Ṣé ó ṣeéṣe kí ọdún 2026 mú àyípadà bá ìtàn àmì ẹ̀yẹ Ballon Dior fáwọn agbábọ́ọ̀lù láti Áfíríkà?

Àkọlé fídíò, Ṣé ó ṣeéṣe kí ọdún 2026 mú àyípadà bá ìtàn àmì ẹ̀yẹ Ballon Dior fáwọn agbábọ́ọ̀lù láti Áfíríkà?
Ṣé ó ṣeéṣe kí ọdún 2026 mú àyípadà bá ìtàn àmì ẹ̀yẹ Ballon Dior fáwọn agbábọ́ọ̀lù láti Áfíríkà?
Published

Awọn osere tiata ti Hollywood lo ni ami ẹyẹ Oscars.

Amọ awọn agbabọọlu lo ni ami ẹyẹ Ballon d'Or. Ẹbun mẹtala lo wa nilẹ fawọn agbabọọlu to pegede lati gba lọdun yii amọ ife ẹyẹ meji pere lo wa.

Igba wo ni agbabọọlu lati ilẹ Afirika gba ife ẹyẹ naa gbẹyin, ati pe awọn eeyan wo gan lo seese ko kọ itan tuntun lọdun 2026?

Idahun ni ọdun 1995. George Weah tii se agbabọọlu lati ilẹ Liberia si lo gba gba ẹbun fawọn agbabọọlu lọkunrin, ko si si agbabọọlu kankan lati ilẹ adulawọ to tun gba ẹbun naa lati igba naa.

Nọnba mii to tun fa ni mọra ree:

Ami ẹyẹ marundinlọgọta ninu mọkandinlaadọrin to wa fawọn agbabọọlu lọkunrin lawọn agbabọọlu to jẹ ọmọ ilẹ Yuroopu gba. Amọ titi di ọdun 1995, ko si agbabọlu to jẹ ọmọ ilẹ Yuroopu ko kunju iwọn fun ami ẹyẹ naa.

Ko si si agbabọọlu ọmọ ilẹ Afirika kankan to n gba bọọlu nilẹ okeere, to tii gba ẹbun naa

Agbabọọlu lati ilẹ Afirika n gba ami ẹyẹ

Lẹyin Wear, awọn agbabọọlu yoku nilẹ adulawọ kan n le ni, o ku diẹ ki wọn ba ami ẹyẹ naa.

Sadio Mane lati ilẹ Senegal se ipo keji lọdun 2022. Mohammed Sallah, agbabọọlu lati ilẹ Egypt se ipo kẹrin lọdun 2025, amọ ta wa ni agbabọọlu naa ti yoo fi opin si idaduro ọlọdun gbọọrọ yii?

Lọdun yii, Achraf Hakimi lati ilẹ Morroco ati Sadio Mané lati ilẹ Senegal naa wa lara awọn agbabọọlu ti orukọ wọn wa ni akọsilẹ fun ami ẹyẹ awọn ọkunrin.

Lara awọn irawọ agbabọọlu ti wọn dijọ n du ami ẹyẹ yii ni Lamine Yamal, Kylian Mbappé ati Harry Kane.

Hakimi ni ajọ to n sakoso ere bọọlu nilẹ Afrika, CAF, kede bii akikanju agbabọọlu ọkunrin lọdun 2025 lẹyin to seranwọ fun ẹgbẹ agbabọọlu Saint-Germain tilu Paris lati gba ife ẹyẹ Champions League.

Amọ ami ẹyẹ ti ilẹ adulawọ yatọ si ami ẹyẹ Ballon d'Or to wa yika agbaye."

Ẹbun fawọn agbabọọlu obinrin n kọ? Ọdun 2018 lo bẹrẹ.

Amọ Barbra Banda tii se agbabọọlu lati ilẹ Zambia ati Temwa Chawinga lati ilẹ Malawi ni wọn fi orukọ wọn silẹ fun ẹbun lọdun yii."

Wọn yoo maa du ẹbun naa mọ awọn oludije yoku lọwọ to fi mọ Alexia Putellas to ti gba ẹbun naa fun igba meji, Alessia Russo tilẹ Gẹẹsi ati Ewa Pajor tilẹ Poland.

Awọn agbabọọlu to gba ẹbun naa lọdun to kọja ni Aitana Bonmatí ati Ousmane Dembélé