Russell Brand: Adẹ́rìnpòṣónú rí ẹ̀wọn ọdún mẹ́wàá àti oṣù mẹ́fà he fún ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ àti aṣemáṣe

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajumọ alawada to maa n farahan lori amohunmaworan ilẹ Gẹẹsi ni ọkunrin kan,Russell Brand, amọ lọjọ Aje ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹsan-an oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii, ile ẹjọ sọ ọ si ẹwọn ọdun mẹwaa ati oṣu mẹfa fun ẹsun ifipabanilopọ ati aṣemaṣe sawọn obinrin kan.
Nigba to n ṣapejuwe Brand, Adajọ Joel Bennathan to gbe idajọ naa kalẹ sọ pe ikooko ajeegunjẹran ni labala aṣemaṣe ibalopọ.
O ni opurọ ni pẹlu, to n fi irọ bo iwa ibajẹ mọlẹ.
Adajọ sọ pe orukọ to ni ati bo ṣe jẹ gbajumọ to lo n da aabo bo ti aṣiri iwa ipa nipa ibalopọ rẹ ko fi tete jẹ jade.
Adajọ Bennathan gboriyin fawọn obinrin to jade sọ iwa ipa ti Brand hu si wọn, o ni olujẹjọ naa ti ṣe ohun to fẹ, eyi to tako iwa ọmọluabi, asiko ẹsan si ti de wayi.
Ki ni Brand ṣe, igba wo lo ṣẹ ẹṣẹ naa?
Ọsẹ to kọja yii ni ile ẹjọ dajọ ifipabanilopọ kan ati ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu awọn obinrin mẹrin fun Brand Russell, ẹni ọdun mọkanlelaadọta (51).
Wọn ni o ṣe awọn ẹṣẹ naa laaarin ọdun 2004 si 2009.
Ọkan lara awọn obinrin to fẹsun naa kan, sọ pe lati ọdun 2004 ti Brand ti ba oun ṣe ere buruku naa ni ile ọti kan ni London ni iṣẹlẹ naa ti n daamu ọkan oun.
Obinrin to tako o ni kootu naa sọ pe:
"Fun ọpọ ọdun ni okiki rẹ fi n kan to si n han lori tẹlifiṣan, ti mi o le ma ri I kaakiri ori ayelujara, ti wọn yoo maa gboriyin fun iwakuwa to n hu sobinrin bii pe awada lo n fi iyẹn naa
ṣe.
Obinrin keji, ẹni ọdun mọkanlelogun to ni Russell fipa ba oun lo pọ ni 2009, sọ fun kootu pe oun ti ro pe ko sẹni ti yoo gba oun gbọ boun ba fẹjọ sun pe Brand Russell fipa ba oun lo pọ.
"Okiki rẹ, ọla ati bo ṣe lagbara to maa n jẹ ki n da bii ẹni ti ko le ṣe nnkan kan fun un."
Ọmọbinrin naa fi kun un pe ifipanilopọ naa ti ni ipa lori igbesi aye oun ni gbogbo ọna.
Brand to n wo orere bi igbẹjọ to sọ ọ sẹwọn ọdun mẹwaa aabọ naa ṣe n lọ lọwọ, tako awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Amọ o loun gba pe oun fẹran ibalopọ, oun si maa n lo jijẹ gbajumọ oun lati fi wọle si obinrin lara.
Iyawo rẹ, Laura Gallacher, to bimọ mẹta fun un naa wa ni kootu Southwark Crown, ni London, nibi ti wọn ti dajọ ẹwọn ọdun mẹwaa aabọ fun Brand Russell ọkọ rẹ.
Atupalẹ ẹwọn ọdun mẹwaa aabọ naa
Ẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun ifipabanilopọ, eyi ti yoo ṣe pẹlu idajọ mẹta mi-in.
Ẹwọn oṣu mẹsan-an fun ẹsun kẹta, iyẹn fun obinrin ti wọn lo fọwọ ko lọyan nile ọti kan ni London ni 2004.
Ẹwọn oṣu mejidinlogun fun ẹsun karun-un, fun ṣiṣe erekere pẹlu obinrin kan ni Choice FM studios, ni London to waye ni 2004 tabi 2005.
Ẹsun eyi ni pe o fọwọ wọ oju obinrin naa mọra o si fẹnu ko o lẹnu ko too fọwọ kan ọyan rẹ ati idi rẹ.
Ẹwọn oṣu mẹjọ fun ṣiṣẹ erekere pẹlu obinrin kan lasiko to n ṣiṣẹ ni Channel 4 ni 2009, nigba naa lo gbe ori rẹ sọwọ isalẹ ara obinrin naa lai jẹ pe iyẹn fun laṣẹ lati ṣe bẹẹ.
Apapọ awọn ẹsun naa lo si jẹ ọdun mẹwaa ati oṣu mẹfa.
Ta a ni Russell Brand?
Wọn bi Brand Russell ni Essex, Ila-Oorun London ni 1975, o kuro nile ẹkọ nipa ere ori itage lai pari nibẹ ko too darapọ mọ MTV nigba to wa lẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ( 25).
O ti figba kan ṣeto lori Radio BBC ri, laaarin 2006 si 2008.
Brand kuro ni BBC lẹyin to fi atẹjiṣẹ ibalopọ kan ranṣẹ si oṣere kan to gbajumọ, to sọ fun iyẹn pe oun ti ba ọmọ-ọmọ rẹ obinrin lo pọ.
Ile ẹjọ sọ pe o jẹbi ẹsun aṣemaṣe to ṣe si oṣiṣiṣẹ MTV kan, ti Channel 4 kan, oṣiṣẹ Capital Radio kan ati ọkan lara awọn araalu to fẹran rẹ lobinrin.
Awọn ileeṣẹ to gba Brand laye fun ọdun pipẹ ti n koju ibeere, pe bawo ni won ṣe gba a laye fun igba pipẹ bẹẹ.
Minisita eto Aṣa nilẹẹ Gẹẹsi, Lisa Nandy, sọ lọjọ Aiku pe awọn ọkunrin to wa nipo agbara ṣi n fi ilọkulọ lọ awọn obinrin lẹka iroyin, o ni itaniji ni ti Brand yii jẹ.




























