Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nipa Shamonda, kòkòrò àrún tó ṣẹ́yọ́ ní Nàìjíríà, tó ti gbẹ̀mí èèyàn kan ní France
Shamonda eleyii ki i ṣe ti ilu Ibadan, adugbo kọ rara, kokoro arun kan to jẹ ẹya virus ni.
Awọn alakooso lorilẹede France ti kede pe kokoro arun tuntun kan ti wọn n pe ni Shamonda ti mu ẹnikan lorilẹede naa.
Akọkọ arun Shamonda naa ti wọn kede ni wọn ri lara ẹni ẹni to pada jade laye nibẹrẹ oṣu Kẹwaa ọdun yii, ni France.
Awọn eleto ilera ibẹ tun sọ pe aisan naa ruju, amọ ko ti I de ipele to le fa ewu fun araalu.
Ki ni arun Shamonda gan-an?
Kokoro arun Shamonda ti wọn tun n ge kuru si Shav maa n mu awọn maaluu, o si le tan kalẹ nipasẹ kokoro kan ti wọn n pe ni Midge, paapaa eyi to ba ti ni arun naa lara.
Shamonda jẹ ẹya kokoro kan naa ti a mọ si Schmallenberg virus, to maa n fa kawọn nnkan ọsin bii ewurẹ ma le ṣe abiamọ daadaa.
Ọpọ iru aisan yii lo ti waye ri laarin awọn àgbò, ewurẹ, ẹsin ati ẹran kan to fara jọ agutan ti wọn n pe ni alpaca .
Amọ arun yii ko mu eeyan ri ninu itan, eyi ni igba akọkọ ti iroyin pe o mu eeyan yoo gbode.
Ajọ Ilera Agbaye (WHO) ati European Centre for Disease Prevention and Control (ECDC), ti sọ pe awọn n wadii iṣẹlẹ naa lọwọ nipa bi aisan Shamonda to maa n mu ẹranko ṣe de ara eeyan.
Ero wọn lọwọ yii ni pe ẹni naa lugbadi arun Shav nipasẹ kokoro midge to ge e jẹ ni Ila-Oorun France.
Gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ ilera ati ọgbin sẹ sọ pe lara awọn ẹranko lẹba odo ni awọn ti kọkọ ri kokoro yii to ṣọṣẹ.
Bawo lo ṣe ṣe ẹni naa ko too pada ja siku?
Awọn eleto ilera ati ileeṣẹ ọgbin naa sọ pe arun to lagbara kan ni wọn n tọju ẹni ti Shav pa naa fun nileewosan Lyon.
Wọn ni o koju awọn iṣoro ailera to ni i ṣe pẹlu ọpọlọ, ọpa ẹyin ati awọ ara.
Alaye ti wọn ṣe ni pe ohun to farahan lara alaisan naa ko ruju rara, o ṣee sọ pe kokoro Shav ni, pẹlu iwadii ti wọn kọkọ ṣe.
Awọn ṣọja ara ẹni naa ti daṣẹ silẹ bi wọn ṣe wi, ko lagbara lati koju aarẹ kankan mọ, eyi to mu ki aarẹ naa wọle si i lara poo.
"Titi dasiko yii, ohun ti a mọ ni pe kokoro Shamonda ko le bọ si ara eeyan, ẹranko nikan ni a mọ fun un, koda bo ti lẹ jẹ pe o pẹ ti kokoro Shamonda ti wa ni Africa ati Asia".
Bi kokoro yii ba wọ agbo maaluu, awọn ẹran to ba fọwọ kan yoo ni aisan iba, igbẹ gbuuru ati ai le pese wara daadaa.
"Lasiko ti oju ọjọ ba tutu bii igba ojo, itankalẹ arun yii maa n dinku bi awọn eleto ilera WHO ṣe sọ.
Lọwọ yii, ECDC sọ pe oun n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alaṣẹ French ati European, lati wadii boya aisun yii le di ewu fun araalu, ati ohun to ṣee ṣe ko mu ba wọn.
Akọkọ iru aisan naa ti wọn ri ni Europe ṣẹlẹ nipari oṣu Keje, gẹgẹ bi ajọ naa ṣe sọ.
Wọn ni awọn ti ri I lara awọn ẹranko inu oko tipẹ lawọn orilẹede bii Ireland, Germany, Italy ati Spain.
Nibo lo ti tan de?
Lara awọn maaluu ni wọn ti kọkọ ri arun yii ni Naijiria ni 1965.
Nigba ti yoo fi di ogunjọ oṣu Kẹwaa yii, o ti to ogun aisan naa ti wọn ti ri pe o ṣẹlẹ lawọn ilu kan ni Europe.
Bawo lo ṣe buru to fun ẹranko to ba kọlu?
Yatọ si iba, igbẹ gbuuru ati ki wọn ma le pese wara pupọ, Shav tun le fa ki oyun walẹ lara ẹranko to ba mu.
O le mu ki ọmọ ti ẹranko naa bi ya abirun.
ọpọlọ ọmọ ẹran naa le maa pe to, paapaa lara awọn ẹran bii ẹṣin.
Nipa ipa to le fun igba pipẹ, ajọ World Organisation for Animal Health (WOAH) sọ pe awọn ko le fidi ẹ mulẹ nipa ẹya rẹ ni Europe.