James Bond: Ohun tí a mọ̀ nipa fíìmù 007 tuntun tó ń bọ̀ lọ́nà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti oṣiṣẹ ile igbafẹ kan beere lọwọ James Bond lọdun 2006 ninu Casino Royale wi pe ṣe yoo fẹ ki wọn mi ọti vodka martini rẹ, tabi wi pe ki wọn kan da, pẹlu ibinu lo fi da a lohun pe "Ṣe mo dabi ẹni to kọ ikan ni?"
Ọrọ to fi dahun naa lo ti n fi apẹẹrẹ iru asiko tuntun fun 007 – ati pe fiimu agbelewo atibadegba naa ti wọn fi lelẹ lọdun 1962 lo ti gbọna ọtun yọ pẹlu Daniel Craig ti wọn gbe wọ.
Ninu awọn fiimu diẹ to n bọ, awọn alakoso ere gbiyanju lati mu ifẹgbẹkẹgbẹ ba ohun to ti kọja, nipasẹ yiya ara wọn ni diẹ ninu apap ere itan naa to dabi arosọ tabi aṣeju. Wọn ko si tun fara mọ gbogbo aṣa, ilana ati awọn abuda ti a mọ si ti Bond bi wọn ṣe maa n tẹle.
Ogun ọdun lẹyin ikopa Craig, agbekalẹ fiimu naa tuntun lo tun fẹẹ dide pada, pẹlu awọn oju tuntun ti yoo mu ki iṣẹ naa gbọna ọtun yọ.
Iwuri nla lo jẹ fun Craig lati tun wọ ọna ti awọn oṣere tuntun yii yoo gba lati mu igbelarugẹ ba iṣẹ to ti kopa ninu rẹ kọja.
Ohun ti a mọ ree
Igba wo ni wọn yoo kede ẹni ti yoo kopa James Bond tuntun?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun awuyewuye, gbogbo eto lo ti to bayii fun awọn alakoso lati kede oṣere ti yoo bẹrẹ sii kọpa James Bond ninu oṣu Kọkanla tabi oṣu Kejila.
Nigba to n sọrọ ninu oṣu Kẹjọ, alakoso ere naa, Amy Pascal sọ fun akọroyin pe: "Mo le sọ pe opin ọdun ni asiko to dara lati kede, ohun to gbọgbọn ni."
Idanwo aworan waye ni ipari oṣu Kẹwaa, fun idi eyi, ayafi ti nnkan miran ba tun ṣẹlẹ, ko yẹ ko pẹ pupọ fun awọn alakoso lati ṣe ipinnu wọn, ati awọn oṣere ti wọn yoo tọwọ bọwe adehun pẹlu.
Lẹyin eyi, o nii ṣe pẹlu igba ti wọn yoo kede. Ibi ipade awọn akọroyin ni wọn ti kede awọn oṣere Bond pẹlu aworan ti wọn gbe sita.
Ṣugbọn ni bayii to jẹ pe Amozon MGM lo n ṣakoso bayii, awọn eeyan n foju sọna fun ileeṣẹ naa lati kede awọn oṣere ọhun lori ikanni amohunmaworan Prime.
Iru eeyan wo ni James Bond tuntun yoo jẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ awọn oṣere ni igbagbọ wa wi pe wọn ti yege fun aṣekagba to kẹyin lati gba ipo oṣere to ga julọ naa.
Awọn oṣere mẹta to wa niwaju ninu awọn to ṣee ṣe ki wọn mu ni:
Jack Lowden, 36
Josh O'Connor, 36
Callum Turner, 36
Awọn yooku ni:
Jack O'Connell, 36
Jack Barton, 31
Joe Alwyn, 35
Nicholas Hoult, 36
Robert Pattinson, 40
Jacob Elordi, 29
Paul Mescal, 30
Igba wo ni wọn yoo gbe Bond tuntun sita?
Ọdun 2027 ni igbagbọ wa wi pe wọn yoo bẹrẹ yiya fiimu naa, ko to di pe wọn gbe e jade ni ọdun 2028. Ko tii si ọjọ kan ni pato ti wọn ti kede rẹ.
ỌJọ ti wọn yoo gbe fiimu jade le jẹ ohun to ruju, ṣugbọn ohun to daju bayii ni pe awọn alakoso ati awọn onkọtan ti wa nilẹ.
Igba kẹrindinlọgbọn ree ti wọn yoo ṣe fiimu naa pẹlu oniruuru akọle, ṣugbọn akọle eyi to n bọ lọna ni wọn ko tii fidi rẹ mulẹ.
Taani yoo kọ itan, ti yoo si dari Bond tuntun?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Denis Villeneuve ti awọn eeyan mọ ninu awọn fiimu bii Prisoners, Sicario, Arrival, Blade Runner 2049 ati eyi ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade, Dune trilogy ti Timothée Chalamet lewaju ninu rẹ ni yoo dari Bond tuntun yii.
Villeneuve sọ pe oun "dagba lati maa wo James Bond pẹlu baba mi, latigba Dr. No pẹlu Sean Connery. Mo jẹ ọkan lara awọn ololufẹ Bond tọkantọkan."
Steven Knight ni yoo kọ Bond kẹrindinlọgbọn, ẹni to ti kọ iọniruuru itan bi Peaky Blinders ati House of Guinness, to fi mọ awọn fiimu bii Burnt, Spencer, Locke ati The Girl in the Spider's Web.



























