Kí ló yẹ kí o mọ̀ nipa ètò ìforúkọsílẹ̀ àwọn ọmọdé tí ìjọba àpapọ̀ ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laipẹ yii ni ijọba apapọ ilẹ Naijiria kede eto iforukọsilẹ lori ayelujara fun awọn ọmọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bi, ati awọn to ba ṣẹṣẹ ku.
Bo tilẹ jẹ pe eto yii ti wa nita tipẹ, eyi ti ajọ to n ṣabojuto onka araalu, iyẹn NPC n ṣagbatẹru rẹ, ṣugbọn ti ko fi bẹẹ han si araalu, nitori ilana ti wọn n gba ṣe e.
Ajọ NPC ti wa sọ pe ori ikanni ayelujara ni eto fifi orukọ awọn ọmọ ti wọn ba ṣẹṣẹ bi, ati awọn to n ku yoo wa, lati le ni akọsilẹ kikun nipa araalu.
Ọmọwe Aminnu Yusuf to jẹ alaga agba fun ajọ alabojuto onka araalu naa sọ nibi ipade awọn akọroyin to waye niluu Abuja l'Ọjọru, ọsẹ yii pe awọn araalu le lọ soju opo ayelujara 'VitalReg' ti wọn gbe kalẹ naa lati bẹrẹ fifi orukọ awọn ọmọ tuntun silẹ, to fi mọ awọn ti wọn n padanu, ki akọsilẹ le wa.
Bakan naa lo tun fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ wọn oo tọ yoo ṣe iwadii kikun, ko to di pe araalu ni anfaani lati gba iwe-ẹri ti wọn ba n fẹ, yala lori ọmọ naa, tabi ẹni to tik u.
O ni igbesẹ tuntun yii lo fi opin si gbogbo wahala ilana lilo ọwọ ti awọn ti n ṣe lati ọdun 1988 ti wọn ti bẹrẹ, to si ni ikanni VitalReg yoo ṣe iranwọ pupọ.
Igba wo ni eto naa bẹrẹ?
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ NPC fi soju opo ayelujara wọn, wọn ni ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2026 ni wọn ṣiṣọ loju opo VitalReg naa, ti awọn araalu si le ṣamulo rẹ kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji to w ani Naijiria, to fi mọ FCT, Abuja.
"Anfaani nla lo jẹ fun mi lati kede fun gbogbo araalu nipa eto iforukọsilẹ fun awọn ọmọ tuntun ati awọn to tik u lori ikanni ayelujara VitalReg, labẹ ikanni ti a pe ni 'Electronic Civil Registration and Vital Statistics (E-CRVS) system'", atẹjade ọhun sọ bẹẹ.
"Bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2026, ni agbekalẹ ọtun yii ti bẹrẹ kakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, to fi mọ Federal Capital Territory."
Anfaani ọtun
Alaga ajọ NPC sọ ninu atẹjade naa siwaju sii pe eto ifọrukọsilẹ naa jẹ eyi ti yoo ya kankan, ti awọn araalu yoo si ni anfaani sii laaarin wakati mẹrinlelogun, ojoojumọ.
Nigba to n fidi rẹ mulẹ, Ọmọwe Yusuf jẹ ko di mimọ pe lẹyin ti araalu ba ti fi orukọsilẹ, awọn yoo ṣagbeyẹwo, ko to di pe awọn eeyan ni anfaani lati gba iwe ẹri naa sọwọ loju ẹsẹ.
O ni eyi yoo jẹ ki awọn ni akọsilẹ to dara, to si tun wa labẹ aabo to pe ye fun ọjọ iwaju.
Yusuf fi kun ọrọ rẹ pe igbesẹ yii yoo mu adinku ba gbigbe iwe kaakiri, diduro de asiko, ati ririn irin-ajo ti ko yẹ pẹlu erongba lati fi orukọ silẹ.
"Agbekalẹ ọtun ori ayelujara yii jẹ ọna ọtun fun atunto ninu itan ilana ifọrukọsilẹ nilẹ Naijiria. O ṣafihan ifarajin ajọ yii lori ọna lati mu itẹsiwaju ba iṣẹ wọn lọna igbalode, nipa akọsilẹ, ati aridaju pe akọsilẹ kikun wa lori gbogbo ọmọ ti wọn n bi ati awọn to n ku nilẹ Naijiria lakọtun," Yusuf ṣalaye.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe akọsilẹ to to miliọnu marun-un ni awọn maa n ni lori ọmọ tuntun lọdọọdun, ṣugbọn to jẹ pe awọn ko ni akọsilẹ kikun lori ẹgbẹlẹgbẹ awọn ti wọn n bi, ati awọn to n ku.
"Iforukọsilẹ awọn ti wọn n bi lọdọọdun wa ni ida mẹtadinlọgọta kaakiri orileede yii, nigba ti akọsilẹ awọn to n ku, ko to ida ogun. Alafo yii n jẹ ọpọ ọmọ Naijiria niya lori aini akọsilẹ kikun, lati ni eto apapọ to muna d'oko," o sọ bẹẹ.
Wo àwọn ibi tí o ti lè rí àwọn òṣìṣẹ́ NPC
Lati le jẹ ki idagbasoke de ba iṣẹ wọn, ati fun awọn araalu lati bẹrẹ ibeere ati alaye lẹkunrẹrẹ, ajọ NPC sọ pe awọn ti ṣi ibudo eto ifọrukọsilẹ ẹgbẹrun mẹrin le ni mọkanla (4,011) kaakiri ijọba ibilẹ ẹrinlelaadọrinlelẹẹdẹgbẹrin (774) to wa ni Naijiria.
O ni awọn ṣi n tẹsiwaju lati ṣe afikun ibudo iforukọsilẹ naa de ẹgbẹrun mẹjọ (8,000 centres).
Ọmọwe Yusuf awọn tun ti tọwọ bọ iwe adehun pẹlu awọn ileeṣẹ ati ajọ bii Association of Local Governments of Nigeria (ALGON), National Identity Management Commission (NIMC), UNICEF ati Barnksforte Technologies Limited lati jẹ ki iṣẹ wọn muna d'oko, ko si de agbegbe ati igberiko.
Siwaju sii, Yusuf sọ pe ikanni VitalReg ni wọn ṣagbekalẹ rẹ lati ṣe iranwọ fun eto idagbasoke imọ-ẹrọ nipa eto ayika, ati lati ṣe iranwọ afojusun agbekalẹ ijọba apapọ lori ayipada igbalode.
O fi kun ọrọ rẹ pe iforukọsilẹ naa ko nii ga araalu lara rara, pẹlu ọna ti wọn gba gbe e kalẹ.
"Ẹ jẹ ki n fi da gbogbo ọmọ Naijiria loju pe agbeyẹwo yii kii ṣe lati di alafo anfaani si iforukọsilẹ. Iforukọsilẹ awọn ọmọ tuntun ati awọn oku jẹ eyi ti ijọba n san owo iranwọ fun, ni ibamu pẹlu ifarajin ajọ yii lati rii pe wọn ṣe aṣeyọri lori eto iforukọsilẹ.
"Ni apapọ, a le ṣagbelarugẹ fun ọna igbalode ti yoo fi ọkan gbogbo ọmọ Naijiria balẹ nipa iforukọsilẹ labẹ ofin, ati akọsilẹ to muna d'oko," Yusuf jẹ ko di mimọ.



























