Àwọn orílẹ̀èdè tó tí kó àwọn ènìyàn wọn kúrò ní Sudan rèé
Ọpọlọpọ orilẹede lo ti n ko awọn eniyan wọn kuro ni Sudan bayii lẹyin ti ija laarin awọn ọgagun naa wọ ọṣẹ keji.
Nkan bii ọṣẹ meji ṣẹyin 1 ni ija bẹ silẹ ni Khartoun laarin awọn ọgagun meji ti wọn n tako ara wọn gẹgẹ bi adari lorilẹede naa.
Igun ikọ ọmọogun to gbajọba lo n koju ikọ RSF to n lọgun lati gba ijọba.
Iye orilẹede to ti ko awọn eniyan wọn kuro niyii
- Ọjọ Aiku ni orilẹede Amẹrika, Canada ati Ilẹ Gẹẹsi kede pe awọn n ko awọn eniyan wọn kuro ni Sudan.
- Aarẹ ilẹ Faranse, Emmanuel Macron kede pe Ọjọ Aiku ati Ọjọ Ajẹ ni awọn yoo gbe awọn eniyan wọ̀n to le ni 388 kuro nibẹ.
- Bakan naa ni orilẹede Belgium ni awọn ti ko awọn eniyan wọn ni ilu Kahrtoum pẹlu ọkọ ofurufu ilẹ Farance.
- Ijọba Ilẹ Gẹrman ni ọkọ ofurufu mẹta ti kuro ni Sudan lọ si Jordan fun aabo awọn ẹniyan mọkanlelọgọrun to wa ninu baalu naa.
- Italy, Spain naa ni awọn ti kọ awọn eniyan wọn kuro to fi mọ awọn ọmọ ilẹ Argentina, Colombia, Portugal, Poland, Mexico, Venezuela ati Sudan.
- Turkey fi ọkọ ko awọn eniyan to le ni ẹgbẹta lati gba oju ọna kuro ni Sudan pẹlu awọn eniyan lati orilẹede Azerbaijan, Japan, China , Mexico ati Yemen.