Gbàǹjo pásípọ́ọ̀tù! Ohun tí a mọ̀ rèé nípa àwọn tó ń ta ìwé ìrìnnà 'diplomatic passport' fáwọn tí kò tọ́ sí

Iwe irinna ilẹ Ghana aṣia ati ontẹ orilẹede Ghana
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O ni igbesẹ ti eeyan yoo gbe to ba fẹ rin irinajo lati ilu kan si orilẹede miran, lara rẹ si ni gbigba iwe irinna atawọn eto miran ti ẹni to fẹ rin irinajo naa ni lati ṣe.

Labẹ eto naa, eeyan yoo lọ si awọn ẹka to n ri si irinajo lati ilu to ti fẹ kuro, yoo gba awọn iwe to yẹ ko gba lọna ẹtọ ki irinajo naa too ṣee ṣe.

Amọ lọwọ yii, ẹka to n ri si irinajo lorilẹede Ghana ti ke gbajare, pe niṣe ni awọn kan n ta iwe irinna atawọn iwe ti arinrinajo nilo lati gba ko too ni anfaani lati le lọ.

Wọn ni awọn to n ṣe eyi n ṣe bẹẹ lẹka iwe irinna ti wọn maa n fun awọn oṣiṣẹ ijọba, awọn to n ṣoju ijọba nilẹ ibomi-in ti wọn si n ṣiṣẹ nibẹ, atawọn ti ko tiẹ yẹ ki wọn fun ni iwe aṣẹ irinajo rara.

Awọn ọmọ ẹgbẹ to kere niye nile igbimọ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Ghana, lo ke gbajare naa lọjọ Aiku ọsẹ yii ti I ṣe ọjọ kẹjọ oṣu Kọkanla ọdun 2026.

"A ti ri awọn ẹri to fi han pe wọn gbowo lọwọ awọn ti ko tọ, ta iwe irinna fun wọn"

Nibi ipade ti wọn fi kede ọrọ naa.

Nigba to n fidi ẹsun yii mulẹ nibi ipade oniroyin to waye lanaa ọjọ Aiku, Samuel Abu Jinapor, ọkan lara awọn igbimọ to n ri si irinajo ilẹ okeere ni Ghana, sọ pe awọn ti ri awọn aṣiri kan to fi han pe wọn n ta iwe irinna fawọn ti kotọ si.

Bẹẹ lo pe fun iwadii kikun ti yoo fi ohun tawọn ri naa han gbogbo aye.

Lọsẹ to kọja, ẹgbẹ oṣelu alatako ni Ghana; New Patriotic Party (NPP) naa sọ pe awọn ti ri awọn iwe ẹri owo sisan ti wọn fi ta iwe irinna fawọn ti ko tọ si i.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lori ọrọ yii kan naa ni olori ile igbimọ aṣofin; Alban Bagbin, ṣe ni ki Samuel Jinapor jade nile igbimọ lọjọ kẹta oṣu Kọkanla yii, lẹyin ti aṣofin naa kọ lati ko ohun to wi nipa tita iwe irinna jẹ.

Aṣofin Jinapoer sọ lọjọ naa pe wọn n ta iwe irinna naa ni $10k ati $50k, amọ ko mu ẹri wa.

Awọn eeyan to kere julọ nile igbimọ naa fi kun un pe o ti to eeyan ọọdunrun (300) to ti fi iwe irinna ti wọn ra rin irinajo lọ sile okeere.

Wọn si ni awọn kan wa lẹka iwe irinna silẹ okeere gbigba naa ti wọn n gba ẹyin ba ẹbọ jẹ, atawọn agbodegbe ni ọfisi naa.

Wọn fi kun un pe awọn to n ta iwe irinaa naa n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ arinrinajo afẹ kan to jẹ aladaani .

Awọn wọnyi ni wọn n fun awọn ti ko si nipo kankan lẹka ijọba ni ipo naa lori iwe irinaa, wọn yoo si kọ orukọ wọn si I ti wọn yoo fi le rin irinajo ọhun bi wọn ṣe sọ.

"Wọn maa n lo ayederu ipo lati fi to iwe irinna, koda nigba ti wọn ko yẹ fun iwe irinna naa."

Samuel Jinapor lo sọ bẹẹ fawọn akọroyin.

"Awọn iwe yii kan fi han pe wọn ti buwọlu u, o gbe awọn orukọ bii Samuel Okudzeto Ablakwa; to jẹ minisita jade."

Bẹẹ ni Samuel Jinapor wi.

Awọn ti wọn ni wọn lọwọ si ọrọ yii

Atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Aiku, darukọ Adele lẹka iwe irinna; Mahama Yahaya Amantana ati Alhassan Sumani to jẹ oṣiṣẹ kekere lẹka irinajo.

Wọn ti fẹsun kan Sumani ri pe agbodegbe ni, ni 2023, ki wọn too gba a siṣẹ tan loṣu Kọkanla ọdun 2024.

Ẹka irinanjo naa tun sọ pe awọn ti tọka awọn oṣiṣẹ meji mi-in fun ọlọpaa lati tọpinpin wọn.

Bakan naa ni wọn ni awọn ti fagile iwe irinaa eeyan mẹwaa ti wọn gba ọna ẹburu gba iwe naa ni 2023.

Wọn fi kun un pe gbogbo awọn to wa nidii iwa yii ni awọn yoo foju wọn lede ti won yoo si jẹjọ ofin.

Ṣaa, ohun ti awọn ọmọ ẹgbẹ to kere ju lọ naa n beere bayii ni pe ki wọn gbe igbimọ kalẹ ti yoo yẹ awọn iwe irinna to wa nilẹ wo.

Ki wọn yẹ awọn eyi ti wọn ti buwọlu wo.

Ki wọn gbe akọsilẹ awọn eeyan to n buwọlu iwe irinna yii jade ati bẹẹ bẹẹ lọ.