'Lóòótọ́ ni mò ń rówó lẹ́yìn tí mo gbìyànjú láti ṣoògùn owó àmọ́ wọ́n ní mi ò gbọdọ̀ kọ́lé tàbí ra ọkọ̀ nínú rẹ̀'

Àkọlé fídíò, Ogbomoso Pastor
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Yoruba bọ wọn ni bi eeyan ko ba mọ ibi ẹgbẹ rẹ gbe n la, ni ṣe ni eeyan yoo ma sare asaku.

Pasitọ ijọ kan ree ni ilu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo, Pasitọ Joel Olasunkanmi Adedeji, ẹni to igbiyanju oun lati ṣe oogun owo nigba ewe.‎

‎Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ile iṣẹ BBC News Yoruba niluu Ogbomoso, Pasitọ Joel ni oun ko ju bi ọmọ ogun ọdun le diẹ lọ nigba naa, eyi to jẹ nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin ti oun pinnu lọkan ara oun lati wu gbogbo iwa to buru julọ ki Ọlọrun le binnu si oun.

‎O ni oun gbagbọ pe atunbọtan oogun owo ti oun gbiyanju lati ṣe lo sọ oun di alaabọ ara lẹyin ọdun marun-un ti oun gbe igbesẹ naa.

Pasitọ Joel Olasunkanmi Adedeji wọ aṣọ olomi aro, o n wo oke

"Ko ju ọdun mẹrin si marun-un lo ti mo fi gbadun ara mi"

Pasitọ Joel ẹniti o jẹ akẹẹkọ jade ile ẹkọ ti wọn ti nkọ nipa imọ alajẹsẹku to wa nilu Oyo, ṣalaye wi pe loootọ ni oun ri owo lẹyin igbesẹ ọhun amọ nitori awọn eeyan kan ṣa maa n fun owo lowo lai ṣe pe oun ṣe iṣẹ kankan fun wọn.

O fi kun pe loootọ ni ẹni ti oun lọ ba pe oun fẹ ṣe oogun owo naa sọ fun pe ko si nnkan to n jẹ oogun owo bikoṣe pe aṣiri bibo lo wa amọ ti oun ni oun fẹ ṣe e ni dandan.

‎O ni ọkan lara awọn ọdọmọbìnrin ti wọn jọ nṣe wọle wọde ni oun fi akisa funfun nu ara rẹ ti oun si mulọ sọdọ oniṣegun gẹgẹ bi wọn ti pàṣẹ fun oun.

"Ẹni mo si lọ ba o sọ fun mi loootọ pe ko si oogun owo nibikan o, mo ṣa dahun mo ni dandan mo fẹ ṣe e. Baba naa powe fun mi ṣugbọn mo ni ko si wahala ẹ ṣe fun mi."

Amọ o ni ko ju ọdun mẹrin si marun-un lọ ti aṣiri oun fi bo lọ ki oun to ṣagbako ijamba ọkọ ayọkẹlẹ to sọ oun di alaabọ ara, to si jẹ pe oun ko ko nnkankan jọ pẹlu owo naa.

"Wọn sọ fun mi pe mi o gbọdọ ra ilẹ tabi kọle ninu owo naa"

O sọ lati ibẹrẹ pẹpẹ ti oun ti bẹrẹ igbesẹ oogun owo naa ni wọn ti sọ fun oun pe oun ko le fi owo naa kọle tabi ra ilẹ, to si jẹ pe ṣina ni owo fi owo ti oun n ri ṣe.

O ni wọn ni ki oun fi aṣọ nu oju ara obinrin ti oun fẹran julọ lẹyin ibalopọ eyi ti oun ṣe to si sọ oun di ẹni to n ri owo amọ ti oun ko le sọ pe pato ibi bayii lawọn owo naa ti n wa.

Pasitọ Joel ni leyin naa ni oun lọ sile ẹkọ oniwaasu ṣugbọn ti oun ni ijamba ọkọ pẹlu alupupu ti oun gun eyi to ṣokunfa bi ẹsẹ oun ṣe da ti wọn si ge e.

‎O ni apa oun mejeeji lo da bẹẹ wọn ge ẹsẹ oun kan, eleyii lo sọ di ẹni tí o ni aabọ ara titi di akoko yii.

O fi kun pe eeyan ti oun ya lowo lati fi ra ọkọ ni oun ni ijamba ọkọ pẹlu, ti ohun ko si ri nnkankan ko jọ.

O wa gba awọn ọdọ ode oni nimọran lati má ṣe sare wa owo lọna aitọ nitori abọde ohun ti eeyan fi agidi wa kii jasi adun.