Jide Kosoko sọ̀rọ̀ lórí gbèse N300m náírà tó jẹ lórí fíìmù tó gbé lọ sinimá

Oṣere Jide Kosoko ree
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agba oṣere tiata nni, Ọmọọba Jide Kosoko ti sọ pe adanu nla ni fiimu agbelewo tuntun toun ṣẹṣẹ gbe jade laipẹ yii jẹ foun, pẹlu bo ṣe sọ pe gbese loun jẹ bọ nibẹ.

Jide Kosoko sọ pe fiimu 'Eleko: Oba Esugbayi' toun gbe kaakiri ile aworan fiimu, iyẹn sinima ko pa owo to yẹ ko pa.

Ogbontarigi oṣere naa sọ pe gbese owo to le ni miliọnu lọna oọdunrun (N300m) naira toun fi ya iṣẹ naa, loun jẹ lori fiimu tuntun ọhun.

Kosoko lo kọminu yii nibi ifọrọwerọ to ṣe laipẹ yii.

O sọ pe awọn oludokoowo lo ko owo silẹ lati fi ya fiimu naa, pẹlu erongba lati ri ere rẹpẹtẹ lori okoowo ọhun.

O ni lati inu oṣu Kẹta, ọdun yii ti wọn ti ṣafihan ati ifilọlẹ fiimu ọhun, ko tii pa owo ti wọn fi ya a, ati pe iwọnba owo ti wọn ri, ni gbogbo awọn to kopa ninu fiimu naa pin mọ ara wọn lọwọ.

"Fiimu mi, 'Eleko: Oba Esugbayi' to jade laipe yii, ti a si gbe lọ sinima, la na owo to le ni ọọdun miliọnu naira le lori. Ṣe mo ni ọọdunrun miliọnu naira? O yẹ ki ẹ mọ pe awọn kan lo gbe owo naa fun mi, kii sii ṣe pe wọn fun mi, wọn fi dokoowo ni, mo sig be fiimu naa lọ si sinima," Jide Kosoko sọ bẹẹ.

O jẹ ko di mimọ pe oniruuru nnkan lo ṣẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ko ri ohun ọhun pada.

"Oniruuru nnkan lo ṣẹlẹ, ti a ko si ri owo wa pada. Iwọnba ti a ri ko jọ la pin mọ ara wa lọwọ. Bi mo ṣe wa yii, bi ẹ ba gbọ pe ẹnikan jẹ gbe gbese kọrun, o si n jo kiri, emi ni," o fidi rẹ mulẹ.