Wo nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọkọ̀ òfúrufú àti drone tí iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria fẹ́ rà

Ọkọofurufu T129 ATAK
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria, Nigerian Air Force (NAF), ti n mura lati ra ẹrọ drone mejila ti orileede Turkey ṣe, ti orukẹ rẹ n jẹ TUSAŞ Aksungur.

Yatọ si awọn ẹrọ wọnyii, a gbọ pe ileeṣẹ ọmọ ogun naa yoo tun ra ọkọ ofurufu ẹlikọpita T129 ATAK lati China.

Ileeṣẹ iroyin Unmanned Africa ni bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọmọ ogun fidi iroyin naa mulẹ, ko mẹnuba asiko ti awọn ẹrọ naa ati ọkọ ofurufu ọhun yoo balẹ si Naijiria.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ naa fi lede loju opo ayelujara rẹ, o ni awọn ọkọ ofurufu ti wọn wa lakata rẹ ti fo fun wakati ẹgbẹrun mẹfa ati ọgọrun lati inu oṣu Kọkanla ọdun 2025 si oṣu Kẹsan an, ọdun 2026.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa ọkọ ofurufu naa

Ọkọ ofurufu Aksungur naa jẹ eyii to ni ẹrọ meji to lagbara lati fo loju ofurufu fun iwadii, bakan naa lo si le ju ado oloro lati oke si awọn ọta lori ilẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti ileeṣẹ to ṣe e sọ, iyẹ apa rẹ gun ni iwọn mita mẹrinlelogun, o si le gbe apapọ ẹgbẹrun mẹta ati ọdunrun iwọn kilo fo.

Ọkọ ofurufu naa tun le gbe apapọ ado oloro ti iwọn rẹ to 750kg fo loju ofurufu.

Yatọ si eyii, wọn tun sọ pe o le wa loju ofurufu fun apapọ aadọta wakati lai si ohun ija ogun ninu rẹ ti ko si ni rẹ ẹ.

Bẹẹ lo tun ni awọn ẹrọ ayaworan ninu ti ileeṣẹ ọmọ ogun le maa fi wo ibi ti awọn ọta ba wa.

Ẹrọ ayaworan naa ni agbara lati ri eeyan tabi ohun ija oloro mii ni oru ọganjọ tabi ninu okunkun.

Iṣẹ wo ni awọn ọkọ ofurufu yii lè ṣe?

Ẹrọ drone ileeṣẹ ọmọ ogun

Lakọkọ, pẹlu awọn ẹrọ ti ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria fẹ ra, wọn le lọ sibi ti awọn agbesunmọmi tabi ọta ba wa ninu igbo lai kuro loju kan naa.

Wọn tun le maa fi awọn drone na ju ado oloro si awọn ọta lai kuro loju kan.

Yatọ si juju ado oloro, wọn le lo wọn fun ṣiṣẹ iwadii, yiya fidio tabi fọto awọn ọta ni ibuba wọn ti awọn ọta naa ko si ni mọ.

Awọn irinṣẹ naa lagbara lati gbe awọn ado oloro rinrinajo fun ọpọlọpọ maili lati lọ koju awọn ọta.

Awọn onimọ ti sọ pe awọn irinṣẹ naa tunbọ ran ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria lọwọ ninu igbiyanju rẹ lati rẹyin igbesunmọmi ni Naijiria.

Wayi o, yatọ si ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria to ṣẹṣẹ fẹ ra awọn awọn ohun ija oloro wọnyii, awọn orilẹede mii ni Afrika bii Chad, Niger, Angola, Angola ati Algeria naa ti fi awọn akoko igba kan ra a ri.