Wo bí ẹni tí kò tìí pé ọmọ ọdún 18 ṣe lè dèrò ẹ̀wọ̀n lásìkò ètò ìdìbò

Àkọlé fídíò, Wo bí ẹni tí kò tìí pé ọmọ ọdún 18 ṣe lè dèrò ẹ̀wọ̀n lásìkò ètò ìdìbò
Wo bí ẹni tí kò tìí pé ọmọ ọdún 18 ṣe lè dèrò ẹ̀wọ̀n lásìkò ètò ìdìbò
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ INEC lasiko to n ba BBC sọrọ
Published

Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC ti sọ pe ijiya wa fun ẹnikẹni ti ba tii pe ọdun mejidinlogun to ba lọ dibo lasiko eto idibo yoowu kaakiri orileede naa.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ INEC to ba BBC sọrọ lo fidi eyi mulẹ.

O sọ pe ẹnikẹni to ba dibo lai jẹ pe iru ẹni bẹẹ ti pe ọmọ ọdun mejidinlogun le lọ sẹwọn ọdun kan gbako, tabi pe ko san owo itanran, ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira.

Bakan naa lo sọ pe ofin faaye gba awọn ti ẹsin ko gba laaye lati ṣi oju silẹ, lati jade dibo lọjọ idibo, dipo ki iru awọn eeyan bẹẹ jokoo sile.