'Ó lè pa wá o': Àwọn olùgbé Kenya figbe ta lórí àkóbá El Niño pẹ̀lú àfojúsùn àgbàrá

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, inu ibẹrubojo ati aibalẹ ọkan ni awọn olugbe agbegbe kan niluu Nairobi, olu-ilu Kenya wa bayii, lori El Niño ti ariwo rẹ n kaakiri.
"Agba ọjọ ṣoṣẹ nibi ninu oṣu Kẹta," Agnes Shikoli, ọkan lara awọn olugbe agbegbe Kibera ni Kenya sọ bẹẹ fun BBC.
Shikoli lo n gbe nitosi odo Ngong, eyi to n ṣan lọ sinu odo olu-ilu Kenya tii ṣe Nairobi.
Pupọ ninu awọn ọṣẹ ti agbara ojo to rọ kọja ni ibẹrẹ ọdun yii ṣe, lo ṣi wa nilẹ, ti ko tii parẹ - to fi mọ ẹrọ amohunmaworan rẹ to to wa lẹgbẹ ogiri kan ninu yara rẹ.
Nibẹ naa ni aworan aburo rẹ, Beatrice Khalayi, ẹni ọdun mejidinlọgọta, to ku nigba ti ojo ṣakoba, to si ba ọpọ dukia jẹ.
Khalayi wa lara awọn ọgọta to padanu ẹmi wọn kaakiri orileede naa, lasiko ojo to rọ naa.
Ẹnikan lo pe mi, to sọ fun mi pe wọn ti ku, nigba ti ẹkun omi ya wọ inu ile rẹ, to si ba ina jẹ, ina ọhun lo gbe e, to fi dakẹ," Shikoli ṣalaye bẹẹ.
O sọ siwaju pe, "Nigba ti mo ri aworan rẹ, ko ba mi lara mu rara, idi ree ti nko ṣe jẹ ki aworan naa sunmọ mi, ki n ma ba maa ri."
Pẹlu bi ojo ṣe wa n rọ diẹdiẹ ni Kenya, Shikoli sọ fun BBC pe ẹru n ba oun – paapaa bi ikilọ ṣe ti wa nipa oorun El Niño to le mu ki agbara ojo tun ṣọṣẹ.
"Niṣe lo dabi ẹni pe o le pa wa. Kii ṣe okuta la fi kọ ile yii," Shikoli sọ bẹẹ fun BBC. "Wọn le pe wa, tabi ki omi gbe wa lọ."
Ilu Kibera ati Kenya ni wọn n lewaju bayii ninu igbaradi fun ipa ti ooru El Niño le ko lawujọ.
Awọn amoye tilẹ ti ṣe ikilọ akọsilẹ alagbara le wa lọdun yii, leyi ti yoo mu ayipada oju ọjọ waye.
Awọn alakoso bẹrẹ igbesẹ aabo
Ni ẹkun Guusu Kenya, arọda ojo yoo ṣọṣẹ, koda to tun ju ti tẹlẹ lọ.
Awọn alakoso ti wa bẹrẹ lati maa ko awọn idọti to wa lawọn agbegbe ti omi n gba kọja kuro, ki omi agbara le raaye lọ lai ni idiwọ.
Eto ọhun ni wọn pe ni Climate Worx, to wa labẹ Aarẹ William Ruto, ni wọn gbe kalẹ lati ṣe atunṣe si odo Nairobi.
Inu oṣu Kẹjọ, ọdun yii ni wọn ti bẹrẹ eto ọhun lati rii pe wọn bori gbogbo ohun to nii ṣe pẹlu ooru El Niño.
Awọ alakoso sọ pe awọn idọti to n di oju ọna omi lo n ṣakoba fun agbara, to si n fa iku aitọjọ awọn eeyan to ti ṣẹlẹ lọdun yii, nitori pe ọpọ ojo ko ri ọna gba.


























