Abacha pinnu láti pa mí sí àhámọ́ àmọ́ Jimmy Carter kéde pé tí mo bá kú, Abacha náà yóò kú - Obasanjo

Àkọlé fídíò, Abacha pinnu láti pa mí sí àhámọ́ àmọ́ Jimmy Carter láti UK kéde pé tí mo bá kú, Abacha náà yóò kú - Obasanjo
Abacha pinnu láti pa mí sí àhámọ́ àmọ́ Jimmy Carter kéde pé tí mo bá kú, Abacha náà yóò kú - Obasanjo
Published

Yoruba ni agba kii tan ni orilẹ, irir si lo n jẹ agba.

Agba kan nilẹ Naijiria ati aarẹ tẹlẹ, Oloye Olusegun Obasanjo ti salaye lori ohun ti oju rẹ ri lasiko ti wọn ti mọ ahamọ lasiko isejọba ologun Ọgagun Sani Abacha.

Obasanjo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n bawọn ewe sọrọ nibi eto kan lọgba fasiti Ibadan eyi ti ẹka iyawekawe nile ẹkọ naa se agbatẹru rẹ.

Obasanjo ni Abacha fẹ pa oun sinu ọgba ẹwọn lasiko naa amọ Olootu ijọba ilẹ Amẹrika tẹlẹ, Jimmy Carter lo sọ fun Abacha pe to ba fi pa oun, Abacha funra rẹ naa maa ku.

"Psalm ni mo maa n ka le awọn ọta mi lori lasiko ti mo wa ni ahamọ tori awọn saamu naa ni mo mọ lori"

Obasanjo wa n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe laarin awọn mẹta ti wọn dijọ wa ni ahamọ nigba naa, oun si wa laye di oni.

O fikun pe Psalm ni oun maa n ka le awọn ọta oun lori lasiko ti oun wa ni ahamọ tori awn saamu naa ni oun mọ lori.

Aarẹ tẹlẹ naa tun kan saara si ipa ti oloogbe Arisekola nilu Ibadan ko si itusilẹ oun ni ahamọ

Obasanjo tun sọrọ nipa ogun abẹle ti Naijiria ja kọja laarin ọdun 1967 si 1970, o si ni un kọ ẹkọ pe ko si ohun ti ọrọ sisọ tabi ifikunlukun ko le yanju.

Bakan naa lo ni oun ko le jẹ ki iru isẹlẹ bẹẹ waye mọ.