Mọ̀ nípa Abdul El-Sayed, mùsùlùmí àkọkọ tó wọlé ìbò Sẹnẹtọ nílé aṣòfin àgbà Amẹrika

Abdul El-Sayed wọ aṣọ kootu dudu ati ewu funfun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orukọ Abdul El-Sayed ti wọ inu iwe itan gẹgẹ bii musulumi akọkọ to wọle ibo sẹnẹtọ nile aṣofin agba orilẹede Amẹrika.

El-Sayed tawọn obi rẹ wa si Amẹrika lati orilẹede Egypt jawe olubori ninu eto idibo ile aṣofin agba ni Michigan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Democrats.

Bo tilẹ jẹ wi pe o koju oriṣiiriiṣi inunibini lasiko ipolongo ibo tori o jẹ ẹlesin Islam, El-Sayed to jẹ ọmọ ọdun mejilelogoji pada jawe olubori.

El-Sayed to jẹ dokita oniṣegun ko tii di ipo oṣelu kankan mu ri tẹlẹ ṣaaju asiko yii.

O koju oniruuru iṣoro ẹlẹyamẹya lasiko to n ṣe ipolongo ibo.

Ọrọ bẹyẹn yọ lasiko aṣekagba ibo abẹnu nigba ti alatako rẹ ninu ẹgbẹ Democrats, Haley Stevens, eyi to la mọlẹ kede atilẹyin rẹ fun oludije sipo aṣofin agba fẹgbẹ Republican, Mike Rogers.

Wọn bi El-Sayed lọdun 1984 ni Rochester Hills ni Detroit, baba rẹ ati iyawo baba rẹ, Jacqueline Johnson, lo wo o dagba lẹyin ti mama ati baba rẹ kọ ara wọn silẹ nigba ti El-Sayed wa ni ọmọ ọdun mẹta.

El-Sayed kọ ẹkọ nipa imọ iṣegun ni fasiti Michigan ati ni fasiti Columbia, nibi to ti kẹkọọ gboye ninu gbigbogun ti arun to maa n ran an.

Iyansipo rẹ gẹgẹ bi adari ẹka eto ilera Detroit lọdun 2015 lo jẹ ki o di ilumọọka kaakiri orilẹede Amẹrika.

El-sayed dupo gomina Detroit o si ṣe ipo keji ninu eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu Democrats, eyi ti alatako rẹ, Gretchen Whitmer, jawe olubori ninu rẹ ti o si wọle ibo gomina ipinlẹ naa.

Stevens ni Whitmer ṣe atilẹyin fun ninu eto ibo abẹnu ile igbimọ aṣofin agba ti ọdun yii, amọ, o pada kede atilẹyin rẹ fun El-Sayed lẹyin to jawe olubori tan.

Awọn abẹnugan ninu ẹgbẹ oṣelu Democrats bii Sẹnẹtọ Bernie Sanders ati aṣofin Alexandria Ocasio-Cortez lo ṣatilẹyin fun El-Sayed.

Aarẹ Amẹrika tẹlẹ ri, Barack Obama, naa ko gbẹyin ninu awọn adari ẹgbẹ Democrats to ṣatilẹyin fun El-Sayed.

Trump fẹsun kan El-Sayed wi pe o n ṣatilẹyin fawọn agbesumọmi

El-Sayed koro oju si iranwọ ti Amérika n ṣe fun Israel lasiko ipolongo ibo rẹ.

Bakan naa lo tun pe fun adinku owo ori fawọn ọlọrọ ki wọn le dokowo lẹka eto ilera.

O tun bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu Israel si Gaza lẹyin ikọlu Hamas ọjọ keje oṣu Kẹwaa ọdun 2023.

Ṣugbọn Aarẹ Trump fẹsun kan El-Sayed wi pe o n ṣatilẹyin fawọn agbesumọmi.

Igbakeji Aarẹ Amẹrika, JD Vance, naa sọ fawọn eeyan wi pe wọn nilo ẹni ti yoo ṣoju wọn daadaa ju El-Sayed lọ.

Amọ, ninu esi rẹ, El-Sayed sọ pe ‘’orukọ ati ẹsin mi kọ lo jẹ ki gaasi idana ati ounjẹ gbowo lori.

Ki i ṣii ṣe ẹsin mi ni ko jẹ ki ọpọ eeyan lowo lọwọ lati lọ gba itọju nile iwosan mọ.

Ilana ẹsin mi le yatọ si ti ọpọ eeyan l’Amẹrika, amọ, nnkankan naa ni gbogbo wa jọ n gbadura fun un.’’