Kí ló dé tí DSS ṣe mú alátìlẹ́yìn Atiku, fojú rẹ̀ ba ilé ẹjọ́?

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti fi oju ọkunrin kan, tii se alatilẹyin oludije sipo aarẹ fun ẹgbẹ oselu African Democratic Congress, ADC, Alhaji Atiku Abubakar, ba ileẹjọ.

Iwaju ileẹjọ Majisireti to w ani ojule Kẹwa, opopona Kabala Doki, nipinlẹ Kaduna, ni DSS wọ ọkunrin naa lọ, ti adajọ si pasẹ pe ki wọn fi si ọgba ẹwọn ilu Kaduna.

Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa ni pe o n pin awọn iwe ilewọ kan kiri eyi ti wọn ni aarẹ Bola Tinubu kọ ni asiri si aarẹ ilẹ Amẹrika.

Afurasi naa, Mubarak Abdullahi, ti gbogbo eeyan mọ si Sardaunan Samari, ni ọlọpaa mu lọjọ Kejidinlọgbọn osu kẹsan lori ẹsun pe o pin ayederu iwe kiri loju opo Facebook rẹ pẹlu akọle to ni "Atiku n pada bọ."

Atẹjade kan ti oludamọran si aarẹ, Bayo Onanuga, fisita loju opo X rẹ salaye pe Mubarak jẹwọ pe lootọ ni oun n pin ayederu iwe naa kiri, to si tọrọ aforijin fun igbesẹ naa.

Amọ bo se tuba naa ko to lati da ijẹjọ rẹ duro rara, ti wọn si ni yoo fi imu ko ata ofin.

Ileesẹ DSS lo foju Mubarak bale ẹjọ, to si ka ẹsun onikoko mẹta si lẹsẹ eyi to da lori iwa ọdaran lori ayelujara ati ibanilorukọjẹ.

Onanuga ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ ti n fihan pe oun kaato lati tọpasẹ awọn eeyan to n pin ọpọ iroyin eke kiri lori ayelujara.

Omoyele Sowore tutọ soke, foju gbaa tori bi DSS se gbe alatilẹyin Atiku

Wayi o, Oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu African Action Congress, AAC, Omoyele Sowore, ti fi ẹsun kan ijọba aarẹ Bola Ahmed Tinubu pe o n lo ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati pa awọn alariwisi rẹ lẹnu mọ.

Sowore sọrọ yii tori bi ajọ DSS se foju alatilẹyin Atiku Abubakar bale ẹjọ lori ayederu lẹta to n pin kiri nipa aarẹ.

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ yii loju opo aayelujara X rẹ, oludije aarẹ fẹgbẹ oselu AAC naa wa koro oju si ọna tijọba n gba lo ileesẹ eleto aabo naa.

O wa to naka aleebu sileesẹ DSS pe se lo n doju kọ awọn araalu, dipo ko fi aaye gba ero awọn eeyan to tako awọn igbesẹ ijọba.

Sowore wa n beere pe bawo ni wọn se tabuku ileesẹ alaabo DSS tilẹ wa di ẹrọ agbalẹ lasan, pe ko maa gba ero awọn araalu danu.

Sowore tun pọn oju mọ ijọba Tinubu pe o n bẹru lati koju awọn ọmọ Naijiria, ko si jiyin isẹ iriju rẹ, to si sapejuwe mimu Mubarak Abdullahi lori iwe to pin lori ayelujara lasan bii eyi to b ani ninujẹ.