Wo àwọn kókó márùn-un tó jẹ́ kí Flamingos gba ife ẹ̀yẹ U-17 fún ìgbà àkọ́kọ́

Ẹgbẹ agbabọọlu Flamingos lasiko ti wọn gba ife ẹyẹ agbaye U-17 lorileede Morocco
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oriire nla lo wọle tọ ilẹ Naijiria, pẹlu bi ẹgbẹ agbabọọlu awọn obinrin ọjẹwẹwẹ, iyẹn Flamingos ṣe gba ife ẹyẹ agbaye U-17 to waye lorileede Morocco.

Igba akọkọ ree ti ẹgbẹ agbabọọlu Flamingos yoo maa gba ife ẹyẹ yii, latigba ti wọn ti bẹrẹ rẹ lọdun 2008.

Flamingos ko kọja ipele Round of 16 ri, latigba ti wọn bẹrẹ idije naa, depodepo wi pe wọn yoo de ipele to kọgun si eyi to kọgun si aṣekagba tii ṣe Quarter Finals.

Yatọ si pe Flamingos gba ife ẹyẹ naa fun igba akọkọ, ẹgbẹ agbabọọlu naa tun lo jẹ akọkọ nilẹ Afrika ti yoo gba ife ẹyẹ ọhun fun igba akọkọ.

Goolu meji si ookan ni Naijiria fi bori awọn akẹgbẹ wọn lati orileede Japan, nibi aṣekagba ifẹsẹwọnsẹ to waye lọjọ Satide.

Awawu Bashiru ati Oluebube Umejiaku ni wọn gba bọọlu sawọn Japan lati fi pegede fun ife ẹyẹ agbaye naa.

Iṣẹju mọkandinlogoji ninu saa akọkọ ni Awawu gba bọọlu naa sawọn, lẹyin ti Mary Dunstan ṣe iranwọ goolu fun un.

Lẹyin eyi ni Umejiaku tun ri anfaani miran ni iṣẹju meji ti wọn bẹrẹ saa keji, nigba ti Esther Stephen gba bọọlu sinu awọn.

Gbogbo ilakaka Japan pada yọri sibikan nigba ti awọn naa ri anfaani lati da goolu kan pada ni ọgọrin iṣẹju, nigba ti Fuki Ito gba bọọlu sawọn Naijiria.

Àwọn kókó márùn-ún náà

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àìṣiyè méjì:

Nigba ti idije naa bẹrẹ, ijakulẹ ni Flamingos kọkọ ba pade nigba ti wọn koju akẹgbẹ wọn lati orileede Poland.

Aami meji si ookan ni Poland fi bori Naijiria nigba ti wọn pade lati koju ara wọn.

Ìfarajìn:

Naijiria ko jẹ ki irẹwẹsi ọkan ba wọn, pẹlu bi wọn ṣe fi gbogbo ara si ifẹsẹwọnsẹ to waye pẹlu akẹgbẹ wọn lati orileede Puerto Rico, ti wọn si bori pẹlu aami ayo meji si odo.

Flamingos yege kuro ni ipele akọkọ tii ṣe Group Stage, nigba ti wọn fẹyin akẹgbẹ wọn lati orileede DPR Korea gbolẹ pẹlu aami ayo mẹta si ookan.

Àfojúsùn:

Ni ipele Round of 16, Naijiria bori akẹgbẹ wọn lati ilẹ Mexico pẹlu aami ayo meji ti ookan, leyi to jẹ ki wọn peregede si abala Quarter Finals.

Venezuela ni Naijiria koju ni ipele Quarter Finals, ti wọn si ṣe akitiyan lati bori pẹlu aami ayo kan si odo lati de ipele Semi-Finals.

Ọkàn akíkanjú:

Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n ro pe Brazil yoo ko goolu rẹpẹtẹ le Naijiria lọwọ, nigba ti wọn ba koju ara wọn, ṣugbọn niṣe ni ọrọ yipada.

Goolu mẹta ni Flamingos ko le Brazil lọwọ lọjọ ti wọn figagbaga, leyi to jẹ ki yege fun aṣekagba to waye lalẹ ọjọ Abamẹta, bo tilẹ jẹ pe Brazil naa ṣe akitiyan lati da goolu kan pada.

Àṣeyọrí:

Kete ti Naijiria ti bori Brazil, ni wọn ti bẹrẹ gbogbo eto lati rii pe awọn gba ife ẹyẹ agbaye naa lati fi itan tuntun balẹ.

Oniruuru igbaradi ni wọn ṣe lai sinmi, lati rii pe awọn gbe ife ẹyẹ naa lọ sile fun gbogbo ọmọ Naijiria.

Tọkantọkan ni Naijiria fi gba aṣekagba naa, eyi ti wọn fi bori pẹlu aami ayo meji si ookan.