Pasitọ Adeboye dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ bílíọ̀nù náírà owó jìbìtì tí ọmọ ìjọ kan fi ta ṣọ́ọ̀ṣì RCCG lọ́rẹ̀ padà fún EFCC

Pasito Adeboye ati Ola Olukoyede
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọga agba pata fun ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, EFCC, Ola Olukoyede ti sọ pe alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ RCCG, Pasito Enoch Adeboye ti da gbogbo owo ti ọmọ ijọ naa kan jiko, to si fi ta ijọ ọhun lọrẹ pada fun awọn.

Olukoyede sọ pe awọn owo to le ni biliọnu owo naira ti ẹni naa jigbe pẹlu iwa ajẹbanu lo fi ta iṣẹ akanṣe to n lọ lọwọ ninu ijọ The Redeemed Christian Church of God lọrẹ, ki aṣiri ma ba a tu.

EFCC jẹ ko di mimọ pe ni kete ti awọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn alakoso ijọ RCCG leti, ni Pasito Adeboye ti paṣẹ pe ki wọn da awọn owo naa pada.

Nigba to n sọrọ, Olukoyede sọ pe awọn owo naa ni wọn tọpinpin de apo aṣuwọn ijọ Ridiimu, lẹyin ti wọn fi awọn owo ọhun sọri iṣẹ akanṣe to n lọ lọwọ ninu ijọ naa.

Ọjọ Abamẹta to kọja yii ni Olukoyede tu aṣiri naa nibi akanṣe eto to ṣaaju ipagọ ọlọdọọdun ti wọn pe ni Holy Ghost Congress, eyi to waye lọjọ keje, oṣu Kọkanla.

O ni laaarin wakati mẹrinlelogun ti Pasitọ Adeboye ti gbọ si iṣẹlẹ naa, ni wọn ti da awọn owo ọhun pada.

Báwo ni ọ̀rọ̀ náà ṣe jade?

Gẹgẹ bi iwe iroyin 'Church Times Nigeria', ṣe kọ ọ soju opo rẹ, Pasito Adeboye lo ranṣẹ pe alaga EFCC naa lati wa ba awọn oṣiṣẹ ijọ naa sọrọ nipa ṣiṣe otitọ ninu ijọ.

Ninu ọrọ Olukoyede, o ṣalaye pe, "ọkan lara awọn ọmọ ijọ lo fi ọpọlọpọ biliọnu owo naira ijọ RCCG lọrẹ fun iṣẹ akanṣe to n lọ lọwọ, ṣugbọn ti iwadii pada fidi rẹ mulẹ pe iwa jibiti lo fi ri owo naa."

Alaga EFCC wa gbe oṣuba kare fun Pasitọ Adeboye lori igbesẹ lati da owo naa pada, ni kete ti o ti gbọ.

"Mo gbe oṣuba kare fun Pasitọ Adeboye to paṣẹ pe ki wọn da owo naa pada ni kete ti a fi to awọn alakoso ijọ leti," Olukoyede sọ bẹẹ.

Ṣugbọn ṣa, Olukoyede ko darukọ iru ẹni ti ọmọ ijọ naa jẹ, iṣẹ akanṣe ti owo naa wa fun, ṣugbọn o fidi rẹ mulẹ pe ọpọ biliọnu naira naa ni wọn ti gba pada.

Alaga EFCC naa to tun jẹ ọkan lara awọn pasitọ ijọba naa, kọminu lori bi awọn olori ijọ ṣe n lọwọ ninu iwa jibiti ati ajẹbanu, paapaa lori awọn ẹsun iwa jibiti ti wọn fi n kan awọn olori ijọ nipa iṣẹ akanṣe.

O wa ṣe ikilọ fun "awọn oṣiṣẹ ninu ijọ, nipa gbigba awọn owo to nii fura si, tabi ki wọn maa foju sọna fun awọn owo to ni ibeere ninu."