"Láti ìgbà tí ọkọ̀ òfúrufú ọmọ ogun ti já lulẹ̀ ní Igbokoda, a kò lè pa ẹja mọ́"

Ọba tawọn olugbe ilu Igbokoda, to jẹ olu ilu ijọba ibilẹ Ilaje, nipinlẹ Ondo ti ke si ijọba fun iranlọwọ lẹyin oorun to gba ilu naa kan latari baalu ọmọ ogun to ja lulẹ nibẹ loṣu to kọja.
Ọjọ karun un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 yii ni baalu naa ja lulẹ lẹyin ọọfi ileeṣẹ ọmọ ogun, Forward Operating Base, to wa ninu ilu naa.
Amọ ibanujẹ lo jẹ pe lẹyin ti baalu naa ja tan, awọn eeyan ilu ọhun ti n dojukọ ipenija mii latari awọn to ku sinu omi ti ọkọ ofurufu naa ja si.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe oorun ti gba agbegbe ti baalu naa ja si kan, lawọn mii sọ pe iṣẹlẹ naa ti gba ounjẹ lẹnu awọn.
Eredi ree ti BBC Yoruba fi gbera lọ si ilu naa lati wo bi nnkan ṣe ri.
"Ẹran eeyan ja wẹlẹwẹlẹ sinu omi naa, gbogbo agbegbe naa lo n run"
BBC Yoruba kan si aafin Olu Igbokoda, Ọba Afolabi Odidiomo to jẹ olori ilu naa lati mọ ipo ti awọn eeyan rẹ wa.
Ọba Odidiomo sọ pe yatọ si ijamba ọkọ baalu to ja, o ṣeeṣe ki ijamba eto ilera mii tun ṣẹlẹ ninu ilu ọhun latari bi omi ti baalu naa ja ṣe bajẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, oorun awọn to ku sinu baalu naa gba ọpọ agbegbe ninu ilu naa kan.

O ni "Oorun awọn to ku sinu ọkọ ofurufu naa lo gba gbogbo ilu kan to jẹ pe laarin ọsẹ kan ti iṣelẹ naa waye, a ko ri imu mi niluu.
"Ko si ẹnikan ti wọn ri gbe jade pato... gbogbo ibẹ yẹn tẹlẹ, ti awọn ọmọde ba de lati ile ẹkọ lọsan, wọn maa n lọ sibẹ lati lọ wẹ.
"Ṣugbọn ọmọ to lọ sinu odo lati lọ wẹ ti ifun lọ mọ lọrun, ṣe o maa tun pada lọ sibẹ?
"Omi yii kan ṣoṣo naa la n mu, oun la n pọn lati fi wẹ, lati fi fọṣọ, lati fi se ounjẹ nibomii, ni bayii, ko si ẹni to le pọn lati fi wẹ."
Kabiesi odidi ọmọ sọ pe ijọba ibilẹ mii lawọn eeyan ilu oun ti n lọ ra omi nitori pe gbogbo ileri ti ijọba ṣe fun ilu naa lori iṣẹlẹ ọhun lo ja si pabo.
Ebi maa pa wa ku, gbogbo inu odo naa lo ti bajẹ – apẹja
Araalu mii to jẹ apẹja ti a tun ba pade ninu Igbokoda to jẹ apẹja sọ pe omi ti baalu ọhun ja si ti bajẹ, awọn ko si le pa ẹja nibẹ mọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun.
O sọ fun BBC Yoruba pe inu odo naa ti n run latari awọn eeyan ti wọn ku sibẹ.
Okunrin ọhun tun sọ siwaju si pe pupọ awọn ẹja naa lo ti ku, ti awọn iyoku wọn si ti salọ, eyi to mu ko ṣoro fun awọn lati ṣiṣẹ oojọ wọn bayii.
Yatọ si awọn ẹja to ku ati oku to jẹra sinu odo naa, ọkunrin naa tun sọ pe awọn ọmọ ogun ko gba awọn laaye lati sunmọ inu ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye mọ, eyii to jẹ ojuko gan ti awọn ti n pa ẹja.
Apẹja naa, Kabiesi Odidiomo, to fi mọ awọn eeyan mii ti a ba sọrọ ni Igbokoda ti ke si ijọba fun iranlọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.

























