Ìjọba kò mú ìkankan ṣẹ nínú gbogbo ìlérí tó ṣe fún wa – Mọ̀lẹ́bí Michael Oyedokun tí ajínigbé bẹ́ orí rẹ̀

Àkọlé fídíò, Mọlẹbi Micheal Oyedokun
Ìjọba kò mú ìkankan ṣẹ nínú gbogbo ìlérí tó ṣe fún wa – Mọ̀lẹ́bí Michael Oyedokun tí ajínigbé bẹ́ orí rẹ̀
Published

Awọn mọlẹbi olukọ ti awọn agbesunmọmi bẹ ori rẹ lẹyin ikọlu wọn sile ẹkọ Yawota ati Ahoro Esinele nipinlẹ Oyo ti sọ pe gbogbo ileri ti ijọba ṣe fun awọn lẹyin iku olukọ naa ni ko mu ṣẹ.

Iyawo oloogbe, ẹgbọn rẹ ati aburo rẹ lo ke gbajare bẹẹ sita lasiko ifọrọwerọ wọn pẹlu BBC Yoruba.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, oniruru ileri ni ijọba ṣe lẹyin iku rẹ, paapaa lẹyin ti wọn doola awọn akẹkọọ ati akẹgbẹ rẹ to wa lakata awọn ọdaran naa tan amọ o ṣeni laanu ijọba ko mu eyikeyi ninu awọn ileri ọhun ṣẹ.

Iyawo rẹ, Mary Oyedokun sọ fun BBC pe "A gbiyanju nipa rẹ, lati igba ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹle, a ke lori agbagbe, a pariwo pariwo ki wọn ba wa wa iyoku ara oloogbe jade, wọn ko gbe igbesẹ kankan nipa rẹ.

"Wọn ran awọn eeyan wa lati Abuja, wọn ṣeleri ọpọlọpọ nnkan pe ka fi ọkan balẹ, pe ko si iyọnu lori eto ẹkọ awọn ọmọ, lori igbayegbadun ti emi iyawo oloogbe.

"Lati igba ti wọn ti ṣeleri, a ko gbọ nkankan lori rẹ mọ, ijọba ko gbe igbesẹ kankan lori rẹ mọ."

Samuel Oyedokun, to jẹ ẹgbọn oloogbe ni ileri miliọnu mẹwaa naira ti ijọba ṣe fun awọn mọlẹbi ti ọrọ kan, ofo ọjọ keji ọja lasan lo ba de fun awọn.

Nigba to n sọrọ lori ohun ti mọlẹbi wọn n reti lati ọwọ ijọba, aburo oloogbe, Isaiah Oyedokun sọ pe awọn n fẹ eto ẹkọ ọfẹ fun gbogbo awọn ọmọ oloogbe.

Isaiah tun sọ pe awọn n fẹ ki ijọba da iyawo oloogbe lokoowo ki wọn si fi orukọ rẹ sọ ile ẹkọ kan ni iranti rẹ.