Fún sísá lójú ogun, ṣọ́jà 66 gba ìdájọ́ ikú

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kere tan, ṣọja mẹrindinlaadọrin (66) ni wọn ti dajọ iku fun bayii lorilẹede Democratic Republic of Congo, fun pe wọn ṣe ojo, wọn sa logun wọn si kọ lati tẹle aṣẹ awọn olórí ti wọn pa fun wọn.
Eyi n waye lẹyin ti ṣọja mọkanlelaadọrin (71), foju ba ile ẹjọ awọn ologun to wa ni Walikale, ni Ariwa Kivu lorilẹede naa.
Wọn yọnda ṣọja mẹrin pe ki wọn maa lo pẹlu alaafia, wọn si ju sọja kan si ẹwọn ọdun mẹwaa.
Ileeṣẹ ologun ilẹ naa sọ pe oun ṣe eyi lati fi awọn to yẹ jofin, kawọn yooku naa le huwa to tọ bi wọn ṣe n koju ikọ to n da ilu laamu ni Ila-Oorun DR Congo.
Ohun to ṣẹlẹ gan-an
Ọdun gbọọrọ ni aibalẹ ọkan ti wa lagbegbe yii ni Congo, bẹẹ ni rogbodiyan n waye laarin ọmọ ogun ijọba ati ikọ Front for the Refoundation of the Nation (FRN), ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ, to fi mọ ẹgbẹ M23.
Iroyin sọ pe ogunjọ oṣu Kẹwaa ni wọn mu awọn ṣọja yii ni Walikale, nibi ti wọn ti fẹsun kan wọn pe wọn fi aaye wọn silẹ, wọn sa loju ogun lasiko ija pẹlu awọn onija FRN.
Bakan naa ni ijọba ti n fẹsun kan orilẹede Rwanda to jẹ alamuleti rẹ pe wọn n ṣatilẹyin fun ikọ M23.
Amọ orilẹede naa sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ, bo tilẹ jẹ pe atilẹyin naa foju han.
Bi ọpọ eeyan niluu naa ṣe n bu ẹnu atẹ lu ẹka ologun ibẹ pe ko si ibawi nibẹ, bẹẹ ni awọn ṣọja naa n sọ pe ijọba ko sanwo gidi fawọn, ko si tun si nnkan elo ogun to.
Nibi ti ọrọ ai si ibawi yii gbilẹ de, awọn ologun mẹtadinlọgbọn (27) ni wọn dajọ iku fun loṣu to kọja lori ẹsun kan naa, lẹyin ti wọn ni wọn sa loju ogun pẹlu awọn alatako.
Loṣu Kẹwaa ọdun 2025, wọn dajọ iku fun Aarẹ Congo tẹlẹ, Joseph Kabila, bo tilẹ jẹ pe ko si nitosi.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni i ṣe pẹlu ogun ati iditẹ mọ ilu.
Kabila loun ko ṣẹ ẹṣẹ naa bo tilẹ jẹ pe ko yọju si kootu lati ṣalaye.
Latigba naa ni wọn si ti ka a si olori ikọ FRN.

























