Ọkọ̀ òfúrufú Air Peace balẹ̀ sí Egypt láti kó àwọn tí ogun lé kùró ní Sudan padà wálé
Ọkọ ofurufu akero ti ileẹṣẹ Air Peace ti gbera kuro ni Naijiria lati lọ ko awọn ọmọ Naijiria to ha si Egypt kuro nibẹ pada wale.
Awọn ọmọ Naijiria naa, ti ọpọ ninu wọn jẹ akẹkọọ ni ogun le kuro ni Sudan ti wọn si lọ si Egypt lati gba ibẹ wale.
Ninu atẹjade kan ti Air Peace fi lede, o ni nnkan bi aago mẹta ọsan ni baalu naa gbera kuro niluu Eko lọ si Egypt.
Atẹjada naa ni “Ọkọ ofurufu Boeing 777 wa to ni nọmba idanimọ 5N-BE gbera kuro ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa niluu Eko ni aago mẹta kọja iṣẹju mẹwaa ọsan oni lọ si Egypt lati lọ ko awọn ọmọ Naijiria ti ogun le kuro ni Sudan wale.”
Ileeṣẹ naa ni yatọ si pe awọn n ṣowo, awọn ko le la oju awọn silẹ ki iya maa jẹ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere lawọn ṣe gbe igbesẹ naa.
Lẹyin naa ni wọn dupẹ lọwọ ijọba apapọ fun akitiyan rẹ lati ko awọn eeyan ọhun kuro ni Egypt.
Ti ẹ ko ba gbagbe, kii ṣe igba akọkọ ree ti ileẹṣẹ Air Peace yoo fi baalu ọfẹ ko awọn ọmọ Naijiri ti iya n jẹ kuro nilẹ okeere pada wale.
Ọpọ awọn araalu lo ti bẹrẹ si n kan sara si ileeṣẹ naa fun akitiyan rẹ.