Àwọn bandiiti ṣìrìn, aráàlú fárígá, pa agbébọn 30

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn olugbe abule Birnin Tudu, nijọba ibilẹ Gummi, ipinlẹ Zamfara ti sọ pe awọn mu balẹ lara awọn ikọ bandiiti to kọlu abule naa ninu rogbodiyan ọlọjọ mẹta kan to waye laaarin awọn pẹlu ikọ onijagidijagan naa.

Ohun ti BBC gbọ ni pe awọn eeyan abule naa koju awọn agbebọn ọhun nigba ti ikọlu ojoojumọ su wọn.

Olugbe abule Birnin Tudu kan sọ fun BBC, pe awon bẹrẹ si i pete ati koju awọn bandiiti naa lẹyin tawọn gbọ pe wọn tun ti n bọ ni abule.

"Nigba ti wọn n de, a ṣina ibọn fun wọn"

Gẹgẹ bi ọkunrin ọmọ abule Birnin Tudu naa ṣe ṣalaye, o ni:

"Nigba ti wọn de, a ṣina ibọn bolẹ fun wọn, awọn naa si da a pada fun wa.

"Wọn ko awọn eeyan wa kan ti wọn jẹ ọkunrin lọ, amọ awa naa pa pupọ ninu wọn."

"A ri awọn kan ninu wọn ti wọn ki I ṣe ọmọ orilẹede Naijiria."

Ọkunrin naa sọ pe oku mejidinlogun tabi mọkandinlogun lawọn pada ba nibudo ikọlu naa, nigba tawọn agbebọn gbe awọn oku kan lọ.

O fi kun un pe ọkada ni awọn bandiiti naa gbe wa, eeyan mẹta-mẹta lori ọkada kọọkan.

Ohun ti ijọba sọ lori iṣẹlẹ yii

Oludamọran pataki fun Gomina ipinlẹ Zamfara, Jafaru Kaura, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC.

O ni awọn ti ṣe afikun awọn ẹṣọ alaabo si agbegbe naa lati da aabo bo awọn eeyan ibẹ ati dukia wọn. Ki awọn bandiiti ma si le wọ ibẹ mọ lati tun ṣọṣẹ ju bẹẹ lọ.

Oludamọran pataki fun Gomina ipinlẹ naa fi kun un pe awọn eeyan ilu naa pa ju agbebọn ọgbọ̀n (30) lọ lasiko ikọlu ọhun.

Jafaru wa rọ awọn olugbe Birnin Tudu ati agbegbe rẹ lati sọwọ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo, paapaa nipa fifi ohun ifura ti wọn ba ri to le ṣakoba fun aabo to wọn leti kia.

Oju wo ni awọn onimọ nipa aabo fi wo ki araalu pa bandiiti?

Ajagunfẹyinti Abdullahi Bakoji, onimọ nipa ọrọ aabo, ṣalaye pe iwa akin to ṣee gboriyin fun ni awọn eeyan abule Birnin Tudu hu.

O ni paapaa bo ṣe jẹ pe ẹtọ wọn ni lati gbeja ara wọn labẹ ofin orilẹede yii ( Self Defence).

Ajagunfẹyinti Abdullahi Bakoji sọ pe:

"Ko yẹ ko maa jẹ pe gbogbo igba ni wọn n mu eeyan bii adiẹ, ti wọn n so wọn mọlẹ ninu igbo, fiya jẹ wọn ti wọn a tun gba owo itusilẹ lọwọ wọn."

Amọ Bakoji kilọ fun awọn araalu naa lati ma ṣe sun asunpara. O ni ki wọn foju ṣọri ju alakan lọ.

Onimọ nipa aabo baa sọ pe awọn agbebọn ọhun ṣi le pada wa, wọn si le ju ti tẹlẹ lọ ti wọn yoo wa lati gbẹsan.

O gba wọn nimọran lati so okun aabo wọn le si I gidi, ki wọn ri I daju pe awọn eeyan wà to n ṣọ abule naa nigba gbogbo.

"Ki wọn dira ju ti tẹlẹ lọ, ẹ ma sun mọ. Bawọn eeyan kan ba sun, ki wọn wa awọn mi-in ti yoo maa ṣọ ilu.

"Ki ẹ tun wa sọ fun awọn ẹṣọ alaabo, kawọn naa le da si idaboobo ẹmi ati dukia awọn eeyan ilu".

Bẹẹ ni Bakoji gba wọn nimọran ni Birnin Tudu.