Kí ni pàtàkì àyẹyẹ àyàjọ́ Ogbomoso tó máa ń wáyé lọ́dọdún?

Ogbomoso cradle carnival, Igbega aṣa, iṣẹ ati Idagbasoke ilu lo bi ipatẹ yii.
Ilu Ogbomosho, ni ipinlẹ Oyo, ti n mura silẹ fun ayẹyẹ nla to so ọpọlọpọ eeyan mora lati inu ilu naa ati lati ilẹ okeere.
Ayẹyẹ ti wọn sọri rẹ ni Ogbomoso Cradle Carnival, eleyii ni yoo waye ninu oṣu Kejila ọdun yii.
Ayẹyẹ Ogbomoso Cradle carnival ti ọdun 2026 nii yoo waye lati ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, si ọjọ kọkanlelogun oṣu naa, ọjọ marun-un ni ayẹyẹ naa yoo fi waye, ati pe ọpọlọpọ eto ni wọn ti la silẹ lati sayajọ ayẹyẹ ọhun.
Ninu ipade awọn akọroyin to waye ninu aafin Soun ti ilẹ Ogbomoso, Alaga igbimọ fun ayẹyẹ naa, Ọgbẹni Segun Dokun Odebunmi, ṣalaye idi ti ilu Ogbomoso fi n ṣe ayẹyẹ naa lọdọdun.
Eto naa ma n mu idagbasoke baa ilu

Odebunmi ni, ayẹyẹ naa dabi ohunfa to maa n mu awọn ọmọ ilu Ogbomosho nile loko ati lẹyin odi walẹ, ki wọn si rantií ibi ti wọn ti wa ati bi ilu wọn ṣe n ni dagbasoke.
O tun sọ pe aṣa jẹ ọna kan to dara julọ lati so eniyan pọ, nitori naa ayẹyẹ naa kii ṣe fun iran wiwo nikan ṣugbọn lati ni imọ si nipa aṣa, iṣẹ ati itan ilu Ogbomoso.
Ọpọlọpọ aṣọ alarambara ni wọn yoo wọ nibi aṣekagba ayẹyẹ naa.
Lara awọn ti wọn n reti nibi ayẹyẹ ọhun ni gomina ipinlẹ Oyo.
Ninu ọrọ rẹ kọmiṣọna fun ẹtọ irọyin ati isoniji, Dotun Oyelade ni, lọdun to kọja ọpọlọpọ eniyan lo wọ aṣọ ibilẹ to ba ara wọn mu bii, aṣọ oke, agbada, gele ati fila ti orin ijo ati ifihan awọn egungun mu ki aṣekagba eto naa dun moni.
























