Inu owó ata àti ẹran tí ìyá àti bàbá mi ń tà ni wọ́n ti ṣàtìlẹ́yìn fún mi láti gbá bọ́ọ̀lù- Bashiru Awawu, agbábọ́ọ̀lù Flamigoes
Agbabọọlu fun ikọ U-17 obinrin Naijiria, Bashiru Awawu ti sọ pe ata ni iya oun n ta tẹlẹ ti baba oun si n ta ẹran ki adura oun to gba nidi bọọlu.
Awau lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba lẹyin ti ikọ naa, Flamigos gba ife ẹyẹ agbaye ni Morocco fun igba akọkọ ninu itan Afrika.
Ọdọbinrin naa sọ pe lati kekere ni oun ti n gba bọọlu, koda, ko si ẹni to kọ oun ni bọọlu gbigba.
O ni "bi wọn ṣe bi mi bayii, mo dẹ mọ bọọlu, wọn ko kọ mi ni bọọlu."
Gẹgẹ bi Awau ṣe sọ, nigba to lọ darapọ mọ ikọ agbabọọlu, o ni ẹka ti ọkunrin loun lọ, eyii ti wọn n pe ni Defences FC.

Oríṣun àwòrán, NFF
Lati ibẹ lọ o tun darapọ mọ Victory Queens ati FC Robo.
O sọ siwaju si pe "Ata ni maami n ta nigbayẹn, ti baa mi naa si n ta ẹran.
"Iya mi ṣatilẹyin fun mi, baba mi naa tun ṣatilẹun fun mi, gbogbo wọn ni wọn ti mi lẹyin. Ninu owo ata naa ni wọn ti sọ pe oya gba, o maa ṣe oriire sẹ."
Awawu sọ goolu si awọn nigba ti Naijitia koju Brazil ninu idije naa, o tun sọ goolu sinu awọn fun Naijiria nigba ti wọn gba aṣekagba idije ọhun.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun to ba BBC Yoruba sọ.



