EFCC tú àṣírí ibùdó ìfọpo China tó lòdì sófin nípìńlẹ̀ Ogun

Ibudo ifọpo naa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ EFCC to n ri si ajẹbanu lorilẹede yii ti ri ibudo ifọpo kan to lodi sofin niluu Ogere, ipinlẹ Ogun, eyi ti wọn ni awọn ọmọ orilẹede China kan lo ni in.

EFCC kede eyi ninu atẹjade ti olori ẹka iroyin rẹ, Dele Oyewale, fi sita lọjọ Iṣẹgun ana.

Ajọ naa sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ni aṣiri ibudo ifọpo lọna aitọ naa tu lẹyin itọpinpin lati mọ ohun ti wọn n ṣe nibẹ gan-an.

Iru epo wo ni wọn n fọ nibẹ?

Awọn àgbá nibudo ifọpo naa

Gẹgẹ bi Oyewale ṣe ṣalaye, o ni ko si eeyan mọ nibudo ifọpo naa nigba ti EFCC debẹ, o si jọ pe wọn ti kọ ibudo naa silẹ.

O ni eyi ri bẹẹ latari bi ijọba ṣe ti kọkọ yabo ibudo mẹrin to jẹ ayederu ti wọn ti n pese eroja ti a mọ si Lithium.

Amọ ni ti ibudo ifọpo ayederu ti wọn ri l'Ogere yii, EFCC sọ pe awọn ri awọn nnkan elo ti wọn fi n fọ epo naa ti wọn ko lo mọ.

EFCC sọ pe ohun to jọ pe wọn n lo niyẹn pẹlu àgbá epo ti wọn rì si abẹ ilẹ, ti wọn fi n rọ epo ọhun.

"Meji ninu awọn agba epo ti wọn ri si abẹ ilẹ naa ti a yẹwo fi han pe epo disu (Diesel) lo wa nibẹ.

"Iwadii fi han pe awọn to n fọ epo naa maa n lo ẹroja epo dudu kan (sludge oil), wọn n ko o wa lati Warri, ipinlẹ Delta ati Port Harcourt, ipinlẹ Rivers.

Eyi ni wọn maa n gbe wa si ibudo ifọpo ayederu to wa ni Ogere, nipinlẹ Ogun, ti wọn yoo fọ si epo"

Oyewale lo sọ bẹẹ.

Bi wọn ṣe n ṣe epo naa

Apa kan ibudo naa tun ree

Oyewale ṣalaye pe awọn to n fọ epo naa maa n gbe e igba ori ina to lagbara, wọn a po o pọ mọ eroja epo bẹntiroolu ti ko ki pupọ, wọn yoo da a mọra wọn ti yoo fi jọ epo, wọn yoo si ta a sọja ni Naijiria.

"Awọn eeyan to wa nibẹ sọ fun EFCC pe awọn oṣiṣẹ China to n ṣe epo ọhun ko sọ orukọ wọn fun ẹnikẹni ri, bẹẹ ni ko sẹni to mọ orukọ ibudo ọhun."

Bẹẹ ni Olori ẹka iroyin ni EFCC naa wi.

O ni ẹka EFCC to wa l'Ekoo ti gba ibudo naa, iwadii si n lọ lọwọ lati mọ awọn to wa nidii ayederu iṣẹ ti wọn n ṣe nibẹ gan-an.