Ìyanṣẹ́lódì tẹ́gbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC bẹ̀rẹ̀ l'Osun, àlàyé bó ṣe kan àwọn ìjọba ìbílẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Nigeria Labour Congress HQ/Facebook
Ẹgbẹ oṣiṣẹ nilẹ Naijiria, NLC, ẹka tipinlẹ Osun ti paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati gun le iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta.
NLC sọ pe lati oni ọjọ Aje, ọjọ kẹsan, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni iyaṣẹlodi naa yoo bẹrẹ, lati fi beere fun awọn owo ijọba ibilẹ nipinlẹ naa.
Atẹjade ti alaga ati akọwe NLC nipinlẹ naa, Christopher Arapasopo ati Victor Amusan buwọ lu lọjọ Aiku to kọja lo fidi rẹ mulẹ.
Awọn alakoso ẹgbẹ naa sọ pe agogo mejila oru ọjọ Aiku si ọjọ Aje ni iyanṣẹlodi ọhun bẹrẹ.
Wọn sọ pe awọn gbe igbesẹ naa lati le ṣatilẹyin fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti ijọba ibilẹ, iyẹn NULGE nipinlẹ Osun, lori awọn owo to jẹ ẹtọ wọn to wa lọwọ ijọba.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Ṣaaju asiko yii ni awọn alakoso NLC ti sọ pe awọn ti gbe ikilọ ọlojọ meje kalẹ fun ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Osun lori bi wọn ṣe mu owo awọn ijọba ibilẹ l'Osun dani, lai yọnda rẹ fun wọn.
Wọn ni awọn ọrọ naa ko tii ni iyanju titi di asiko ti awọn fi paṣẹ pe ki iyanṣẹlodi ọhun bẹrẹ.
Ninu atẹjade naa ti Arapasopo ati Amusan buwọ lu, o sọ pe, "Lẹyin lilo gbogbo ọna to tọ, ti ko si sọna abayọ, ati pẹlu abajade ipade ti igbimọ iṣakoso (SEC) ṣe l'Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026, gbogbo ọmọ ẹgbẹ NLC nipinlẹ Osun la n paṣẹ fun lati gun le iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta lati ṣatilẹyin fun ẹgbẹ NULGE nipinlẹ Osun."
"Iyanṣẹlodi naa bẹrẹ ni oru ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2026, ti yoo si wa fun ọjọ mẹta, eyi ti yoo wa si opin loru Ọjọru, ọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, ọdun 2026.
"Ati pẹlu, gbogbo awọn ẹgbẹ alafọwọsowọpọ pata ni ki wọn sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati rii pe wọn tẹle aṣẹ ati ilana yii kaakiri ibiṣẹ wọn."
Ìkìlọ̀
Bakan naa, NLC wa ṣe ikilọ fun gbogbo oṣiṣẹ ti ọwọ ba tẹ wi pe o lọ si ibi iṣẹ tabi wi pe o tapa si aṣẹ ati agbekalẹ naa yoo foju winna ofin ẹgbẹ wọn.
O fi kun ọrọ rẹ pe, "Gbogbo ẹgbẹ patapata ni wọn gbọdọ fi atilẹyin wọn han nipa iṣṣokan ati ifarajin fun ilakaka fun aabo, ẹtọ ati igbayegbadun awọn oṣiṣẹ. A ni lati mọ pe ohun ba de si oju, o ti de si gbogbo ara naa niyẹn.
"Iya to n fojoojumọ koju awọn eeyan wa ninu ẹgbẹ NULGE jẹ agbajọwọ fun gbogbo ẹgbẹ oṣiṣẹ, ati pe gbogbo wa la ni lati gbaruku ti wọn."


























