Ibi tí wọ́n bí mi sí kò jìnà síbi tí wọ́n ti ń ta igbó, àánú ló kó mi yọ tí mo fi di akọrin ẹ̀mí - Esther Igbekele

Oríṣun àwòrán, Esther Igbekele/Instagram
Gbajumọ akọrin ẹmi, Esther Igbekele, ti sọ pe ọpọ awọn akẹgbẹ oun ni ko fẹran iru orin toun n kọ.
Arabinrin Esther sọ fun BBC News Yoruba wi pe oju akọrin ẹmi to ti wọ inu aye lọpọ awọn akẹgbẹ oun maa fi n wo oun.
Igbekele ni''mi o le sọ pe awọn olorin ti a jọ n kọrin ko fẹran nnkan ti mo n ṣe.
Ṣugbọn kii ṣe bo ti yẹ ki wọn fifẹ han si nnkan ti mo n ṣe to ni wọn ṣe n ṣe.
Awọn ni wọn mọ idi ti wọn ko fi gbaruku ti mi, mo maa n ri omiran ninu wọn gan an to maa n sọ pe mo ti wọ inu aye pẹlu orin ti mo n kọ.
Mo si maa n dawọn lohun wi pe inu aye ni emi n gbe, aye si wa ninu aye; ati pe Ayeraye lo n ṣejọba aye.''
Arabinrin Esther tun kọminu lori aṣa bi ọpọlọpọ ọdọ ṣe n mu igbo ati ọti eyi ti o sọ pe o ti di tọrọ fọn kale bayii.
Ilumọọka akọrin naa sọ pe kii ṣe wi pe iru iwa yii ko si tẹlẹ nigba toun n dagba, amọ, o ni ko si igboya fawọn ọdọ lati maa ṣe iru nnkan bayii nigba naa.
O ni ọdọ to ba n mu ọti ati igbo gan an ko ni i fẹ ki wọn mọ nile wọn.
Akọrin ẹmi naa fikun ọrọ rẹ pe wọn o bi oun sile ti wọn ti n fi ṣibi idẹ jẹun.
Gbajumọ olorin ẹmi naa sọ pe agbegbe Orile-Iganmu ni wọn bi oun si.
Arabinrin Igbekele ṣalaye wi pe ibi ti wọn bi oun si ko jinna sibi ti wọn ti n mu igbo ati ọti, ṣugbọn o ni aanu Ọlọrun lo ko oun yọ toun fi yatọ sawọn to n mu igbo.
Olorin ẹmi naa tun sọ pe ipa rere ni orin oun toun pe akọle rẹ ni ''Ṣe Normal'' ti ko ninu aye oun.
Ilumọọka olorin ẹmi naa sọ pe ọpọ eeyan lo maa n ke ti wọn ba gbọ orin oun ''Ṣe Normal.''
Akọrin ẹmi naa wa rọ awọn ọdọ lati wo iru ọrẹ ti wọn n ba a rin pẹlu bi iwa ibajẹ mimu ọti ati igbo ṣe pọ lawujọ bayii.
Bakan naa ni o tun rọ awọn obi papaa julọ awọn to lọmọ nile ẹkọ giga pe ki wọn mojuto wọn daadaa.
O ni ile ẹkọ alakọberẹ ni wọn ti n ran ọmọ mii ni igbo, kii ṣe igba to ba wọ ile ẹkọ giga fasiti.
Arabinrin Igbekele wa rọ awọn ọdọ wi pe ki wọn rọra ṣe ki wọn si ma fi oni ba ọla wọn jẹ.



























