Wo àwọn nǹkan tí Ààrẹ Tinubu ń gbèrò láti ṣe fún aráàlú tó bá wọlé sáà kejì

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
Ni ipalẹmọ de ibo aarẹ ti yoo waye loṣu Kin-in-ni ọdun 2027, Aarẹ Bola Tinubu ti kede awọn ohun ti yoo ṣe fawọn ọmọ Naijiria bi wọn ba le dibo fun un sipo naa lẹẹkan si i.
Tinubu sọ pe oun yoo gba ẹṣọ alaabo ẹgbẹrun mejidinlọgọrin (78,000) ti wọn yoo jẹ ọlọpaa ati ṣọja siṣẹ, ti yoo jẹ afikun awọn eyi to wa lẹnu iṣẹ naa tẹlẹ.
Bakan naa lo ni oun yoo kọ ile ẹgbẹrun lọna igba (200,000) ti araalu yoo le rowo gba, ti ko ni i wọn rara bi wọn ba le dibo foun lati di aarẹ ni 2027.
Aarẹ Tinubu sọrọ yii ninu alakalẹ eto ti ẹgbẹ oṣelu APC sọ pe awọn ni fun ọdun 2027 titi de 2031, bi ẹgbẹ naa ba jawe olubori pẹlu ibo araalu.
Awọn nnkan wo lo tun ku ti Tinubu ṣeleri?
Ninu iwe oloju awẹ ọkandinlaadọfa (109) ti wọn kọ ileri Aarẹ si lo ti ṣeleri :
* Afikun ida mẹfa lẹka ọrọ aje lọdọọdun.
*Ina ọba to duro deede.
*Adinku owo ọja
*Nini ẹtọ si ẹkọ ati ilera.
Ṣọja 28,000, ọlọpaa ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) ni Aarẹ sọ pe oun yoo gba si i fun eto aabo.
Wọn yoo ro ibudo ologun to wa ni Makurdi, Ilorin, Jalingo ati Benin City.
Bakan naa ni lo ṣeleri igbesi aye irọrun, ẹdinwo ounjẹ ti yoo to ti yoo tun ṣẹku.
A maa gba tiṣa 20, 000
Fun eto ẹkọ, Aarẹ Tinubu sọ pe oun yoo gba tiṣa ẹgbẹrun lọna ogun, awọn obinrin ni yoo si pọju ninu wọn, bẹẹ ni yoo kan awọn agbegbe igberiko ti tiṣa ko ti pọ.
Ileri naa tẹsiwaju, Aarẹ loun yoo din awọn akẹkọọ ti ko si nile ẹkọ ku nipa fifi wọn sile ẹkọ, riri i daju pe wọn duro wọn si pari ẹkọ wọn.
Ni abala ilera, Aarẹ Tinubu ṣeleri pe ida aadọrun-un (90%) ile iwoṣan alabọọde yoo maa ṣiṣẹ deede nigba ti yoo ba fi di ọdun 2031 ati bẹẹ bẹẹ lọ.


























