Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Flamingos ti Nàíjíríà pegedé fún ipele àṣekágbá ìdíje U-17 ti àwọn obìnrin fún ìgbà àkọ́kọ́

Agbabọọlu Naijiria ati awọn agabbọọlu Brazil ree lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Itan tuntun ni ẹgbẹ agbabọọlu awọn ọjẹ wẹwẹ ti orileede Naijiria, iyẹn Flamingos fi balẹ nigba ti wọn fidi akẹgbẹ wọn lati Brazil rẹmi.

Naijiria lo lu Brazil pẹlu ami ayo mẹta si ookan ninu idije ife-ẹyẹ agbaye ti awọn obinrin ọjẹ wẹwẹ U-17 to n lọ lọwọ lorileede Morocco.

Ipele to kangun si aṣekagba, eyi tii ṣe Quarter Finals ni Flaingos ti pegede fun ipele aṣekagba ọhun.

Igba akọkọ ree ti Naijiria yoo maa de ipele aṣekagba naa, latigba ti wọn ti bẹrẹ lọdun 2008.

Naijiria lo kọkọ gba goolu mẹta wọle, ko to di pe Brazil naa tiraka lati ni ggolu kan, eyi ti wọn fi pa odo rẹ.

Queen Joseph lo ṣide goolu naa ni iṣẹ mẹrindinlọgọta, lẹyin ti wọn ti gba ọọmi ni saa akọkọ.

Oluwakemi Adegubyi lo ṣe iranlọwọ goolu naa, ti Joseph fi gba a wọle.

Iṣẹju mọkanlelaadọrin ni Awawu Bashiru tun ri anfaani to ṣi silẹ, to si gba bọọlu wọle nigba ti Queen Josepn ṣe iranwọ.

Bashiru naa lo tun gba goolu kẹta wọle ni ọgọrin iṣẹju, lati de aṣeyọri wọn lade.

Ṣugbọn nigba to ku diẹ ki feere ifẹsẹwọnsẹ naa wa si opin, ni ọmọ Brazil nni, Greise Kelly, ri anfaani, to sib a bọọlu naa sawọn ni iṣẹju mọkandinlaadọrun-un.

Ni bayii, orileede Japan ni Naijiria yoo lọ koju l'Ọjọru, ọsẹ to m bọ, ọjọ kọkanla, oṣu yii.

Japan lo fidi North Korea to jẹ alagbara idije naa lọwọlọwọ rẹmi ṣaaju.