Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
'Mo mọ̀ nípa ẹ̀sùn tí bàbá mi ń kojú, ó kún ohun tí mi ò ṣe jẹ́ kí bàbá mi súnmọ́ àwọn ọmọ mi'
- Author, Sean Coughlan
- Role, Royal Correspondent
- Author, Freya Scott-Turner
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Duchess ti Sussex, Meghan Markle sọ pe ohun ti gbọ nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan baba oun lati ọdun 2018.
Ninu atẹjade kan, Meghan sọ pe lẹta kan ti wọn fi fẹsun kan baba oun, Thomas Markle, ti wọn kọ ranṣẹ sawọn ọlọpaa Metropolitan lọdun naa lọhun, wọn fi ẹda rẹ ranṣẹ si oun.
Eyi lo n waye lẹyin ti iroyin pe wọn ba awọn aworan to ṣafihan iwa fifi ipa ba ọmọde lopọ eyi ti wọn fẹsun kan pe wọn ba nile baba rẹ tẹlẹ to w ani Philippines.
Thomas Markle, ẹni ọdun mejilelọgọrin, to n gbe ni Amẹrika jiyan pe oun ni iru aworan bẹẹ.
Nigba to n sọrọ lori ẹsun naa ti ileeṣẹ iwe iroyin The Sun Newspaper kọkọ gbe, Meghan Markle sọ pe o jẹ ohun to ba eeyan lọkan je pe iru iroyin bẹẹ le jẹ jade.
O ni ọkan oun wa pẹlu awọn ọmọde to ṣeeṣe ki iroyin naa ṣakoba fun.
O ṣalaye pe nigba ti oun gba lẹta ti wọn ti fẹsun kan baba oun lọdun naa, wọn sọ aridaju rẹ fun oun pe iwadii n lọ lori ẹsun naa.
O fi kun pe o yẹ ki idi ti oun ko fi da si baba oun mọ, ti ou ko si jẹ ki awọn ọmọ oun sun mọ baba oun ye awọn eeyan bayii.
"Eyi jẹ lati da aabo bo wọn, mo si gbagbọ pe awọn alaṣẹ n ṣe ohun gbogbo to yẹ lati da aabo bo awọn ọmọ mii naa."
O juwe ẹsun naa bi oun to buru jai, to si ni oun gbagbọ pe idajọ ododo maa waye lori ẹsun naa, ti aabo awọn ọmọde yoo si jẹ ohun ti awọn alaṣẹ ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu.
Ọbakan Meghan, Thomas Markle kekere sọ fun The Sun pe oun ri awọn aworan to nii ṣe pẹlu fifipa ba ọmọde lopọ nile baba oun ni Philippines, ti oun si lọ fi to awọn ọlọpaa leti.
Akọwe ileeṣẹ to n ri si ọrọ idajọ ni Philippines, Nicholas Ty sọ fun BBC pe iwadii n lọ lọwọ lori ẹsun naa ati pe ẹka to n ri si lilo eeyan lọna aitọ ni Cebu lo n ṣewadii ẹsun naa.
Minisita fọrọ abenu ni Philippines, Jonvic Remulla sọ fun BBC pe awọn ọlọpaa ti ri ẹrọ kọmputa Markle gba lati fi ṣe ayẹwo awọn nnkan to wa ninu rẹ.
Ẹṣọ aabo FBI naa sọ pe awọn ti gbọ si ẹsun naa, ti awọn yoo si pese iranwọ to ba yẹ fawọn alaṣẹ Philippines, ti wọn si tun ni awọn maa ṣe iwadii lori ohunkohun to ba tako ofin Amẹrika.
BBC ti kan si Thomas Markle, Baba Meghan Markle ati ileeṣẹ ọlọpaa Metropolitan lati gbọ ti ẹnu wọn.
Ni oṣu Kẹjọ ọdun yii ni Meghan Markle ati ọkọ rẹ Ọmọọba Harry pada si UK lẹyin ọdun mẹfa ti wọn ti n gbe Amẹrika.
Ni oṣu Kiini ọdun 2020 ni wọn ko lọ si Amẹrika lẹyin ti wọn kede pe awọn ko ni da si ọrọ oye UK mọ, ti wọn ko si gba owo mọ.
Meghan nikan ni iya rẹ bi fun Thomas Markle amọ to ni ọmọ meji mii ti iyawo to kọkọ fẹ ti bi fun-un.
Ṣaaju igbeyawo Meghan lọdun 2018 ni oun ati baba rẹ ko ṣe papọ mọ ti baba rẹ ko si kopa nibi eto igbeyawo naa.
Ni 2025 ni Thomas Markle ko lọ si Philippines lẹyin to ni aisan rọwọrọsẹ.
Ile itọju kan ni iroyin sọ pe o n gbe bayii ni Florida, nibi ti wọn sọ pe o ti n kọ bi yoo ṣe maa rin pada lẹyin ti wọn ge ẹsẹ rẹ ninu oṣu Kejila ọdun 2025.
Meghan kọ lẹta ranṣẹ si baba rẹ nigba to w anile iwosan ni Philippines lẹyin ti wọn ṣiṣẹ abẹ ti wọn fi ge ẹsẹ rẹ.
Afikun iroyin latọwọ Virma Simonette Rivera