Ọkọ̀ òfúrufú já lulẹ̀, gbogbo èrò inú rẹ̀ jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eeyan mẹsan an ti jade laye lẹyin ti baalu kekere kan ti wọn wa ninu rẹ ja lulẹ ni Florida, lorilẹede Amẹrika.
A gbọ pe agbegbe Cresthaven, to jẹ kilomita mẹrinla si Mar-a-Lago, to jẹ gbagede igbafẹ Aarẹ Donald Trump ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Austin, ni Texas ni baalu ọhun ti kọkọ gbera to si n lọ si Bahamas ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
Ayẹwo bi baalu naa ṣe fo ṣafihan pe o n jabọ ni ọpọlọpọ iwọn bata ko to ja lulẹ patapata.
Ṣaaju ko to ja lulẹ lawọn to n tukọ rẹ ti n fi ohun ranṣẹ pe iṣoro wa.
Ninu ọrọ awọn awakọ ofurufu naa tawọn to wa ni papakọ ofurufu ka silẹ, ọrọ ti wọn sọ kẹyin ni pe "ko si akoko fun wa mọ."
Amọ ṣaaju akoko naa ni wọn ti kọkọ n pariwo "May day! May day!" eyii to n ṣafihan pe ewu n bẹ loko longẹ.
Awọn fidio ori ayelujara kan ṣafihan bi baalu naa ṣe ja lulẹ to si lana lẹsẹkẹsẹ.
Gomina Florida, Ron DeSantis sọ fun awọn akọroyin pe bi baalu naa ṣe ja da bii igba ti wọn ba yin ado oloro misaili.
A ko tii le sọ irufẹ eeyan to wa ninu rẹ lasiko ti baalu naa ja lulẹ,
DeSantis ni "lọwọ yii, a ko ni iroyin kankan lọwọ nipa ẹnikẹni to wa lori ilẹ…to ku tabi farapa."
Akọwe ileeṣẹ to n ri si eto irinna, Sean Duffy sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyi to ba awọn lẹru amọ ajọ FAA yoo ṣe iwadii kikun lori rẹ.
Duffy ni "Ẹ darapọ mọ mi lati gbadura fun awọn mọlẹbi atawọn ololufẹ gbogbo awọn ti iṣẹlẹ naa kan."
Ileeṣẹ ọlọpaa Palm Beach County ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ pe awọn ti n ko awọn eeyan kuro lagbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
A gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣakoba fun awọn nnkan amayedẹrun mii to wa lagbegbe naa bi omi, yoo si to nnkan bii ọgbọn ọjọ ki wọn to le ṣi oju ọna to ja si pada.

























