Ọmọlanke ni a kò bá máa fi ti owó Náírà bí a bá fẹ́ẹ́ lọ ra ata lọ́jà báyìí, kání kò sí àgbákalẹ̀ àtúntò ni – Ààrẹ Tinubu sọ̀rọ̀ fọ́mọ Nàíjíríà

Aarẹ Bola Tinubu lasiko to n sọrọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti ilẹ Naijiria ti sọ pe agbekalẹ atunto ti iṣakoso oun ṣe, lo gba owo Naira silẹ kuro ninu didi yẹpẹrẹ laaarin owo agbaye.

Tinubu sọ pe kani oun ko gbe igbesẹ lati fopin si owo iranwọ ori epo ni, eto ọrọ aje Naijiria ko ba ti dẹnukọlẹ patapata, ti owo Naira naa yoo si di yẹpẹrẹ.

Ilu Uyo, ni ipinlẹ Akwa Ibom ni Aarẹ Tinubu ti sọrọ yii, nibi eto ifilọlẹ gbọngan ayẹyẹ nla to wa ninu ọgba igbafẹ ARISE Palm Resort ti ijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ kọ.

Ilu Uyo, ni ipinlẹ Akwa Ibom ni Aarẹ Tinubu ti sọrọ yii, nibi eto ifilọlẹ gbọngan ayẹyẹ nla to wa ninu ọgba igbafẹ ARISE Palm Resort ti ijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ kọ.

Aarẹ sọ pe kani oun ko gbe igbesẹ akikanju ni kete toun gba iṣakoso gẹgẹ bi Aarẹ lati yọ owo iranwọ ori epo naa ni, owo Naira ko ba ti ma ti agbara kankan rara.

O ni iṣakoso toun gba, lo ku diẹ kaato deb iwi pe ipinlẹ mẹtadinlọgbọn ninu mẹrindinlogoji ni wọn ko le san owo oṣu fawọn oṣiṣẹ, depodepo wi pe wọn yoo san owo ifẹyinti ati owo ẹtọ lẹyin ifẹyinti.

"Nigba ti mog ba iṣakoso yii, gomina mẹtadinlọgbọn ninu mẹrindinlogoji lorileede yii ni wọn ko le san owo oṣu deedee, depodepo wi pe wọn yoo san owo ifẹyinti ati ẹtọ awọn oṣiṣẹ," Aarẹ Tinubu sọ bẹẹ.

O tẹsiwaju pe "Lonii, mo n duro siwaju yin lati sọ pe ohun gbogbo ti yi pada, a si ti kuro ninu asiko bẹẹ. Mo le fi gbogbo ọwọ sọya wi pe gbogbo asiko gbesẹ naa ti kọja."

Bakan naa, nibi eto ọhun to waye lọjọ Ẹti to kọja yii, Tinubu jẹ ko di mimọ pe, "Ni iru asiko yii, ka ni a ko gbe iru igbesẹ bẹẹ ni, lọjọ ti mọ gba iṣakoso, niṣe ni a ko ba maa fi ọmọ lanke ti owo naira wa kaakiri. Nitori pe ko nii jọju mọ."

"Naijiria ko tun ni pada sẹyin mọ lori ọrọ sọbusidi."

O fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹrun kan ati ọọdunrun naira ni owo dọla kan jẹ bayii, to si ni owo naa ti duro lori awọn iyi to ṣe pataki, nitori igbesẹ ti iṣakoso rẹ gbe.

Aarẹ wa fidi rẹ mulẹ pe ko si ohun to jọ wi pe awọn tun n boju wẹyin mọ lori ohun to ti kọja, bẹẹ si ni ko si ipinnu kankan ti iṣakoso rẹ yoo yipada.

O ni Naijiria yoo tubọ maa tẹsiwaju ni, pẹlu bo ṣe sọ pe, "Naijiria ko tun ni pada sẹyin mọ lori ọrọ sọbusidi."

"A n sọrọ nipa ẹgbẹrun kan ati ọọdunrun si owo dọla kan bayii. Nitori pe o tun ṣi ni iyi lapo. Ka ni a ti fi silẹ ni, ọmọlanke ni a ko ba maa fi tii bayii nigba ti a ba lọ ra ata lọja. Otitọ to wa nibẹ niyẹn."

"gbogbo owo ti ajọ EFCC ba ti gba, inu agbekalẹ eto ẹkọ lo n lọ"

Nigba to n sọrọ lori awọn aṣeyọri rẹ lẹka eto ẹkọ, Aarẹ sọ pe lara awọn ohun elo to ṣe pataki lati gbogun ti iṣẹ ati oṣi ni eto ẹkọ.

Aarẹ Tinubu ṣalaye pe gbogbo ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku, iyẹn EFCC n gba lori iwa ajẹbanu ni wọn n ko sori eto ẹkọ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, "Nko mọ iṣoro ti ọja ni, ṣugbọn mo n pin ninu iṣoro. Idi ree ti mo fi pinnu lati fopin si gbogbo ilakaka awọn obi ati alagbatọ lati san owo ile-ẹkọ awọn ọmọ wọn.

"Anfaani kan naa fun gbogbo eeyan to ba fẹẹ kawe. Nipa mimu eto ẹkọ gẹgẹ bi ohun elo gidi lati gbogun ti isẹ ati oṣi. Ati pipese anfaani fun awọn to n bọ lẹyin.

"Lati oni lọ, bi a ṣe n gbogun ti iwa ajẹbanu, gbogbo owo ti ajọ EFCC ba ti gba, inu agbekalẹ eto ẹkọ lo n lọ. Ko sẹni to le yi eyi pada."

Aarẹ Tinubu wa rọ awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Akwa Ibom lati gbarukuti iṣakoso rẹ, to si ṣeleri lati farajin fun idagbasoke ipinlẹ naa.