Lóòótọ́ ni mo fẹ́ Lukman Ajuwon lẹ́yìn ikú ọkọ̀ mi, Gbenga Adeboye - Lara Adeboye

Oloogbe Gbenga Adeboye wọ buba leesi ati fila, aya rẹ Lara Adeboye wọ aṣọ leesi pẹlu gele aṣọ oke
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Arábìnrin Omolara Adeboye, tó jẹ́ opó olóògbé Gbenga Adeboye, tí sọ̀rọ̀ lórí ìrìnàjò rẹ̀ , pàápàá ìrìnàjò ìfẹ́ pẹ̀lú ọkùnrin míràn lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀.

Nínú ifọrọwanilẹnuwo kan tó ṣe, èyí tí Time Trek Blog gbé síta, ni Arabinrin Adeboye ti ṣàlàyé pé , lóòótọ́ ni òun fẹ́ ọkùnrin kan, Lukman Ajuwon, tí ariwo ti n sọ lórí rẹ̀ láti bi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn.

Ṣáájú ni awuyewuye ti n wáyé lórí bí Arábìnrin náà ṣe rìnrìn àjò rẹ̀ lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú.

Bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ọdún 2003 ni ọkọ rẹ̀ kú, láìpẹ́ yìí ni orí ayélujára tún n gbóná nípa Omolara Adeboye, lẹ́yìn ti fídíò ifọrọwanilẹnuwo tí àbúrò ọkọ rẹ̀ , Seun Adeboye, ṣe, jáde sórí ayélujára. Nínú rẹ̀ ló ti sọ àwọn nkankan bí ẹ̀sùn ìwà àgbèrè àti àìnání ẹbí ọkọ lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀, kan òpó náà.

Nígbà tó n dáhùn ìbéèrè nípa Ọgbẹni Lukman Ajuwon, Lara sọ pé lóòótọ́ ni òun fẹ́ arákùnrin náà.

Ó ní "bẹẹni, mo fẹ́ Lukman Ajuwon."

Ọ̀kan lára àwọn adarí ẹgbẹ́ awakọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifo, nípìnlẹ̀ Ogun, ni Ajuwon.

Ó ṣàlàyé pé, Ọgbẹni Ajuwon dúró ti òun àti àwọn ọmọ òun , tó sì ṣe atilẹyin fún àwọn.

"Lukman Ajuwon dúró tì mí. O tọ́jú mi, o tọ́jú awọn ọmọ mi. Kò sí nǹkan taa nílò, tí kò ṣe fún wa."

Omolara tẹ̀síwájú pé, arákùnrin náà ló dáàbò bo òun lọ́wọ́ gbogbo awuyewuye tó jẹyọ lẹ́yìn ikú ọkọ òun.

Bó ṣe n sọ ọrọ̀ náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ n jẹri sí i pé, Ọgbẹni Ajuwon, dára sí àwọn púpọ̀.

Òun tí Arábìnrin Omolara sọ yìí sì ló fi òpin sí àwọn àríyànjiyàn tó ti n wáyé lórí ọ̀rọ̀ òun àti ọkùnrin náà.

Bákan náà ló sọ pé lóòótọ́ ni àwọn méjèèjì kìí ṣe ọlọ́rọ̀ mọ́, nítorí pé ó fẹ́ fẹ̀ òun ni ìyàwó, "àmọ́ mi ò le gbàgbé òun tó ṣe fún mi".

Ọ̀gbẹ́ni Gbenga Adeboye, tó jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, adẹ́ẹ̀rínpòṣúnú, àti akọrin ṣaaju ikú rẹ̀, jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká lẹ́ka àwọ̀n amúlùdún, tọ́pọ̀lọpọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ sí fi ṣe àwòkọ́ṣe.

Elijah Oluwagbemiga Abefe Adeboye ni orúkọ àbísọ rẹ̀, àmọ́ Alhaji, Pastor, Olúwo, Jengbetiele, Itu baba ita, Alaye mi Gbengulo àti àwọn orúkọ míràn tó pani lẹ́rìn lo n jẹ lẹnu isẹ́.

Àwọn nǹkan málègbàgbé nípa Gbenga Adeboye

Oloogbe Gbenga Adeboye wọ ẹwu onila, o n woye
Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kò sí àníàní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò lé gbàgbé ádẹ́rìnposónu sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ náà nítori àwọn iṣẹ́ to ti gbése kí ó to gbà fún ikú lọgbọ̀n ọjọ oṣù kẹrin, ọdún 2003.

Láti túbọ̀ ṣe ìràntí Gbẹnga Adeboye, A ṣe àkójọ àwọn nǹkan mánigbàgbé mẹ́wàá tó ti ṣe nile aye.

1. Gbenga Adeboye lo sọ awada di itẹwọgba kaakiri

Gbenga Adeboye ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Funwọntan, ni ó wà lára àwọn ẹni àkọ́kọ́ tó sọ àwàda kẹrikẹri dí iẹwọgba gbogbo ènìyàn, kí àwọn ènìyàn mii tó lájú síbẹ̀.

Títí di àsìkò yìí, kò tíì ṣí ẹni tí o le ti ẹsẹ̀ bọ bata Gbenga Adeboye láti àsìkò yii titi di igba tó lọ sinmi láyà Oluwa.

Lẹ́yin àìsàn tó niṣe pẹ̀lú kídìrín ní Gbega Adeboye gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra.

2. Gbenga Adeboye lo ni orukọ inagijẹ to tii pọju lẹnu isẹ:

Nígbà tí a bí Gbenga Adeboye, Elijah Oluwagbemiga Adeboye ni wọn sọ ọ́, sùgbọ́n nígbà tí yóò fi kú, o níra láti le sọ iye orúkọ tó n jẹ́ lẹnu isẹ.

Ìdí ni pé nínú orín àti àwàdà tí o má n ṣe, ló ti jẹ́ oníruurú orúkọ bii Funwontan, Alhaji Pastor Oluwo, Jengbetiele, Itu baba Ita, Alaye mi Gbengulo àti àwọn orúkọ mííràn.

Gbenga Adeboye ni ẹbun pupọ ti ko se ka

Gbenga Adeboye jẹ ọkan ninu àwọn to ni ẹbun púpọ, ti o sì ni ìmọ̀ tó pọ̀ nínú iṣẹ̀ tọ yàn láàyò.

Kò sí ìgbà tó bá ń ṣe ohunkóhun ki àwọn ènìyàn má rín ẹ̀rin àrìn tàkìtì, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni, oludari ayẹyẹ lóde àríyá ni pẹlu, bakan naa lo tu maa n kọrin.

3. Oloju aanu ati Onididun ọlọrẹ ni Gbenga Adeboye

Nígbà ayé rẹ̀ àti lásìkò tó kú tan, gbogbo ènìyàn ló n jẹ̀rí si pé Gbenga Adeboye jẹ́ onínu dídùn ọlọ́rẹ ati ẹni ti kò máyé le rara.

Ọ̀kàn nínú ọ̀mọ̀ Funwọntan lo fi idi ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ fún BBC lásíkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

"O yá bábá mi kí a mú gàrí ju kí ará ìta má ri ounjẹ jẹ lọ."

4. Amunimọna ni Gbenga Adeboye, paapaa awọn to sẹsẹ n didelẹ:

Ọ̀pọ̀ ló má a n pè Gbenga Adeboye ni olùtọ́nisọ́nà fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde ni Alayé mi Gbengulo, bi ọ̀pọ̀ ṣe má a n pè é.

Ìròyìn fi ye ni pé, Gbenga Adeboye lo jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ gbájúgbàjà òṣèré Fathia Balogun bii isana ẹlẹẹta nítorí pé ó ṣe àfihàn rẹ̀ nínú ijó orin rẹ̀ kan.

Àwọn ènìyàn bí Baba Gboin, Ereke ni Sọobu àti àwọn mííràn ló ti ara Adeboye dide pẹlu.

5. Ọjọru jẹ ọjọ ọ̀wọ̀ fun Gbenga Adeboye, kii fi sere rara:

Gbenga Adeboye jẹ́ ẹni ti kìí fi Ọjọ́rú ṣere nígbà ayé rẹ̀, abúrò rẹ̀ kan lo fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ nínú àwo orin kan tó gbé jáde.

Ninu awo orin naa lo ti sọ ìtàn ayé Gbenga Adeboye kí ó tó di ìlúmọ̀ọ̀ká lásìkò náà, Ọmọ Majẹmu lo pe àkọle orin náà.

Ọjọ́rú jẹ́ ọjọ́ àrà ọ̀tọ̀ fún Gbenga Adeboye, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kẹsan ọdun 1959 ni wọ́n bíi

Ọjọ́rú ló bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé, Ọjọ́rú bákan náà ló rin ìrìnàjò àkọ́kọ́ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Amẹrika, Ọjọ́rú náà lo ṣe ètò Radio rẹ̀ àkọ́kọ́.

Ọjọ́rú, ọgbọ̀n ọjọ́, Oṣù kẹrin ọdún 2003 lo kú, wọ́n sì sí ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹrinlà, oṣù karun ọdún 2003.

6. Gbenga Adeboye ri ọrun, ko to ku

Wọ́n máá n ri Gbenga Adeboye gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti rí ọ̀run, kí ó tó kú.

idi ni pe o ti kọkọ ku nile iwosan, ti okiki si ti gba aye kan, ko to tun wa ji pada, ko si pẹ lẹyin igba naa, to tun jade laye pada.

Asiko perete to lo laye lẹyin iku rẹ akọkọ naa si lo gbe awo orin kan sita, ninu eyi to ti sọ bi ọrun se ri ati iriri ranpẹ to ni lajule ọrun nigba iku rẹ akọkọ.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ nínú àwo orin naa, o ni òun kú, òun si rí Ọlọ́rún, sùgbọ́n ó dá òun pada láti lọ pari iṣẹ́ tó ran òun láti gbé ilé ayé ṣe ni.