Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Wàhálà yóò ṣẹlẹ̀ bí Gómìná kankan bá rọ Olubadan lóyè - Sunday Igboho fọnmú
Olori ẹgbẹ ajijangbara nilẹ Yoruba, Sunday Adeniyi Adeyemo ti ṣe ikilọ fun Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo lati dẹkun erongba yiyọ Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rasidi Ladoja n'ipo.
Sunday Adeyemo, ẹni tọpọ awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho sọ pe bi gomina kan gbiyanju lati yọ Olubadan nipo, wahala yoo ṣẹlẹ nipinlẹ naa.
Igboho sọ pe digbi loun duro lẹyin Ọba Olubadan, toun si ṣetan lati gbeja rẹ, nigbakugba ti wahala kankan ba fẹẹ dide sii.
Ninu fọnran kan to n kaakiri ayelujara, Igboho sọ pe, bi Makinde ba fi gbe igbesẹ yiyọ Olubadan, wọn yoo kede ijọba pajawiri nipinlẹ Oyo, nitori pe nnkan ko nii fararọ.
"Wọn wa n rọ ọ, mo ni ki wọn ma rọ ọ, ki wọn jẹ ko gbiyanju ẹ. Gomina to ba gbiyanju lati yọ Olubadan, wọn yoo kede ijọba pajawiri niluu yẹn lọjọ yẹn," Igboho sọ bẹẹ.
O ni kii ṣe ọrọ ẹnu lasan, nitori pe oun yoo dide lati tako iru igbesẹ bẹẹ, ti awọn eeyan yoo si dide lati ṣatilẹyin foun.
"Bi gomina kan ba gbiyanju ẹ, mo fi Ọlọrun bura, mi o fi ẹnu ṣe e. Lati Soka nibi ni Ibadan yoo ti maa mi titi," Igboho fidi rẹ mulẹ.
"Nigba ti ẹnikan tun wa sọ fun mi pe, wọn ni wọn yoo da Olubadan lọna, mo ni ko sẹni to to bẹẹ, wi pe ọrọ ẹyin ni. Nigba ti ko tii si iru agbara bayii lọwọ Olubadan, bi wọn ba lọ ka a mọle, wọn maa n ba a nibẹ ni.
"Ṣugbọn nigba ti agbara bayii tun ti wa lọwọ, ẹ wa sọ pe ẹ fẹ lọ ba baba mọle, miliọnu kan yin ko to bẹẹ. Bi ẹ ba gbiyanju ẹ, ẹ maa sa kuro ninu ile ijọba ni.
Bakan naa ni olori ajijangbara ọhun tun sọ pe oun ti fi ọkan Olubadan balẹ lati ma ṣe foya, nitori pe oun yoo ṣe atilẹyin fun un titi de opin.
Ninu ọrọ rẹ, o ni, "Mo sọ fun baba wa Olubadan wi pe ki wọn sun, ki wọn han oorun, ko sẹni to to bẹẹ, ti yoo wa ba a yin ninu ile, ọmọ ipinlẹ Oyo kan naa ni wa. Ara ipinlẹ Oyo ni Igboho wa, wọn ko tii pin wa.
"Baba Olubadan lo n beere fun ipinlẹ Ibadan, wọn ko sit ii buwọ lu, ipinlẹ Oyo naa la ṣi wa, a ko tii kọja aaye wa. Ki Ọlọrun jẹ ki ẹmi baba wa Olubadan gun," Igboho kadi ọrọ rẹ nilẹ.