Owó oṣù méje ni Gómìnà Adeleke ń jẹ àwa Ọba l'Osun, ọ̀pọ̀ Ọba ló ń ṣàìsàn tí kò rówó ra oògùn - Oloyan ìlú Oyan ké gbàjarè

Oloyan ti ilu Oyan, Oba Adekeye Oluyeye, wọ agbada pẹlu irukẹrẹ lọwọ, Gomina Ademola Adeleke wọ buba olomi buluu ati fila olomi ọsan.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oloyan ti ilu Oyan, Oba Adekeye Oluyeye, ti ke gbajare wi pe owo oṣu meje ni ijọba ipinlẹ Osun n jẹ awọn lọbalọba ipinlẹ naa.

Ọba Oluyeye sọrọ yii ninu fidio kan eyi ti ọpọ eeyan ti n sọ nipa rẹ lori ayelujara bayii.

Oloyan kepe Gomina Ademola Adeleke wi pe ko sanwo awọn lọbalọba tori ebi n pa awọn ori-ade bayii.

''Ebi n pa awọn ọba o, Nurudeen Jackson Adeleke, wọn n fi ebi pa awọn ọba atawọn ijoye.

Ni Odo-Otin wa nibi nikan, ọba mẹtadinlogun ni a ni pẹlu awọn Oloye 440.

Ko si ẹni to ri owo oṣu gba ninu gbogbo wa fun oṣu meje bayii.

Awọn to maa ṣagbatẹru bawọn eeyan ṣe maa dibo naa ni ijọba n fi ebi pa yii.

Pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe wọn yii, eyi gan an lo jẹ kawọn eeyan maa ku tori ironu ti pọju,'' Oloyan lo sọ bẹẹ.

''Ọsẹ marun un ni mo fi gba itọju nile iwosan LUTH niluu Eko, mo ṣẹṣẹ pada wale ni''

Ọba Oluleye ko ṣai fidi rẹ mulẹ wi pe Aarẹ Bola Tinubu ti ṣe nnkan to yẹ ko ṣe pẹlu bi o ṣe ni kawọn ijọba ibilẹ da duro maa ṣe ijọba wọn funra wọn lai sọwọ awọn gomina nibẹ.

Kabiyesi Oloyan sọ pe Tinubu maa n fi ifẹ han sawọn ọba alade.

Kabiyesi Oluyeye wa rọ gbogbo eeyan wi pe ki wọn kepe Gomina Adeleke pe ko sanwo to n jẹ awọn lọba lọba.

Oloyan ni ''oṣu keje lo tun pari bayii, ki ni ka ṣe bayii?

Igba ni onigba maa n ka, o ti ṣẹlẹ ri bayii naa ti ijọba Adeleke ti jẹ wa lowo oṣu mẹjọ.

Nigba to ya ni ijọba san diẹ fun wa ninu owo ọhun ki wọn to tun jẹ wa ni omiran.

Igba wo ni a fẹ ṣeleyii da? Nigba to ba rẹ ọba, ti ọba ko rowo ra oogun.

Fun apẹẹrẹ, ọṣẹ marun un ni mo fi gba itọju nile iwosan LUTH niluu Eko, mo ṣẹṣẹ pada wale ni.

Ati sanwo oogun fawọn dokita nira, ki ọba maa ya owo ra oogun.''