'Bí eré, bí àwàdà la fi bẹ̀rẹ iṣẹ́ orin kíkọ̀' - Ẹgbẹ́ akọrin Loud Urban Choir

Awọn akọrin Loud Urban Choir
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Odu ni ẹgbẹ akọrin Loud Urban Choir, wọn ki ṣaimọ foloko nilẹ Naijiria, ati kaakiri agbaye.

Awọn olorin naa ni wọn ṣalaye bi wọn bẹrẹ orin kikọ, to fi di pe gbogbo aye tẹwọ gba wọn lai lero rẹ tẹlẹ.

Aṣoju ẹgbẹ naa, Funmi Arewa lasiko to n ba BBC sọrọ, jẹ ko di mimọ pe bi ere, bi awada ni awọn fi bẹrẹ iṣẹ orin kikọ naa, ko to di pe o burẹkẹ mọ wọn lọwọ.

Funmi Arewa sọ fun BBC pe, "Bi gbogbo wa ṣe bẹrẹ si ni maa ṣiṣẹ pọ, a rii wi pe a nifẹ ka maa kọrin papọ. A ri wi pe ti a ba jokoo papọ, ti a ba kọrin, a maa wo pe, ki lo n dun to dun leti bayii.

"Ki lo n dun to jẹ ki ara maa da ṣaka bayii. A wa wo pe ko ni da ka ni nnkan to dara bayii, ka ma fi ṣe nnkan.

"Gbogbo wa la wa panupọ, a si pinnu lati sọ ọ di nnkan ti a jọ ma maa ṣe. A jọ ma maa kọrin, a ko ma maa ṣere, a jọ ma maa ṣe oriṣiriṣi nnkan papọ.

"A si bẹrẹ si maa ṣe e. Igba ti a dẹ kọrin kan ti a pe ni Bloody Samaritan pẹlu Ayra Starr. Igba ti a kọrin yẹn, ni gbogbo orin ọhun ba di ilumọ-ọn-ka.

"Kaakiri lawọn eeyan ti n sọ pe ki lo n ṣẹlẹ. A wa wo o pe a ko le fi kini yii ṣere, bi gbogbo wa ṣe wa papọ, ti a bẹrẹ sii ṣe awo orin jade niyẹn," o sọ bẹẹ fun BBC.

"Ibi gíga láti dé"

Arẹwa tun fi kun ọrọ rẹ pe ibi to ga ni iṣẹ orin naa ti gbe awọn de, to si lawọn ko lero wi pe awọn le debẹ, nigba ti awọn bẹrẹ.

O ni ẹni akọkọ to n ṣe oun ni kayeefi lati ba ṣiṣẹ papọ ni gbajugbaja Kelly Rowland, to ni awọn jọ kọrin papọ.

Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe awọn ṣi n tẹsiwaju.