Àlàyé rèé lórí báwọn agbébọn ti ṣekúpa èèyàn mẹ́tàlá nínú ẹbí kan ṣoṣo

Oríṣun àwòrán, Nigerian army/X
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara ti ṣalaye bawọn janduku agbebọn ti ṣekupa eeyan mẹtala ninu ẹbi kan ṣoṣo.
Lopin ọsẹ to kọja ni awọn agbebọn ṣẹkọlu si idile kan labule Gidan Taba nijọba ibilẹ Maradun nibi ti wọn ti pa ọkunrin kan ati gbogbo idile rẹ.
Iṣẹlẹ naa ba awọn eeyan abule ọhun lẹru gan an, bo tilẹ jẹ pe lọpọ igba lawọn agbebọn ti maa n dunkoko mawọn eeyan abule ọhun tẹlẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe lasiko tawọn eeyan ti n sun ni iṣẹlẹ naa waye lopin ọsẹ to kọja.
Bi iṣẹlẹ ọhun ti waye
Agbẹnusọ ọlọpaa, DSP Yazid Abubakar, sọ fun BBC wi pe loru tawọn agbebọn naa ya wọ ilu ọhun ni wọn yika ile ọkunrin naa.
''Ile ọkunrin yii ni wọn lọ taara, wọn o si gbiyanju lati ṣekọlu si ẹlomiran ni abule ọhun yatọ si ọkunrin yii ati ẹbi rẹ,'' agbẹnusọ ọlọpaa lo sọ bẹẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn agbebọn ọhun dana sun ile ọkunrin yii lẹyin ti wọn ṣekupa oun ati gbogbo ẹbi rẹ tan.
DSP Yazid ni ''nnkan to buru jai ni iṣẹlẹ ọhun, awọn agbebọn naa ṣekupa ọkunrin naa atawọn iyawo rẹ to fi mọ gbogbo awọn ọmọ rẹ.
Gbogbo eeyan ti wọn ṣekupa si jẹ mẹtala, wọn si tun dana sun wọn.''
Eeyan meloo lo ba iṣẹlẹ naa lọ?
Ṣaaju ni awọn ileeṣẹ iroyin kan ti jabọ wi pe eeyan mejila lo ku ninu ikọlu naa.
Amọ, DSP Yazid ti fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹtala lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ọhun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọkunrin yii atawọn iyawo to fi mọ awọn ọmọ rẹ nikan ni won ṣekupa.
O ṣalaye wi pe ọkunrin yii lo ti maa n ṣeranwọ fawọn ẹṣọ eleto aabo to n gbogun tawọn janduku agbebọn lagbegbe naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni gbogbo awọn eeyan ti wọn ṣekupa naa ni wọn ti sin oku wọn bayii.
Eeyan meloo lawọn ẹṣọ eleto aabo ti fọwọ ofin mu lori iṣẹlẹ naa?
DSP Yazid Abubakar fikun ọrọ rẹ pe awọn kan fi to ileeṣẹ leti nigba ti ikọlu naa n lọ lọwọ.
Yazid sọ pe ni kete tawọn ọlọpaa gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn sare lọ sibẹ.
Amọ, o ni awọn agbebọn naa ti salọ kawọn ọlọpaa to de ibẹ.
Agbẹnusọ ọlọpaa tun sọ pe awọn agbofinro ti wa ni abule naa bayii lati pese eto aabo to peye ni abule ọhun.
''Ọkunrin ti wọn pa lo n daabo bawọn eeyan abule rẹ''
DSP Yazid Abubakar ṣalaye pe ọkunrin ti wọn ṣekupa yii lo ti n daabo bawọn eeyan abule rẹ lọwọ awọn agbebọn.
''Ọkunrin yii lo maa n fi ara rẹ silẹ lati ṣeranwọ fawọn ẹṣọ eleto aabo to n gbogun ti awọn janduku agbebọn.
Ọpọ awọn janduku agbebọn yii ni wọn ti n ṣọ ọkunrin naa.
Idi niyii ti wọn fi wa ọkunrin naa lọ tori wọn ti n binu si i tipẹ.
Akinkanju ni ọkunrin yii, o si maa n gba awọn eeyan abule rẹ silẹ.
Idi niyi tawọn eeyan abule rẹ fi wa ninu ibẹru-bojo bayii,'' DSP Yazid lo sọ bẹẹ.


























