Ọkọ̀ bọ́ọ̀sì forí sọ ọkọ̀ akérò, èèyàn 21 jáde láyé

O kere tan, eeyan mọkanleogun (21) lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ kan to waye lorilẹede Tanzania.
Yatọ si awọn to jade laye, eeyan marun-un mi-in ni iroyin sọ pe wọn tun farapa ninu ijamba ọkọ naa to waye lọjọ Aje, ọjọ kẹsan-an oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii.
Bawo ni ijamba naa ṣe waye?
Gẹgẹ bi atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Iringa ni Tanzania fi sita ṣe sọ, ni ijamba naa waye lorita Kiponzero, loju ọna marosẹ Iringa-Mbeya, ni Guusu orilẹede naa.
Ọkọ akero kan lo n bọ lati abule to si n lọ si aarin ilu Iringa, ko too fori sọ ọkọ miran to jẹ ọkọ akẹru.
Ohun ti a gbọ ni pe ọkọ bọọsi naa padanu ijanu rẹ lojiji ni, to mu ki dẹrẹba ma ni ikapa lori rẹ mọ.
Eyi lo fa a ti dẹrẹba to n wa bọọsi naa fi lọ fori ọkọ naa sọ ọkọ akẹru miran to wa nitosi.
Ohun to fa ijamba to mu ẹmi eeyan mọkanlelogun lọ niyẹn.
Gẹgẹ bi akọsilẹ awọn ọlọpaa ṣe wi, ọkunrin mẹwaa, obinrin mẹsan-an ati awọn ọmọde meji lo ba ijamba naa lọ sọrun.
Ni ti awọn ero ọkọ marun-un to farapa, wọn ko wọn lọ sile iwosan fun itọju, bo tilẹ je pe wọn ko kede bi ifarapa naa ṣe pọ to.
Ṣaa, awọn ọlọpaa sọ pe iwadii n tẹsiwaju lati mọ ohun pato to fa ijamba naa gan-an.



























