ ra lati le fidi rẹ mulẹ boya ojulowo ni foonu naa tabi ayederu.
NCC sọ ọ di mimọ pe o ṣe pataki fun gbogbo ọmọ Naijiria to ba fẹẹ ra foonu tuntun fun lilo ara wọn, wọn ni lati mọ eyi to jẹ ojulowo, ko ma lọ jẹ awọn eyi ti wọn ti gbabọde ni wọn fẹẹ ko owo le lori.
Alakoso ẹtọ imọ ẹrọ ati arabiaṣa to jẹ ojulowo, Edoyemi Ogoh fidi rẹ mulẹ pe ayẹwo naa yoo dena awọn eeyan lati ra ayederu ẹrọ ibanisọrọ, ati pe yoo dena rira awọn ẹrọ ibanisọrọ ti yoo dena nẹtiwọọki awọn ẹrọ ibanisọrọ miran.
"Ki o too ra foonu, tẹ koodi *315#, ki o si rii daju pe ojulowo ni, ko to di pe o san owo," Ogoh sọ bẹẹ.
O wa jẹ ko di mimọ pe eto naa yoo bẹrẹ ni pẹrẹu lati ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Kí lo dé tí NCC ṣàgbékalẹ̀ ìlànà wọ̀nyí?
Nigba to n ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa pataki agbekalẹ tuntun naa nibi to ti farahan lori amohunmaworan kan laipẹ yii, Ogoh sọ pe idi pataki mẹta ni ajọ naa fi gbe ilana tuntun yii kalẹ.
O ni titẹle ilana ofin, didaabo bo araalu ati agbelarugẹ fun ojulowo iṣẹ wọn.
Alakoso agba naa sọ pe iwe ofin eto ikansiraẹni ti ọdun 2003 faaye gba awọn irinṣẹ ẹrọ ikansiraẹni lati gba ayẹwo kọja, ko le ba ilana orileede naa mu.
"Gbogbo erongba naa ni lati mọ pe awọn ẹrọ ibanisọrọ to n wọ orileede yii jẹ ojulowo, wọn si n ṣiṣẹ lọna to yẹ," Ogoh sọ bẹẹ.
Lórí ìdí pàtàkì kejì
Nigba to n sọrọ lori idi keji, o sọ pe yoo dena awọn araalu lati san owo fun ayederu tabi eyi ti ko nii ṣiṣẹ to yẹ.
"Nigba ti ẹ ba n na owo ti ẹ jiṣẹ-jiya le lori lati fi ra foonu, ẹ ni lati mọ daju pe ojulowo ni ohun ti ẹ n san owo fun," o fidi rẹ mulẹ.
Ìdí kẹta
Bakan naa, lo tun mẹnuba idi kẹta, Ogoh sọ siwaju pe lati pese ojulowo iṣẹ wọn, ni idi kẹta wa fun.
O ni oniruuru aniyan ati ẹjọ ni Ogoh sọ pe awọn araalu ti gbe wa si ileeṣẹ wọn nipa irufẹ nẹtiwọọki ti wọn n ri lo lori foonu wọn.
"A mọ pe a ni lati ṣe nnkan lori rẹ ni kiakia, to si ṣe pataki, ni ibamu pẹlu ilana, didaabo bo awọn araalu, ati lati rii daju pe ọkan awọn eeyan balẹ lori iṣẹ wa," o fidi rẹ mulẹ.
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe atubọtan lilo ẹrọ ibanisọrọ ti wọn ko buwọ lu, le kuro lori ẹni to n lo nikan, ṣugbọn ti yoo tun de ọdọ ẹlomiran ti wọn jọ wa ladugbo kan naa.
"Nigba ti awọn eeyan ba n lo ẹrọ ibanisọrọ ti ko ni ontẹ, kii ṣe awọn nikan ni wọn yoo mọ-ọn lara, awọn miran ti wọn jọ n gbe lagbegbe kan na yoo tun mọ-ọn lara pẹlu," o sọ bẹẹ.
"A ti apẹẹrẹ ibi ti ẹnikan ti ni ipenija lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ, a si wa rii pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ lo fa a,"
Ki lo kan fun ọ lati ṣe bi foonu rẹ ba kuna ayẹwo yii?
Siwaju sii lo ni, wi pe ayẹwo ẹrọ ibanisọrọ ko lọ lasiko ti wọn n yẹ ẹ wo, ko tun mọ s iwi pe ayederu ni iru ẹrọ ibanisọrọ bẹẹ.
O ṣalaye pe ipele meji ni ayẹwo naa pin si: akọkọ ni iru ontẹ ti foonu naa ni ati esi ayẹwo ti foonu kọọkan ni.
O ni irufẹ ontẹ naa ni yoo sọ yara ayẹwo to gba kọja lati mọ boya o ba ilana Naijiria mu, ati pe yoo le ṣiṣẹ pẹlu awọn nẹtiwọọki to wa nita.
"Nigba ti wọn ba tan foonu naa, yoo le so mọ nẹtiwọọki, ti yoo si sọrọ daadaa," o fidi rẹ mulẹ, bẹẹ lo tun fi kun un pe ontẹ naa ni wọn yoo ṣe lẹẹkan ṣoṣo fun foonu kan.
O ni awọn gbọdọ mọ iye ẹrọ ibanisọrọ to n wọ orileede naa, lati fi orukọ pẹlu nọmba agbaye (IMEI) wọn silẹ lori ikanni NCC.
"Nigba ti a ba tẹle ilana yii, ni a le sọ pe eto aabo ti pari lori rẹ," o sọ bẹẹ.
Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe awọn ileeṣẹ to n ṣe ẹrọ ibanisọrọ naa, to fi mọ awọn to n ko foonu wọle, pẹlu awọn alagbata ni wọn ni ojuṣe lati tẹle ilana naa, kii ṣe awọn to n ra a fun lilo.
Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn foonu ti wọn ti ṣe, to si ti wa ni lilo ṣaaju asiko ti ikede ayẹwo yii waye?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alakoso agba yii sọ pe awọn foonu to ti wa ni Naijiria ṣaaju gbedeke ọjọ ti ilana naa yoo bẹrẹ sii fẹsẹ mulẹ ko nilo lati gba ayẹwo naa kọja.
"Gbogbo ẹrọ ibanisọrọ to ti wa lori nẹtiwọọki titi di oru ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa ni wọn ti gba ilana ti wọn kọja," o fidi rẹ mulẹ.
"A ni ẹrọ ibanisọrọ to le ni miliọnu lọna igba (231m), ti wọn si ni ontẹ ayẹwo,"
O ni awọn foonu tuntun ti wọn ṣẹṣẹ n gba lero lati ko wọle si Naijiria ni wọn yoo nilo lati gba abẹ ayẹwo kọja.
Bẹẹ lo sọ pe awọn ẹrọ ibanisọrọ kan ṣafihan wi pe wọn ṣe ẹda rẹ ni, ko to di pe eto naa bẹrẹ, ati pe ilana yii ko ba wọn wi.
"A ko nii fiya jẹ wọn, 'Ẹ ra ayederu, ẹ ko wọn jade.' Ko si nnkan to ṣe awọn foonu naa."
Ṣe ko si ewu fun awọn ohun to wa lori foonu bi eeyan ba tẹ nọmba *315# yii?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba to n sọrọ lori aabo ara ẹni ti awọn oloyinbo n pe ni 'privacy', Ọgbẹni Ogoh sọ ọ di mimọ pe agbekalẹ ti wọn pe ni 'Device Checker', lo n lo IMEI lati fidi ayẹwo rẹ mulẹ.
"A ko mọ boya ẹyin lẹ ni foonu naa nigba ti ẹ ba tẹ koodi naa si, nitori pe ohun kan to jẹ wa logun ni IMEI yẹn," o sọ bẹẹ.
"A ko ni anfaani tabi ẹtọ si ipe ori aago awọn eeyan. A ko mọ awọn ti ẹ ni lori foonu, bẹẹ la ko ni anfaani si atẹjiṣẹ to n wọle-jade, to fi mọ awọn nnkan ti eeyan fi pamọ sori foonu wọn."
O ni ohun kan ṣoṣo ti wọn ṣe agbekalẹ rẹ ni lati mọ boya foonu naa jẹ ojulowo.
Siwaju sii lo ni awọn to n ra foonu le tẹ *315# lati mọ boya ojulowo ni ẹrọ ibanisọrọ wọn, tabi ki wọn pe ileeṣẹ wọn lori 622 bi wọn ba ni ibeer lati beere lọwọ wọn.
Bẹẹ lo sọ pe awọn fi ikilọ sita wi pe nọmba *315# nikan ni awọn fontẹ lu fawọn eeyan lati fi mọ aridaju foonu wọn, tabi pe ki wọn lọ soju opo ayelujara wọn, bi wọn ba fẹẹ mọ ohunkohun.
o ni ki wọn yee pin awọn nọmba ti wọn fi n ranṣẹ si wọn pẹlu ẹnikẹni, iyẹn OTP, nitori pe awọn nikan ni wọn letọọ si i.


























